Àwọn ilé ìgbìmọ̀ ìjọba Aṣòfin ilú Ghana mà ti kó sí wàhálà báyi, nítorí bí wọ́n ti ngbọ́ ohun tí ó nṣẹlẹ̀ ní ìlú Kenya si olórí orílẹ̀ èdè ìlú Kenya náà. Àwọn ọ̀dọ́ Kenya ti fi ipá lé ìjọba kúrò lórí apèrè rẹ̀. 

Inú Ìbẹ̀rù Tí Ó Ní Agbára Ni Àwọn Oní Ìbàjẹ́ Aṣòfin Oríléẹ̀ Èdè Ilú Ghana Wà Báyi O.

 

Tí ó bá ṣe wípé àwa ọmọ aládé, I.Y.P, ti D.R.Y. náà ti dìde sí àwọn tí wọ́n fi tipá jẹ gàba sí Sekitéríatì Yorùbá ni, inkan ọ̀tọ̀ ni àwa ọmọ aládé, I.Y.P. kò bá máa sọ báyi. Nítorí wípé Yorùbá bọ̀, wọ́n ní wípé ‘Má fi oko mi dá nà, ọjọ́ kan ni ènìyàn ma nkọ̀.

Gẹ́gẹ́bí màmá wa, Modúpẹ́ọlá Onítirí-Abíọ́lá, ṣe sọ fún àwa ọmọ D.R.Y. wípé, ẹnikẹ́ni tí ó bá wà ní ipò ìjọba ní orílẹ̀-èdè Yorùbá, D.R.Y., tí kò bá ṣe nkan tí ó tọ́ fún ará ìlú, gẹ́gẹ́ bí  àdéhùn tó ti dá fún awon I.Y.P., ó ti da ọwọ́ rú nìyẹn, ó di dandan, kí àwa ọmọ I.Y.P. da ẹsẹ̀ rẹ̀ rú.

Inú Ìbẹ̀rù Tí Ó Ní Agbára Ni Àwọn Oní Ìbàjẹ́ Aṣòfin Oríléẹ̀ Èdè Ilú Ghana Wà Báyi O.

Nítorí Orílẹ̀ Èdè wa tuntun yi, D.R.Y., kò ní fi àyè gba inkan rádaràda tí ó ṣẹlẹ̀ ní ìlú Kenya àti ìlú àwọn Aríremáṣe.

Ìdí rè nìyí tí àwa ọmọ Yorùbá, I.Y.P, gbọ́dọ̀ fi ọwọ́ so ọwọ́ pọ̀ láti ṣe iṣẹ́ pẹ̀lú Olórí Adelé àti  gbogbo àwọn adelé yókù láti jẹ́ kí wọ́n wọ inú  Sekiteriati ọmọ Yorùbá, kí agbára le padà sí ọwọ́ gbogbo ará ìlú.