Kò kàn wá o! Pé ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà fi kún owó ìwé-ìrìnnà ìlú wọn nítorí pé, ọ̀tọ̀ ni Orílẹ̀-Èdè ti Democratic Republic of the Yorùbá (D.R.Y), ọ̀tọ̀ sì ni Nàìjíríà, ọ̀tọ̀ ni ìwé-ìrìnnà Nàìjíríà, ọ̀tọ̀ ni ìwé ìrìnnà Democratic Republic of the Yorùbá.

Ìlú Agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà Ṣe Àfikún Owó Ìwé Ìrìnnà Ìlú Wọn

Ní kété tí ìjọba adelé wa bá ti wọlé sí àwọn oríkò ilé-iṣẹ́ ìjọba wa gbogbo ní Orílẹ̀-Èdè wa, a máa mọ̀ nípa ìwé ìrìnnà D.R.Y

Láìpẹ́, láìjìnà, a máa rẹ́yìn àwọn agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà; Èdùmàrè á ṣí wọn nídìí kúrò lórí ilẹ̀ wa.

Ìwé ìrìnnà wa ní Democratic Republic of the Yorùbá máa tóó jáde nítorí gbogbo àgbáyé ti mọ̀ wá sí orílẹ̀ èdè olómìnira láti ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbẹ̀wá ọdún ó lé méjìlélógún, tí a sì ti di orílẹ̀-èdè aṣèjọba ara ẹni láti ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbẹ̀wá ọdún ó lé mẹ́rìnlélógún, tí a sì ti búra wọlé fún olórí adelé wá bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọ́kọrẹ́ gẹ́gẹ́bí olórí ìjọba Adelé wá, tí ìjọba wa sì ti bẹ̀rẹ̀.

Màmá wa, Olóyè Ìyá Ààfin Modúpẹ́ọlá Onitiri-Abiọla sì tí jẹ́ kí a mọ̀ pé, Ìwé ìrìnnà tiwa yíò ní àpọ́nlé káàkiri àgbáyé nítorí ọrọ̀ ajé orílẹ̀-ède D.R.Y yóò  dúró dáradára nítorí àwọn àlàkalẹ̀ ìṣèjọba àrà ọ̀tọ̀ tí Olódùmarè ti fi rán màmá wa yìí, àwọn ọ̀dọ́ wa kò ní máa sa kiri láti lọ ṣ’ẹrú mọ́ ní orílẹ̀ èdè mìíràn,káàkiri àgbáyé ni wọn yóò sì máa wá láti  ṣíṣẹ́ tàbí ṣe òwò lórílẹ̀ èdè wa, nítorí t’onílé, t’àlejò ni yóò jẹ ìgbádùn ìsèjọba orílẹ̀ èdè DRY.

Ká Ìròyìn Síwájú sí: