Ìkọjá Àyé!: Gómìnà Naijiria, Babajide Sanwoolu Ṣe Àtúbẹ̀rẹ̀ Ètò Ìmọ́tótó Àyíká Oṣóosu L'èkó

Ìwé ìròhìn kan gbée jáde pé gómìnà Naijiria tó ńjẹgàba lórí ìpínlẹ̀ Èkó ni Democratic Republic of the Yorùbá, Babajide Sanwoolu ti fi àṣẹ sí ídápadà ètò ṣiṣé ìmọ́tóto àyíká olóṣosú  ni ìpínlẹ̀ náà.

ÀKÍYÈSÍ PÀTÀKÌ LÓRÍ AWUYEWUYE ÀTI ÌṢẸ̀LẸ̀ TÓ NṢẸLẸ̀ KÁÀKIRI LÓRÍLẸ̀-ÈDÈ YORÙBÁ, LÁTI ORÍ NKAN Ọ̀GBÌN OLÓRÓ, ÀTI ÌGBÀLÁÀYÈ ÌBÁLÒPỌ̀ ỌKÙNRIN-SỌ́KÙNRIN, TÀBÍ OBÌNRIN-SÓBÌNRIN, TÍ ÌJỌBA ORÍLẸ̀-ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ ṢAGBÁTẸRÙ RẸ̀, TÍ Ó SÌ NJẸGÀBA… Share on X Kọmiṣọ́ná wọn fún àyíká àti ọrọ̀ omi, Tòkunbọ̀ Wahab ló sọ èyí di mímọ̀, ó sì tún wípé ìgbìmọ̀ aláṣẹ wọn ti fí àṣẹ sí pé kí ètò olóṣoṣù náà bẹ̀rẹ̀.

Ṣùgbọ̀n o wipe léìpẹ́, gómìnà wọn ní yíò kéde ètò náà tí yíò bẹ̀rè ní ìparí oṣù Agẹmọ .

“Gómìnà Naijiria tí ńjẹgàba lórí ìpínlẹ̀ Èkó, Babajide Sanwoolu pẹlú àwọn tí wọ́n pe ara wọn ní ìgbìmọ̀ aláṣẹ ìpínlẹ̀ tí fí àṣẹ sí ìdápadà ètò ìmọ́tóto olóṣoṣù.”

“Gómìnà ajẹgàbá náà yíò kéde rẹ̀ láti bẹ̀rẹ̀ loṣù yí.” Wahab fí èdè Yorùbá sọ̀rọ̀ yí lori ojú òpó X ìkéde ti ìpínlẹ̀ Èkó fún Àyíká.

Ìwé ìròhìn kan wípé ni ẹgbẹwáọdúnólémẹ́rìndínlògùn ni won dá ètò ìmọ́tóto àyíká náà dúró tẹ́lẹ́

Ìjọba wọn wípé wọ́n dá ètò wákàtí mẹ́ta mẹ́ta ososu náà dúró nigbayẹn fún àtúnṣe.

Ìdápadà ètò ìmọ́tóto àyíká náà yíò jẹ nítori omiyale tí o ṣẹlẹ̀ lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí nílu Èkó nígbàtí òjò bíi wákàtí mẹ́sàn sí méjìlá da Èkó láàmú pẹlú àgbàrá tí ọ wó ilé kan ní Mushin, tí o sì bá dukia jẹ́ káàkiri ìpínẹ̀ Èkó, láì sọ tí ẹ̀mí tí o sọnù.

Ìkọjá Àyé!: Gómìnà Naijiria, Babajide Sanwoolu Ṣe Àtúbẹ̀rẹ̀ Ètò Ìmọ́tótó Àyíká Oṣóosu L'èkó

Gbogbo ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá nsọ fún ìjọba agbésùnmọ̀mí Naijiria tó ńjẹgàba lórí ilẹ̀ wa pé kí wọ́n kúrò ní orílẹ-èdè wa, gbogbo ẹ̀mí tí ó sọnù nínú òjò àti omíyalé tí o kọjá yìí ẹ̀bi ìjẹgàba wọn ni.

Tí a bá ti ṣi Naijiria búburú yìí nídìí kúrò lórí ilẹ̀ wa, ìjọba wa ní ètò tí o dára láti dẹ́kun gbogbo irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ búburú yìí, a ò bẹ̀ wọ́n níṣẹ́ kankan nítorí gbogbo ohun tí a nílò láti ṣe ọ̀nà ati kòtò nínù geerege wà ní orílẹ-èdè wa. Bitumen pọ̀ ní ìpínlè Ondó, a ni èroja fún cement ni ipinlẹ Ogun, a sì tún ní àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tó dangajia fún gbogbo iṣẹ ilé wà. 

Democratic Republic of the Yorùbá kò sí lára Naijiria, nítorí nàà, gbogbo àwa ọmọ aládé níláti fi ọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn Adelé wa láti lè àwọn ìkà wọ̀nyí dànù kúrò lórí ilẹ̀ àjogunba wa  kí wọ́n yé ṣe ìpalára fún orílẹ-èdè wa àti àwa ọmọ I.Y.P.

Ká Ìròyìn Síwájú sí: