Ẹni tí Ẹlẹ́da Yorùbá yàn, tí Ó fi ṣe Olùgbàlà Ìran Yorùbá, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́la, tún ti fọhùn síta o, lórí díẹ̀ nínú àwọn nkan tó wà nínú Àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè fún àwa Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá, fún Orílẹ̀-Èdè wa, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá.

Ní àkọ́kọ́ ná, Màmá àwa ọmọ Ìran Yorùbá, rán wa létí pé kò sí inkankan tó kàn wá pẹ̀lú ohun tí ó nṣẹlẹ̀ ní Nàìjíríà o!

Wọ́n sọ, pàtó, lórí ọ̀rọ̀ aṣòfin kan ní Ìlú Nàìjíríà, ìlú tí ó fẹ̀gbẹ́ tì wá, èyí tí a gbọ́ láìpẹ́ yí pé o ndába òfin kan látàrí pé kí ẹnikẹ́ni ó má ṣe sọ ọ̀rọ̀ tàbí gbé ìgbésẹ̀ tí ó le mú kí elòmíì sọ pé àwọn fẹ́ yapa kúrò nínú ìlú wọn Nàìjíríà.

Màmá fi dá wa lójú pé ìlú wọn, Nàìjíríà, ni wọ́n ti nsọ ìyẹn o, àti pé kò kàn wá rárárárá, àwa Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti ẹ̀ tún ti wá gbọ́, pàápàá pé aṣòfin Nàìjíríà ọ̀ún tiẹ̀ tún ti yí ohùn padà, gẹ́gẹ́bí Màmá ṣe fi tó wa létí; ṣùgbọ́n wọ́n tẹnu mọ pé kò tilẹ̀ kàn wá láti ilẹ̀ pẹ̀pẹ̀: nítorí Orílẹ̀-Èdè ọ̀tọ̀ ni àwa, orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ sì ni Nàìjíríà.

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. pín sórí àgbàgbé ti X (Twitter)

Bẹ́ẹ̀ náà ni Màmá tún sọ fún wa pé, jíjẹ́ orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀, pẹ̀lú pé aṣèjọba-ara-ẹni ni a tún jẹ́, láti ọjọ́ kéjìlá oṣù igbe ọdún tí a wà nínú rẹ̀ yí – ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rin-lé-lógún, ìyẹn jẹ́ òótọ́ tí ó dúró títí ayé, kò sì ní nkankan ṣe, tàbí papọ̀ mọ́ jíjẹgàba tí Nàìjíríà ṣì jẹ gàba lórí ilẹ̀ wa di ìwòyí: ìkan kò ní ohunkóhun íṣe pẹ̀lú ìkejì rárárárá.

Nàìjíríà dẹ̀ máa kúrò láìpẹ́ yí, láṣẹ Èdùmarè; ìjọba D.R.Y ti nṣiṣẹ́ lọ, ìyẹn ò sì ní àìníyelórí kankan látàrí pé Nàìjíríà jẹ gàba; kò dín agbára orílẹ̀-èdè wa kù, kò dín jíjẹ́ tí a jẹ́ orílẹ̀-èdè kù, rárárárá, kò sì lè dinkù láílaí.

Bẹ́ẹ̀ náà ni Màmá wa fi yé wa pé, inkan tí ó njẹ́ “Ilẹ̀ Yorùbá,” láti àtètèkọ́ṣe wá, tí á tún mọ̀ sí “Ìṣèjọba Yorùbá,” “Agbègbè-Ilẹ̀ Yorùbá,” àti “Orílẹ̀-Èdè Yorùbá,” òun kan náà ni a tún npè ní “Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá” (D.R.Y), lóni. Ìkan náà ni, àti pé láti ìsisiìyí lọ, gbogbo gbólóhùn wọ̀nyí ni kí á máa lò.

Màmá wá bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn ohun díẹ̀ díẹ̀ yé wa nínú Àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè fún àwa Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorubá; lákọkọ́, wọ́n jẹ́ kí á mọ̀ pé ìyàtọ̀ wà láarín “Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá” àti “Ará Ìlú Yorùbá,” èyí sì jẹyọ nínú nọ́mbà ìdánimọ̀ tí wọ́n máa fún wa ní àìpẹ́.

Nọ́mbà ti Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P) òun ni a mọ̀ sí ÌYÌN (Indigenous Yorùbá Identification Number); tí nọ́mbà Ará Ìlú Yorùbá sì jẹ́ CIN (Citizen Identification Number). Wọ́n yàtọ̀ síra wọn.

Ẹnikẹ́ni kò dẹ̀ gbọdọ̀ purọ́ pé Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá ni òun (I.Y.P) tí kìí bá nṣe I.Y.P; ẹnikẹ́ni tí ó bá purọ́ bẹ́ẹ̀, á kábamọ̀ ayérayé ní ohun tí ó máa ṣẹlẹ̀ si.

Màmá wá fi yé wa pé àwa tí a jẹ́ I.Y.P, ní kété tí ó bá ti pé ọmọ ọdún mọ́kànlélógún, ni a ti ní ẹ̀tọ́ láti kàn sí ìjọba pé a fẹ́ ní ilẹ̀, tí ìjọba D.R.Y dẹ̀ máa fún ẹ ní ÌLẸ̀ ní orúkọ ẹ lọ́fẹ!

Ẹ̀tọ́ ẹ ni gẹ́gẹ́bí I.Y.P tóo bá ti pé ọmọ ọdún mọ́kànlélógún: ṣùgbọ́n óò ní ẹ̀tọ láti ta ilẹ̀ náà, láyé, fún ẹnikẹ́ni; tí ó bá gbìyànjú àti ṣe èyí, o máa kábamọ̀ rẹ̀ gidi. Má ṣe dan wò.

Ìwọ ni kí o ṣe iṣẹ́ rẹ, bóyá o jẹ́ òṣìṣẹ́ níbi kan ni, tàbí o dá iṣẹ́ kan sílẹ̀, tìẹ ni kí o ṣiṣẹ́ láti le ní owó tí o máa fi kọ́ ilé tí o fẹ́ kọ́ sí orí ilẹ̀ náà, ṣùgbọ́n óò san owó kankan fún ilẹ̀, ẹ̀tọ́ rẹ ni gẹ́gẹ́bí ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá, tí oò dẹ̀ gbọ́dọ̀ tàá. Ilẹ̀ tí o lè tà ni ilẹ̀ tí o fi owó rà fúnra rẹ, kìí ṣe èyí tí D.R.Y fún ẹ gẹ́gẹ́bí ẹ̀tọ́ ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá.

Ìdí tí D.R.Y ò fi ní fún ẹ ní owó láti kọ́ ilé náà, lẹ́hìn tí wọ́n ti fún ẹ ní ilẹ̀ lọ́fẹ, ní pé, gẹ́gẹ́bí Màmá wa ṣe sọ, Àlàkalẹ̀ D.R.Y kò fi àyè sílẹ̀ fún ọ̀lẹ; nítorí ìlú tí ó bá nfún àwọn ènìyàn ní owó ọ̀fẹ́ kìí sábà gbérí tó bo ṣe yẹ kí wọ́n lè gbérí tó. Ṣùgbọ́n D.R.Y máa ṣe ìrànlọ́wọ́ àti mú kíkọ́ ilé náà kí ó rọrùn.

Màmá wá tún wá gbà wá ní ìmọ̀ràn, pé, tí a bá jẹ́ I.Y.P, tí ó sì jẹ́ pé lẹ́nu ọdún kan sẹ́yìn, tàbí ọdún méjì sẹ́yìn, sí àkókò tí a wà lóni, a ti lọ sí ilé-ìwòsàn, yálà ní Ilẹ̀ Yorùbá, tàbí ní Nàìjíríà lọ́hun, tí wọ́n dẹ̀ ṣe iṣẹ́ abẹ fún wa, èyí tí ó mú kí wọ́n kùn wá lórun láti ṣe iṣẹ́ abẹ náà dání, wọ́n ní kí á padà lọ ṣe àyẹ̀wò ara wa o, láti ri dájú pé ẹ̀yà ara wa ṣì pé, ati kí ó má dẹ̀ jẹ́ pé èyà ẹranko tàbí ẹ̀yà-ara ẹni kan tó ti kú, tí kò dẹ̀ dára, ni ó wà ní ibikíbi ní ara wa.

Tí ó bá jẹ́ pé àìrí owó kò jẹ́ ká lè ṣe eléyi, wọ́n ní kété tí ìjọba wa, ìjọba D.R.Y, bá ti wọlé sínú oríkò ilé-iṣẹ́ ìjọba wa gbogbo, D.R.Y máa ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wa láti lè ṣe àyẹ̀wò-ara náà, nítorí D.R.Y kò níí gbà kí ẹnikẹ́ni ó ti mú ẹ̀yà ara I.Y.P kankan!

Democratic republic of the Yoruba ominira new update | Yoruba Nation | Newest Nation in Africa, Youngest country in the World 2024
Ìròyìn Òmìnira Olojoojumọ – Bèrè fún ẹ̀da títí rẹ!

Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyi, Màmá ní kí irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí kó gbogbo àwọn ìwé tí ó jẹ mọ́ iṣẹ́ abẹ náà jọ.

Màmá tún wá ṣe ìkìlọ̀ fún gbogbo àwọn tí kìí ṣe I.Y.P ṣùgbọ́n tí wọ́n ngbé ní ibikíbi káàkiri orígun-mẹ́rẹ̀rin ilẹ̀ Yorùbá, ìṣèjọba Yorùbá, Agbègbè-Ilẹ̀ Yorùbá, Orílẹ̀-Èdè Yorùbá, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (ìkannáà ni gbogbo ẹ̀), pé kí wọn máṣe sọ ọ̀rọ̀, tàbí ṣe ohunkóhun tí ó lòdì sí I.Y.P, tàbí lòdì sí D.R.Y, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ àbùkù, ọ̀rọ̀ àlùfànṣá, ọ̀rọ̀ ìgbéraga, tàbí ìjẹgàba lórí tàbí sí I.Y.P tàbí D.R.Y. Tí wọ́n bá ṣe eléyi, ẹ̀ṣẹ̀ nlá gbáà ni o!

Màmá wa tún sọ̀rọ̀ lórí Ìfẹ̀hónúhàn, èyí tí ó jẹ́ pé, a ò tilẹ̀ nírònú báwo ló ṣe máa ṣẹlẹ̀, nígbà tó jẹ́ pé, rere rere ni nkan tí Orílẹ̀-Èdè wa, D.R.Y, ní fún wa; ṣùgbọ́n, wọ́n wá sọ pé, tí ìrúfẹ́ nkan bẹ́ẹ̀ bá máa wáyé, ó ní àlàkalẹ̀ tí a máa gbe gbà, èyí tí ó fi jẹ́ pé kò níí sí wàhálà kankan, kò dẹ̀ ní si pé ẹnikẹ́ni ndàgboro rú!

Màmá sọ pé ọmọ-ológun Yorùbá kankan kò ní ẹ̀tọ́ láti wà láarín ìgboro; kò dẹ̀ sí ohun tí ó njẹ́ pé ọmọ-ológun tàbí ọlọ́pa máa dójú ìjà kọ ẹnikẹ́ni tí ó nṣe ìfẹ̀hónúhàn!

Ohun gbogbo ti Yorùbá, ìwà ọmọlúàbí ni!