Ṣé a tilẹ̀ mọ̀, tẹ́lẹ̀, pé, àti ìgbà tí òyìnbó amúnisìn ti bẹ̀rẹ̀ ìjẹgàba lórí ilẹ̀ Yorùbá, lọ́jọ́ náà l’ọhún ni ohun gbogbo kò ti lọ bí ó ṣe yẹ kó lọ, ṣùgbọ́n, lẹ́hìn èyí tí wọ́n pè ní Òmìnira, ṣebí àwọn tí ó pe’ra wọn ní ọmọ onílẹ̀ ìbá tiẹ̀ ṣe dáadáa; ṣùgbọ́n yàtọ̀ sí àwọn bàbá wa Awólọ́wọ̀ àti àwọn irúfẹ́ wọn tí wọ́n ṣe ohun tí ó dára, tí a dẹ̀ ṣì nfi rántí wọn di òní yí, kíni èyí tí ó pe’ra rẹ̀ ní ààrẹ Nàìjíríà l’oní ṣe fún ìpínlẹ̀ Èkó wa nígbà tí a ṣì wà pẹ̀lú Nàìjíríà, tí ó dẹ̀ jẹ́ òun ni gómìnà Èkó ní’gbà kan rí tó fi nsọ pé òun ni òun mú ìdàgbàs’okè wá sí ìpínlẹ̀ Èko?
Ṣebí eléyi kì bá ti ṣe ọ̀rọ̀ l’oní tí ó bá jẹ́ pé ní kété tí a ti ṣe ìpolongo iṣèjọba-ara-ẹni Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y) ní ọjó kéjìla oṣù igbe, ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rin-lé-lógún, tí a wà nínú rẹ̀ yí, ni ìjọba Nàìjíríà tí k’angárá wọn kúrò lórí ilẹ̀ wa, ṣùgbọ́n, rárá o, àfi jíjẹgàba yíì náà ni wọ́n nṣe, ṣùgbọ́n tí Olódùmarè máa bá wa tì wọ́n jàde l’aìpẹ́ yí.
Èyí ni ó mú kí á m’ẹnu lé ọ̀rọ̀ náà, nítorí fídíò kan tí a rí lórí ẹ̀rọ ayélujára l’aìpẹ́ yí, ó ti ojú sú’ni, nígbà tí a rí ọkọ̀ dánfó kan ní ìlú Èkó, ní’bi tí wọ́n ti fẹ́ r’epo, tí ọkọ̀ náà dàbí ṣálángá tí onílé ti kọ̀ sílẹ̀ láti ọdúnm’ọdún; òun ni a wá wòó pé, ṣé nkan tí wọ́n npè ní ọkọ̀ ní ilẹ̀ ìran ọmọ-aládé náà nì ‘yí?! Háà!
Tí ènìyàn bá fi eléyi kó adìyẹ, ó yẹ ká bínú pé ṣé ó fẹ́ kí àwọn adìyẹ ọ̀ún ṣe àìsàn ni? Ṣùgbọ́n irúfẹ́ ọkọ̀ bẹ́ẹ̀ ni wọ́n nkó ìran ọmọ aládé sí o, ìbá ṣe pé àwọn agbésùnmọ̀mí wọ̀nyí ti kúrò láì ṣe agídí wèrè, kí a ti wọ’lé sí’nú oríkò ilé-iṣẹ́ ìjọba wa ni, tani ẹni náà tí ó tún máa láyà láti gbé irúfẹ́ ọkọ̀ bẹ́ẹ̀ s’orí títì! Ṣùgbọ́n, wọ́n fẹ́, wọ́n kọ̀, wọ́n máa sá kúrò láìpẹ́!
Áà!, ìlú Èkó, àwa nṣe àfẹ́rí rẹẹ! Arómisá-lẹ̀gbẹ-lẹ̀gbẹ́, má ṣàì dá wa l’ohùn-un, kí ó jádé wá láti inú ihò ṣálángá tí ajẹgàba nàíjíríà sọ ẹ́ sí yí!
Ìgbéga rẹ ti de, Ìlú Èkó; àwọn Ìjọba-Adelé wa ti wa ní’kàlẹ̀ẹ̀, – ìlú Èkó, jí dìde kí àwọn ọ̀tá rẹ kí ó parẹ́; jí dìde, kí ajẹgàba nàìjíríà ó pòórá; ìlú Èkó, a nretí rẹ, fi Agbára rẹ hàn, kí ọ̀tá kí ó parẹ́; ògo ọmọ Èkó, àti gbogbo ilẹ̀ Yorùbá, jí dìde, kí a má ṣe rí Nàìjíríà lórí ilẹ̀ wa mọ́! Àsìkò ti tó o; ìlú Èkó, àti gbogbo ilẹ̀ Yorùbá, jáde kúrò lábẹ́ ìjẹgàba agbésùnmọ̀mí nàìjíríà.
A fẹ́ rí Èkó tí ó l’arinrin, Èkó tiwa, kì nṣe èyí tí wọ́n ti sọ di ṣálángá; Èkó, a ndárò rẹ, ìlú Ẹwà, ìlú tó ṣeé fi yangàn níbikíbi ní àgbáyé! Gbé’ra nlẹ̀, kí àwọn ọ̀tá Yorùbá ó sáré kàbàkàbà lọ sí ìparun wọn!
AYÉDÈRÚ ỌTÍ LÍLE TI WÀ NÍ’TA Ò, ỌMỌ YORÙBÁ Ẹ FUN’RA!