Àwọn ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá ti f’ọhùn já’de o! Wọ́n ní gbogbo Ilẹ̀ Yorùbá, l’ati Èkó dé Ìbàdàn, títí dé Ògùn, dé Ọ̀ṣun, dé Ondó, dé Èkìtì, dé Ìpínlẹ̀ Ìṣèjọba Ọ̀yọ́ (Old Ọyọ Empire; èyí tí àwọn kan mpè ní Kwara àtí Kogi, tẹ́’lẹ̀, ní apá ìwọ̀-oòrùn Odò Ọya); ti ọmọ Yorùbá ni o! Wọ́n ní gbogbo ilẹ̀ tí a dá’rúkọ wọ̀nyí, ti ọmọ Yorùbá ni o! kìí ṣe fún àjèjì kankan!

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

 

Yoruba land belong only to the indigenous people of the yoruba

Ọ̀rọ̀ yí wá ní’gbàtí wọ́n nkìlọ̀ fún ọmọ Íbò kan tí orúkọ rẹ̀ njẹ́, Obi Cubana, ẹni tí ó sọ wípé òun dá ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti nṣe kẹ̀kẹ́ akérò sí’lẹ̀ ní ìlú Èkó l’atàrí wípé òun ní’fẹ́ ìlú!

Òun ni àwọn ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá bá yára da padà fun wípé, àt’òun àti ìfẹ́-ìlú t’ó sọ ‘pé òun ní, ayé wọn máa polúkúrúmuṣu!

Àwọn ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá wá rán Obi Cubana l’etí wípé, a ti sọ́ o! wípé ohunk’ohun tí ẹnik’ẹni bá ṣe, l’orí ilẹ̀ Yorùbá, l’ati ọjọ́ kéjìlá oṣù kẹ́rin ọdún yí, láì sí àṣẹ ìjọba Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá ní’bẹ̀, irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ ti dá ọ̀ràn l’abẹ́ òfin o!

Àwọn ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá wá sọ wípé, l’oòtọ́, kò sí ẹni tí ó sọ wípé àjèjì kò lè dá ilé-iṣẹ́ sí’lẹ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá, ṢÙGBỌN, nínú ohungbogbo, ànfààní ọmọ Yorùbá ni Àkọ́kọ́; èyí tí ó tú’mọ̀ sí wípé, ohun tí Orílẹ̀-Èdè Yorùbá bá fẹ́ fún Ọmọ Yorùbá, ìyẹn l’ó ṣáájú ohun gbogbo! Ní ìlẹ̀ Yorùbá o! kò sí ohun tó njẹ́ kẹ̀kẹ́ ak’erò!

Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá fí àkókò náà tún kìlọ̀ ìrántí fún gbogbo ènìyàn, wípé, gbogbo ẹni tí ó bá npe orúkọ Yorùbá mọ́ náìjíríà, ìparun ni wọ́n nkó ara wọn lọ o! Ṣebí wọ́n ti sọ wípé, a wí fún ni, k’ó tó dá’ni, àgbà ònjàkadì ni.

 

Yoruba land belong only to the indigenous people of the yoruba