Àsìkò nì yí o! – tí a ní láti ṢỌ́RA gidi!

Ìlú nàìjíríà tún ti gbé àrékérekè wọn dé o! Wọ́n fẹ́ ṣe ìwọ́de láti ọjọ́ kíní, títí dé ọjọ́ kẹ́wa, oṣù kẹ́jọ, ọdún yí, l’atàrí wípé, kí ìjọba Nàìjíríà yé purọ́ lóríi ọ̀rọ̀ subsidy, àti wípé kí wọ́n dá owó epo padà, kí ó má ṣe tó ọ̀ọ́dúnrún naíra (èyíinì, N300), àti wípé kí wọ́n mú owó ilé-ìwé àwọn ilé-ẹ̀kọ́ giga bíi unifásítì, padà sí iye tí ó jẹ́ tẹ́lẹ̀.

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n sọ wípé, àwọn fẹ́ kí ìjọba Nàìjíríà ó dá owó iná mọ̀nọ̀mọ́nọ́ padà sí èyí tí ó máa rọrùn fún ará ìlú láti san.

Ìlú Nigeria Tún Ti Bẹ̀rẹ̀ Àrékérekè Ìwọ́de: Ọmọ Yorùbá, Máse Báwọn L'ọwọ́ Si!

Wọ́n tún wá sọ wípé àwọn fẹ́ kí ìjọba nàìjíríà ó dá owó ìkẹ́rù-wọlé láti òkè-òkun, kí wọ́n dinkù sí iye tí ó wà tẹ́lẹ̀.

Wọ́n tún wá sọ wípé àwọn fẹ́ kí ìjọba Nàìjíríà ó sọ, pàtó, iye gan-an tí àwon senator wọn, àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ aṣòfin apapọ̀, ngbà ní owó-oṣù, àti wípé àwọn fẹ́ kí ìjọba ó dín owó náà kù!

Wọ́n tún wá sọ wípé àwọn fẹ́ kí ìjọba nàìjíríà kí ó gbé owó kalẹ̀ láti fi ṣe ìrànwọ́ fún àwọn oníṣẹ́ àdáni-kékèké.

Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n sọ wípé, àwọné fẹ́ kí àjọ INEC wọn ní ìlú Nàìjíríà, kí ó má ṣe sí lábẹ́ àwọn olùṣèjọba wọn, àti wípé kí wọ́n ṣe òfin tí á fi jẹ́ wípé bí èsì ìdìbò ní nàìjíríà wọn ọ̀ún náà, bá ti njáde, ni wọn ó máa gbe tààrà sí ojú agbagbe ẹ̀rọ ìgbàlódé; bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n sọ wípé àwọn fẹ́ kí ìjọba wọn ní nàìjíríà, kí ó ṣí gbogbo àwọn ibodè wọn (èyíinì, border); wọ́n tún wá sọ wípé ìwọ́de tí àwọn fẹ́ ṣe ọ̀ún tún dá lóríi wípé kí nàìjíríà ó ṣe àtúnṣe lóri àjọ EFCC wọn, àti wípé àwọn fẹ́ kí òfin pàjáwìrì kí ó wáyé, lórí bí ohun gbogbo ti di ọ̀wọ́n-gógó ní ìlú Nàìjíríà; bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n fẹ́ àtúnṣe lórí ètò ìgbẹ́jọ́ ní ilú Nàìjíríà.

  Ìlú Nigeria Tún Ti Bẹ̀rẹ̀ Àrékérekè Ìwọ́de: Ọmọ Yorùbá, Máse Báwọn L'ọwọ́ Si!

Ẹ JỌ̀WỌ́, kí ló kan ọmọ Yorùbá nínú gbogbo rádaràda tí wọ́n kà sílẹ̀ wọ̀nyí? Kí ló kan àwa ọmọ Yorùbá pẹ̀lú nàìjíríà!? Àwọn aláìlọ́pọlọ olóṣèlú nàìjíríà wọ̀nyí kò ní ìbẹ̀rù o!

Nítorí wípé àwa mọ̀ wípé àwọn gan-an ni wọ́n wà ní ìdí àyédèrú ìwọ́de yi; wọ́n fẹ́ fi da ilẹ̀ rú ni: wọ́n fẹ́ kí ẹnikẹ́ni kó má ṣe kọjú sí ọ̀rọ̀ orílẹ̀-èdè Yorùbá mọ́, ṣùgbọ́n wípé kí àwọn ènìyàn máa rí’ra wọ́n gẹ́gẹ́bí “nigeria,” bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé orílẹ̀-èdè olómìnira ti Yorùbá ni wọ́n wà; ṣùgbọ́n wípé kí wọ́n gbàgbé nípa pé Yorùbá ti di orílẹ̀-èdè aṣèjọba-ara-ẹni tirẹ̀ (sovereign nation); kàkà bẹ́ẹ̀, kí ọkàn wọn ó wà ní wípé nàììjíríà ni àwọn, àti wípé àwọn njà fún ìṣèlú-rere ní nàìjíríà ni.

Ṣé àwọn olórí nàìjíríà wọ̀nyí rò wípé bí àwọn ṣe gọ̀, wípé bẹ́ẹ̀ ni Yorùbá gọ̀?

Ẹ JỌ̀WỌ́, GBOGBO ỌMỌ ÌBÍLẸ̀ YORÙBÁ, I.Y.P, ẹ máṣe báwọn lọ́wọ́, rárárárá nínú ìwọ́de kankan! Ẹ má ṣe lọ́wọ́ si rárá! ÌKÌLỌ ti jáde o, láti àwọn aṣáájú ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, wípé orílẹ̀-èdè aṣèjọba-ara-ẹni, òun ni ilẹ̀ Yorùbá jẹ́ o! A kìí ṣe ara Nàìjíríà, o!

Kí onílé kó gbọ́, kó sọ fún toko o! – wípé kò sí nkan-kan tó kan ọmọ Yorùbá, àti ilẹ̀ Yorùbá, nínú ìwọ́dek’iwọ́de tí àwọn ará nàìjíríà fẹ́ ṣe láti ọjọ́ kíní dé ọjọ́ kẹ́wa oṣù kẹ́jọ ọdún yí o! tàbí nígbà míràn pàápàá; ẹ jọ̀wọ́, ọmọ Yorùbá, àwa kìín ṣe nigeria mọ́ o!

Ẹ máṣe darapọ̀ mọ́ ìwọ́de kankan tí ó nííṣe pẹ̀lú nàìjíríà o! A ò kìí ṣe ọmọ Nàìjíríà, bẹ́ẹ̀ ni ilẹ̀ Yorùbá kò sí lára nàìjíríà; kò ní dára, láyé, fún àwọn tí ó wà ní ìdí ọ̀rọ̀ ìwọ́de wọn yí o! Kò ní dára fún yín, nítorí tí ẹ dárúkọ ilẹ̀ Yorùbá mọ́ ibi tí ẹ ti fẹ́ ṣe ìwọ́de ọ̀ràn yín, yíi o!

Ká Ìròyìn Síwájú sí:

Ẹ dárúkọ Èkó síbẹ̀, tí kì dẹ̀ nṣe ara nàìjíríà! Orílẹ̀-Èdè Yorùbá ni Èkó wà, kìí ṣe Nàìjíríà! Kí ẹ gbọ́, dáradára, nítorí wípé, ẹ máa kan ìdin nínú iyọ̀, tí ọmọ Yorùbá kankan bá báwọn kópa nínú ìwọ́de ọlọ́jọ́ mẹ́wa tí wọ́n ní wọ́n fẹ́ ṣe náà, tìtorí èyí lòdì pátápátá, gbáà, sí òfin orílẹ̀-èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y).

Nítorí èyí, ẹnikẹ́ni, tí ó bá jẹ́ I.Y.P (ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá), tí ó bá bá wọn ṣe protest (ìwọ́de) nàìjíríà kankan, ní orí ilẹ̀ Yorùbá, mọ̀ wípé, tìẹ ti bá ẹ o!