Ilé ejọ́ ìgbẹ́jọ́ ìwà ọ̀daràn ní àgbáyé ti dá Al-Hassan Aq-Abdulazeez Aq-Muhammed lẹ́bi. Ó jẹ́ olórí àwọn alákatakítí àti ọ̀kan lára àwọn agbésùmọ̀mí àlkaida.

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X
Ilé Ẹjọ́ Ìgbẹ́jọ́ Ìwà Ọ̀daràn Ní Àgbáyé Dá Ọ̀kan Nínú Àwọn Olórí Agbésùnmọ̀mí Lẹ́bi

 

Wọ́n dáa lẹ́bi fún ìwà ọ̀daràn, ogun jíjà àti ìwà ìkà sí ọmọ ènìyàn ní orilẹ̀-èdè Mali.

Lara ẹ̀suǹ tí wọ́n kà síi lẹ́sẹ̀ ni ìfìyàjẹni, ìṣènìyàn ní jàḿbà to ṣélẹ̀ ní àárín ẹgbẹ̀wáọdúnóléméjìlá àti ẹgbẹ̀wáọdúnólémẹ́tàlá. Yóò tún gba ìdájọ́ lórí ẹ̀sùn ìfipá bánilòpọ̀, inúnibíni, ṣíṣe ìgbéyàwó tipátipá fún ni àti fífi ènìyàn ṣe ẹrú ìbálòpọ̀.

Àwọn olùpèjọ́ sọ pé Al-Hassan jẹ́ òkan gbòógì láàrín àwọn ẹgbẹ́ alákatakítí ẹ̀sìn Islam kan tí ó so pọ̀ mọ́ àlkáídà lakòóokò tí wọ́n ńjẹgàba ní ipò àṣẹ ní agbègbè Àríwá Mali nígbànáà.

Àwọn ẹgbẹ́ yìí fi ọwọ́ agbára ìjẹgàba yi hu ìwà ìgbésùnmọ̀mí nígbà náà. Àwọn ẹgbẹ́ búburú yìí ṣe iṣẹ́ ibi púpọ ní ìlú Timbuktu.

Ìdájọ ẹ̀bi yìí ti ṣí asọ lórí ọ̀rọ̀ kan tó lágbára báyìí, tí ìjọba Mali ńfi ẹ̀sùn kan orílẹ̀-èdè France pé ó ńṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àti àtìlẹ́hìn fún àwọn agbésùnmọ̀mí ní Mali.

Olórí adarí ìjọba Mali Choguel Kokalla Maiga wípé ẹ̀rí tó dájú fihàn pé ọmọ ogun France dá agbègbè ìkọ̀kọ̀ kan silẹ̀ ní Kidal ní Àríwá Mali tí wọ́n fà lé ẹgbẹ́ Ansar Aldeen, tí ó ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn alkáídà.

Maiga sọ fún àwọn oníròhìn wípé, “Wọ́n ní àwọn ẹgbẹ́ agbébọn tí ó gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ ọmọ ogun France, ẹrí tó dájú wà. Èyí kò yé wa, a kò lè fara dàá.

Láti Libya ni àwọn ẹgbẹ́ agbébọn yìí ti wá, wọ́n kò fí àyè sílẹ̀ fún ọmọ ogun Mali lati dé ọ̀dọ̀ wọn.

Ọ̀rọ̀ náà le dé ibi pé Orílẹ̀-èdè Mali lé àwọn ọmọ ogun France, ikọ̀ ìlú France ati àwọn ọmọ ogun apẹ̀tù sí aáwọ̀ láti Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé nitori ogun àwọn agbésùnmọ̀mì náà le síi lábé àkóso àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta.

Ilé Ẹjọ́ Ìgbẹ́jọ́ Ìwà Ọ̀daràn Ní Àgbáyé Dá Ọ̀kan Nínú Àwọn Olórí Agbésùnmọ̀mí Lẹ́bi

 

Bí ilé ẹjọ́ àgbáyé ti fẹ́ rán Al-Hassan lọ sí ẹ̀wǒn gbére fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ báyìí, ìberè ti o ṣẹ ní Mali, ibéèrè ni pé tani àgbáyé ma mú pé ó ńgbówó sílẹ̀ tí ó sì ńṣe ìdánilèkọ̀ọ́ fún àwọn agbésùnmọ̀mí tí ó ti ńgbìyànjú lati da gbogbo àgbègbè saheli lápapọ̀ rú láti ọdún púpọ̀ yí wá.

Ìṣẹ̀lẹ̀ yí ń fihàn bí ọ̀rọ̀ Mali àti gbogbo agbègbè saheli ti lọ́júpọ̀ tó, pèlú oríṣiríṣi àwọn ìwà ìmọtara ẹni àti ẹ̀sùn ṣíṣe àtìlẹ́hìn fún agbésùnmọ̀mí jẹ́ kí ó nira láti dojú ìjà kọ àwọn alákatakítí.

Ìròhìn yí dúró bí ìkìlọ̀ fún agbésùmọ̀mí àti àjẹgàba Nigeria lórí ìlẹ̀ àwa Democratic Republic of the Yoruba, pé wọ́n á jẹ ìyà ẹ̀sùn yìí ní ilé ẹjọ́ àgbáyé fún gbogbo ìwà ìjegàba àti ìgbésùnmọ̀mí tí wọ́n ń hù lórí ilẹ̀ wa.

Kò ní pẹ́ mọ́, ayọ̀ wa ti dé.