Ọ̀pọ̀l’ọpọ̀ ọmọ Yorùbá, l’oní, ni kò mọ̀ wípé, ní ìgbà kan rí, nígbàtí Yorùbá ṣì nṣe àkóso ara wọn bí ó ti’lẹ̀ jẹ́ wípé Nàìjíríyà ṣì mbá ìjọba àpapọ̀ lọ ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ wípé, Yorùbá wà ní àyè ara rẹ̀; nṣe ni ìpèsè omi ẹ̀rọ t’ó mọ́ gaara wà káàkiri ilẹ̀ Yorùbá.

Ẹ̀yin ẹ jẹ́ kí á lé agbésùnmmí Nigeria já'de ná kúrò l'orí ilẹ̀ wa; nígbànáà ni ẹ ó wá rí ohun rere tí orílẹ̀-èdè Yorùbá yíò gbé ka'lẹ̀ fún ìgb'áyégbá'dùn ọmọ Yorùbá. Share on X

Títí dé gbogbo ìgbèrí’ko sì ni omi ẹ̀rọ t’ó mọ́ gaara yí wà. Kìí tún wá ṣe wípé o máà rìn lọ títí kí o tó dé ibi tí ẹ̀rọ náà wà; rárá o! Bóyá l’ó ṣe ju ojúlé mẹ́ẹd’ogun sí’ra tí wàá tún ti rí ẹ̀rọ omi.

Àdúgbò kan tí  ojúlé ibẹ̀ kò fi tóbẹ́ẹ̀-jùbẹ́ẹ̀-lọ pọ̀ púpọ̀ lè ní irúfẹ́ ẹ̀rọ yí bíi márun ní àdugbò wọn.

Àwọn ẹ̀rọ wọ̀nyí kìí ṣe àwọn tí ojú ibi tí omi ngbà já’de jẹ́ kékeré rárá!

Ka Ìròyìn: Ọmọ-Alade Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá Ṣe Àlàyé Nípa Ìbò Dídì Ní D.R.Y

Nṣe ni ojú ihò ẹ̀rọ náà tó’bi dáradára tí ó sì jẹ́ wípé agbára tí omi náà fi nrọ́ já’de, ó pọ̀ dé ibi wípé tí ó bá jẹ́ ife ni o mú dání l’ati fi gba omi, agbára omi tí ó nrọ́ já’de yí á gba ife náà bọ́ sọnù sí’lẹ̀ ní ọwọ́ rẹ tí o kò bá dìímú dáradára.

Bẹ́ẹ̀ náà ni ó jẹ́ wípé, omi yí mọ́ gaara tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ wípé, a má a ngbọ́ fírífírí ohun àmúsọ-omi-di-dídára, èyíinì, chlorine, tí wọ́n fi fọ omi náà mọ́ tí ó fi ṣe gaara.

Ìwọ̀nyí ni l’ara ohun àmáyédẹrùn tí ó ti fi ìgbà kan wà rí ní ilẹ̀ Yorùbá.

Nísiìyí tí Olódùmarè ti ràn wá l’ọwọ́ tí a ti gbé ìjọba wa wọ’lé, ọ̀pọ̀l’ọpọ̀ ànfààní báwọ̀nyí ni orílẹ̀-èdè Yorùbá yíò máa jẹ.

Ẹ̀yin ẹ jẹ́ kí á lé agbésùnmmí Nigeria já’de ná kúrò l’orí ilẹ̀ wa; nígbànáà ni ẹ ó wá rí ohun rere tí orílẹ̀-èdè Yorùbá yíò gbé ka’lẹ̀ fún ìgb’áyégbá’dùn ọmọ Yorùbá. 

Lẹ́hìn òkùnkùn biribiri, ìmọ́lẹ̀ á tàn.