Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe gbọ́ọ nínú ìròyìn kan pé, àwọn ènìyàn tí ó ní àìsàn ìtọ̀ ṣúgá ni ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà, ni wọ́n ti pariwo síta o, pé, àwọn oògùn tí àwọn ńlò fún ìtọ́jú ara wọn, èyí tí wọ́n ń rà ní ọ̀kẹ́ mẹ́ta àbọ̀ owó wọn, náírà, tẹ́lẹ̀ ti di ọ̀kẹ́ mẹ́sàn án báyìí o, tí ó sì jẹ́ pé oṣù kan péré náà ni wọn yóò fi ló oògùn yìí.
Èyí ti wá mú kí ó nira fún ọ̀pọ̀ nínú wọn láti ra oògùn yìí, tí àwọn míràn sì ti ń gba ọ̀nà ìbílẹ̀ láti ṣe ìtọ́jú ara wọn, nígbà tí àwọn míràn kò tilẹ̀ lo oògùn mọ́ rárá.
Háà! Ẹ̀yin ọmọ Yorùbá, ṣé ẹ ti wá ríi báyìí pé, kò sí ètò kankan tí àwọn tí wọ́n pe ara wọn ní olóṣèlú ní ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà ní fún ará ìlú wọn.
Kàkà kí ewé àgbọn wọn kí ó dẹ̀, pípele ló ń pele síi. Wọn kò ní àánú àwọn ará ìlú wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni ohun gbogbo nle síi lójoojúmọ́ láarín wọn.
Kò sí iná mọ̀nọ̀mọ́nọ́, kò sí ààbò, ètò ẹ̀kọ́ ti t’ẹnu b’odò, ètò ti ìwòsàn ní ká tilẹ̀ má dárúkọ òun rárá. Síbẹ̀, wọ́n tún dúró lórí ilẹ̀ wa lẹ́yìn tí a ti kéde òmìnira orílẹ̀ èdè wa láti ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbẹ̀wáọdúnóléméjìlélógún, tí a sì ti ṣe ìbúra-wọlé fún olórí ìjọba-adelé wa, Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ, láti ọjọ́ kejìlá oṣù Igbe ẹgbẹ̀wáọdúnólémẹ́rìnlélógún.
Ṣùgbọ́n, kò burú, kí ẹ̀ṣẹ̀ wọn bàa leè pọ̀ síi ni, nítorí pé kò sí èyíkéyìí nínú wọn tí yóò bọ́ nínú ìyà yí rárá.
Ṣùgbọ́n ju gbogbo rẹ̀ lọ, àwa ọmọ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, ẹ jẹ́ kí a máa gbé àṣà ilẹ̀ wa lárugẹ. Ṣèbí lára àṣà wa náà ni ṣíṣe ìtọ́jú ara ẹni pẹ̀lú ewé àti egbò tí Olódùmarè fi fún wa.
Ṣèbí ewé àti egbò yí náà ni wọ́n ń pò papọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bá tún ti fi àwọn nkan tó leè ṣe àkóbá fún àgọ́ ara síi tán, wọ́n á sì tún wá tàá fún ènìyàn ní owó gọbọi. Ní Orílẹ̀-Èdè ti’wa, D.R.Y, a máa lo nkan tí Olódùmarè fún wa láti tọ́jú ara wa.
Nítorí náà, àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá, ẹ jẹ́ kí a dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè tí ó rán ìránṣẹ́ rẹ̀ sí wa ní àkókò yí, Màmá wa Ìyá-Ààfin Modupẹ Onitiri-Abiọla.
Gẹ́gẹ́ bí màmá wa se máa ń sọ fún wa, ètò ìwòsàn ọ̀fẹ́ ní yóò wà fún gbogbo àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá ti Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá. Gbogbo àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, a kú oríire!