Ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá, BLACK LION, abúramúramù kìnìún dúdú tí ó ní ìfẹ́ ìran rẹ̀, ti ṣe ìkìlọ̀ tí ó l’agbára já’de fún àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá. Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ọ̀rọ̀ tí BLACK LION sọ ni a mú wá fún yín ní àkókò yí: ẹ máa bá wa ká lọ:

“Mo kí gbogbo ọmọ Yorùbá ní’lé, l’oko, ní’bi tí gbogbo wa bá wà l’oni.

“Mo wá l’ati ṣe ìkìlọ̀ fún gbogbo wa tí a nṣ’iṣẹ́ ní abẹ́ OMINIRA YORÙBÁ 2022; àwa tí a nṣ’iṣẹ́ fún Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y), wípé kí á ṣọ́’ra.

“Àkọ́kọ́, àkíyèsí mi, pàtàkì, ni wípé, a rí àwọn tí ó jẹ́ wípé wọ́n nta’fà s’okè, wọ́n á wá yí’dó bo’rí. Wọ́n ti wà nínú àwa tí a jọ nṣ’iṣẹ́ ìrìn-àjò yí. Kí Ọlọ́run ọba aláanú, kí ó wá ṣí irú àwọn ẹ̀dá bẹ́ẹ̀, kí ó wá fi wọ́n hàn sí gbangba àgbáyé.

“Ìdí tí mo fi sọ ọ̀rọ́ yí ni wípé, oríṣiríṣi ni mo ti gbọ́ t’ó nṣẹ’lẹ̀; ṣùgbọ́n nígbàtí Ọlọ́run bá ti sọ wípé òun ni òun nrin ìrìn-àjò, kò sí ẹ̀dá náà tí ó lè da dúró. Tí Ọlọ́run bá sọ wípé òun nlo ẹni báyi-báyí, wípé k’ó ṣe irúfẹ́ iṣẹ́ báyi-báyi, kò sí ẹ̀dá tí ó lè da dúró.

“L’oótọ́, kò sí ẹ̀dá tí ó pé tán; bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹ̀dá t’ó mọ̀ọ́ ṣe tán. Èèyàn ni wá; ẹlẹ́ran ara dẹ̀ ni wá.

“Mo wá rí wípé, èyí tí ó pọ̀jù l’ara àwa tí a nṣ’iṣẹ́ l’abẹ́ ìrìn-àjò yí; ọ̀tẹ̀, ìlara, ìbànìyànjẹ́, ti wà nínú ẹ̀. Òun ni mo ṣe pe ọ̀rọ̀ mi yí ní ÌKÌLỌ̀; wípé, kí gbogbo wa kí á ṣọ́’ra. Ìkìlọ̀ ni.

Ìkìlọ̀ Ré O! L'ati Ọwọ́ Black Lion

 

“Mi òì tíì fẹ́ sọ ọ̀rọ̀ púpọ̀ jù, ṣùgbọ́n mo ní kí nwá ṣe ìkìlọ̀ ná; ṣùgbọ́n t’ó bá d’ojú ẹ̀, àá sọ ojú abẹ ní’kó pátápátá; tí kò dẹ̀ tíì yá rárá nísiìyí. Ohun tí àwọn èèyàn dẹ̀ nfẹ́ ni pé kí èèyan sọ ojú abẹ ní’kó nísìnyí, kí wọ́n wá r’ayè fi ìyẹn gbé ojú wa kúrò ní ọ̀gangan ibi tí a nlọ. Èmi ò dẹ̀ wá ní fún yín l’ayè ìyẹn. Àsìkò ọ̀rọ̀ máa tó sọ, kòì tíì yá ni. Ẹ ní sùúrù. Ó nbọ̀.

“Mo fẹ́ sọ fún gbogbo ẹ̀yin tí ẹ máa njẹ́ wípé ọ̀rọ̀ àbòsí ni ẹ máa nsọ l’ẹhìn. Àkọ́kọ́, kí ẹ pa’rọ́ mọ́’yàn; kí ẹ ṣe ẹ̀dá irọ́, inkan tí kò rí bẹ́ẹ̀; ẹ̀ẹ́ kàn gbé irọ́ ka’lẹ̀, tí kò ti’lẹ̀ jọ mọ́ ẹni náà; tí ẹ ò ti’lẹ̀ mọ ẹni náà rí; ẹ̀ẹ́ gbé irọ́ ka’lẹ̀, ẹ̀ẹ́ máa tàá. Ìbẹ̀ ni àwọn kan wá wà, tí ó jẹ́ wípé, irọ́ yẹn ni àwọn máa nrà kiri ní ti’wọn! Tìt’orí kíni? Tìt’orí wípé, àwọn náà wà nínú ẹgbẹ́ kí wọ́n máa ba ọmọ’n’ìkejì jẹ́; kí wọ́n máa gbé ọmọ’n’ìkejì wá’lẹ̀.

Kìí ṣe wípé wọn ò mọ̀ o! Wọ́n mọ̀ọ́-mọ̀ ni o, t’orí èròngbà oníkálukú, ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni. Ọba arí’nú-r’ode ni Ọlọ́run Ọba. Gbogbo ẹ̀dá t’ó bá nṣe bẹ́ẹ̀, ìbáà ṣe èmi pàápàá, nínú ìrìn-àjò yí, kí Ọlọ́run ó gbé mi sí’ta gbangba sí gbogbo àgbáyé – kí ọmọ Yorùbá ri wípé alábòsí ni mí.

“Àdúrà tí mo níí’gbà fún yín; gbogbo ẹ̀yin tí ẹ nṣe irú ìwà yẹn nínú ìrìn-àjò yí n’ìyẹn – kí Ọlọ́run kí ó tú yín sí’ta gbangba sí gbogbo àgbáyé, kí ọmọ Yorùbá ri wípé alábòsí ni yín.

“Mo tún wá ṣe àkíyèsí, wípé, gbogbo àwọn tí ó ti bẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjò yí; tí wọ́n ti nṣe ìrìn-àjò yí; tí wọ́n ti ṣé dé’bi t’ó dé ní òní yi; bí àwa ẹ̀dá kò bá kan sárá sí wọn, Ọlọ́run kan sárá sí wọn – àwọn t’ó gbe dé’bi t’ó dé ní òní yi, l’oríṣiríṣi, l’abẹ́’lẹ̀; gbogbo àwọn tí ó nṣiṣẹ́ lábẹ́lẹ̀.

Gbogbo ohun iṣẹ́ rere tí wọ́n nṣe l’abẹ́’lẹ̀, tí ẹ nrí t’ó njá’de l’oní yi, àwọn kan l’ó wà ní’dí ẹ̀ – àwọn ọmọ Yorùbá. Wọ́n pọ̀ gan ní’dí ẹ̀. Àwọn t’ó nṣe àbòsí, tí wọ́n nṣe ọ̀dàlẹ̀ wà nínú wọn tí a dẹ̀ ti yọ àwọn yẹn dànù – tí Ọlọ́run fún’ra rẹ̀ yọ wọ́n dànù, tí a dẹ̀ rí wọn.

“Tí ó bá jẹ́ wípé àbòsí ni èèyàn nṣe ni, àwọn tí wọ́n ngbé ìrìn-àjò yí, tí wọ́n nṣ’iṣẹ́ l’abẹ́’lẹ̀, wọn kì bá ti dé’bi tí wọ́n dé, l’oní. Ẹ ẹ̀ lè wá máa dá’ná irọ́ l’orí wọn, tí kò dẹ̀ rí bẹ́ẹ̀; tí ẹ ò dẹ̀ rí ẹ̀rí gbé bọ́ sí’ta. Ẹ wá fẹ́ kí nla ojú mi sí’lẹ̀, kí nmá s’ọ̀rọ̀ le l’orí. Ẹẹ̀ lè ri ṣe o!

“Ẹni tí Ọlọ́run bá rán ní ìrìn-àjò yí, t’ó fi lé l’ọwọ́ wípé k’ó ṣe apá kan, k’ó ṣ’iṣẹ́ díẹ̀ ní’bẹ̀, Ọlọ́run tí ó fun ṣe, á ràn-án l’ọwọ́. Ìwọ ẹ̀dá t’ó bá rò wípé o fẹ́ fa ẹni yẹn wá’lẹ̀, wàá fa ara ẹ wá’lẹ̀ ‘gbẹ̀hìn ni, wàá dẹ̀ ṣ’ẹ̀sín àgbáyé.

“Mo máa nsọ wípé, ìrìn-àjò yí, ìrìn-àjò ẹ̀mí ni; kì nṣe ti ara. Ẹ̀yin kan á kàn dá’ná irọ́, ohun tí kò ṣẹ’lẹ̀, ẹ̀ẹ́ kàn rọọ́ bí ẹni nrọ irin, ẹ̀ẹ́ dẹ̀ wá fọn sí’ta! Tìt’orí wípé ẹ fẹ́ fi gbé ẹnìkejì wá’lẹ̀. Ohun tí kò dára ni. Òun ni mo ṣe sọ wípé ìkìlọ̀ ni eléyi. Aò fẹ́ irú ìwà bẹ́ẹ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá. Aà fẹ́ wípé kí á tún máa jẹ’ra wa l’ẹsẹ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá.  Aà fẹ́ ìwà kí á máa ta’fà s’okè, k’á wá yí’dó bo’rí. Aà fẹ́ máa bá èèyàn fẹ ẹyín, kí o máa tu’tọ́ funfun sí ìta, tí ó dẹ̀ jẹ́ wípé nṣe ni inú ẹ, nṣe l’ó dúdú. Eléyi kò dára. Àtubọ̀tán alábòsí, kò kì ndára.

Ìkìlọ̀ Ré O! L'ati Ọwọ́ Black Lion

 

“Mo gbọ́ oríṣiríṣi. Wọ́n ní àwọn kan nwá’ṣẹ́ fún àwọn kan; àwọn kan ti tò fún iṣẹ́, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀. Ìkan sọ wípé Black Lion máa fi wọ́n sí’pò. Mo wá sọ l’oní, ẹnik’ẹni t’ó bá mọ̀ wípé òun bá mi sọ́, tí mo dẹ̀ sọ fun wípé nmáa fún ọmọ ẹ, tàbí màá fi òun sí’pò, k’ó bọ́ sí’ta. Tí ẹni náà kò bá bọ́ sí’ta, kò níí ṣ’orí ire. Ẹni tí kò bá lè bọ́ sí’ta wípé Black Lion ṣe ìlérí fún òun nípa ohun bái-bái, ẹni náà kò ní ṣe orí-ire.

“Ẹ̀yin tí ẹ wò wípé àwọn tí ó nṣ’iṣẹ́ ìrìn-àjò yí, tí ẹ máa nrò wípé àwọn nìkan ni wọ́n ndá ṣeé, tí ẹ ti wá mọ̀ wípé kì nṣe àwọn nìkan ni wọ́n ndá ṣeé, òun l’ẹ ṣe ntadí’nà àwọn tí wọ́n nṣeé dé’bí t’ó jẹ́ wípé ìrìn-àjò yí fi dé ibi t’ó dé ní òní yí. Nít’orí ìlara ni ẹ dẹ̀ ṣe nṣe eléyi.

“Nít’orí náà, ni mo ṣe sọ wípé, ní ti òní, mo wá ṣe ìkìlọ̀ ni.

“Mo fi títóbi Ọlọ́run bẹ ẹ̀yin ọmọ Yorùbá, pátápátá, ẹ jẹ́ kí a ṣọ́’ra. Ẹnu dídùn; ètek’ete – ìwà tí kò dára, tí a ò sì fẹ́ ní ilẹ̀ Yorùbá n’ìyẹn. Inkan t’ó sún àwọn baba baba ti’wa, l’ayé ọjọ́’un, tí wọ́n ṣe, l’aárín ara wọn, òun ni ẹ tún fẹ́ bẹ̀rẹ̀ yí! Ẹ jẹ́ kí á ṣe àkíyèsí, eléyí kò dáraà!

Tí ó bá jẹ́ wípé irúfẹ́ ìwà bẹ́ẹ̀ dára ni, ilẹ̀ Yorùbá kò ní wà ní’bi t’ó wà l’oní yi; kò ní wà bí ó ṣe wà, rádaràda, l’oní yi. Tìt’orí àbòsí, ọ̀dàlẹ̀, irọ́, òun l’ó sún Yorùbá dé ibi tí a wà ní oni! Ẹ má tún gbé ‘yẹn wá sí orí ilẹ̀ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y). Ẹ má gbe wá sí’bẹ̀. Ìyẹn ni a ò ní gbà! Ẹ máṣe gbe wá rárárárá. 

“Ẹni tí ó bá rò wípé wọ́n fẹ́ fún òun ní’ṣẹ́, tí wọ́n lọ nṣe’lérí fún ẹ – bóyá o ti sọ fún wọn wípé ‘ọmọ mi ti ṣe’tán o, ẹ má gbàgbé ọmọ mi,’ tí ẹnìkan wá nṣe ìlérí iṣẹ́ fún yín, wọ́n ntàn yín ni o! T’orí, iṣẹ́ pọ̀ n’lẹ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá gan-an ni, fún gbogbo ọmọ Yorùbá t’ó fẹ́ ṣ’iṣẹ́. Kò sí ẹnik’ẹni t’ó lè sọ wípé òun nwá’ṣẹ́ l’ọwọ́ ẹnik’ẹni. Ẹni kankan kò lè fún yín ní’ṣẹ́! Ẹni kankan kò lè mú yín mọ ẹni kankan!

Ọlọ́run Ọba nìkan ni ó wà fún gbogbo wa. Òun ni ó máa nṣí’nà fún’ni. Ẹ̀dá nmú ẹ mọ’ni, ìyẹn ò ní ọjọ́ ‘wájú nínú. Nítórí náà, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ nsọ’rọ̀ k’ẹnìkan máà fi yín mọ ẹnìkan, tí ẹ nsọ wípé ẹ mọ Black Lion, kò s’ọnà n’bẹ̀! Ẹ nfi orúkọ mi sọ oríṣiríṣi káàkiri, ẹ npa irọ́ inkan tí mi ò sọ! Àti eléyi tí kò tilẹ̀ ṣẹlẹ̀ – ìyẹn ló máa nbí mi nínú jù! Wọ́n á dá’ná irọ́!

“Ọ̀tá pọ̀! bí wọ́n ṣe máa gbé ẹnìkejì ṣubú ni wọ́n nwá kiri. Pàápàá, àwọn t’ó bá nṣ’iṣẹ́ nínú ìrìn-àjò yí. Àwọn míì wà, t’ó jẹ́ wípé wọ́n fi ohun ìní wọn, iṣẹ́ wọn, gbogbo àyè wọn, wọ́n fií sí’lẹ̀ l’orí ìrìn-àjò yí; àwọn míì wà tí ó jẹ́ wípé orí ìrìn-àjò yí ni gbogbo ẹ̀mí wọn dúró lé lórí; ẹ̀ẹ́ wá máa bà wọ́n jẹ́ kiri; ẹ̀ẹ́ máa pa’rọ́ mọ́ wọn kiri; oun tí kò rí bẹ́ẹ̀. Ẹẹ̀ dẹ̀ lè gbé ẹ̀rí gbogbo ohun tí ẹ nsọ kiri, sí’ta! gbogbo àbòsí tí ẹ nṣe l’ẹhìn.

“Ohun tí kò yé ‘yín pọ̀; ó máa yé yín t’ó bá yá o! – wípé, Ọlọ́run l’ó nrin ìrìn-àjò yí; ìrìn-àjò ẹ̀mí ni. Gẹ́gẹ́bí màmá wa, Modúpẹ́ọlá Onítirí-Abíọ́lá ṣe máa nsọ, ìrìn-àjò ẹ̀mí ni; kì nṣe ìrìn-àjò lásán. Nítórí náà, ẹ̀yin tí ẹ bá rò wípé ẹ fẹ́ gbé eré ọpọlọ, tí ẹ rò wípé ẹ ní ọpọlọ, wípé ẹ lè ṣe àbòsí kí ẹ fi dé ibi tí ẹ fẹ́ dé; àti wípé ẹ lè parọ́, ẹ lè ba ti èèyàn jẹ́, kí ẹ lè dé ipò, kí ẹ lè dé ibi tí ẹ fẹ́ dé; ẹ ntan ara yín ni o! kì nṣe lórí ìrìn-àjò yí ni ẹ ti máa rí ìyẹn ṣe. Torí Ọlọ́run fún’ra rẹ̀ máa yẹ̀yẹ́ ẹ, sí ìta gbangba àgbáyé ni. Gbogbo ohun tí o nrò lọ́kàn, Ọlọ́run máa tu síta. Òun ni wọ́n ṣe nwípé Ọlọ́run ọba, ọba mi, ọba okè, wípé ọba adáni wáyé mágbàgbé, arínú-róde, olùmọ̀ràn-ọkàn ni, tó nrin ìrìn-àjò yí. 

“Ẹni tó bá gbọ́n nínú yín, ẹ jẹ́ lọ ṣọ́ra; òun ni mo fi sọ wípé ìkìlọ̀ ni. Ẹ lọ wo gbogbo àwọn tí ó rin ìrìn-àjò yí ní ìrìn àbòsí, tí ẹ̀dá kò rí, tí ó jẹ́ wípé ojú la rí, a ò rí inú, ṣùgbọn tí Ọlọ́run dẹ̀ tú gbogbo wọn síta nínú ìrìn-àjò yí. Láti ìbẹ̀rẹ̀, ẹ lọ wòó. 

“Ẹ̀yin tí ẹ ngbé irúfẹ́ ọwọ́ yẹn, mo wá fún yín ní ìkìlọ̀, ní pàtàkì jùlọ, ẹ̀yin tí ẹ nṣiṣẹ́ nínú ìrìn àjò yí. Ẹ ṣọ́ra yín. Ọlọ́run ló ngbé ẹ̀dá ga, kò nṣe èèyàn. Ọlọ́run ló nfún ẹ̀dá nípò, kò nṣe èèyàn. Ohun tí Ọlọ́run bá fún èèyàn, ìwọ ẹ̀dá tó bá ngbìyànjú, tó nwá bóo ṣe máa gbé ẹni yẹn wálẹ̀, bóo ṣe máa fàá ṣubú, bóo ṣe máa ba tiẹ̀ jẹ́ lẹ́hìn, àṣírí ẹ kò ní bò – pẹ̀lú àṣẹ Ọlọ́run.

“Mi ò fẹ́ sọ̀rọ̀ jù. Mo mọ̀ wípé Ọlọ́run ọba ni ọba ẹlẹ́san, mò dẹ̀ mọ̀ wípé òun ni Ọba tí ó máa dá ẹjọ́; tó máa dá ẹjọ́ a fi eyín pẹ́ran; òun náà ló máa dá ẹjọ́ àwọn “ojú larí, ọ̀rẹ́ ò dé’kùn.

“Mo fẹ́ ṣ’ẹnu kò. Mi ò fẹ́ tíì lọ jìnnà, lorí ọ̀rọ̀ yí. Ìkìlọ̀ ni mo pèé.

“Gbogbo èyí tí ẹ nṣe, tí ẹ fẹ́ fi gbé ojú wa kúrò ní ọ̀kánkán ibi tí a nlọ nínú irìn àjò yí, ẹẹ̀ lè ríi ṣe. Mo ti sọ tẹ́lẹ̀ rí, mo ní ìrìn àjò yí, tí ìwọ bá gbe ní ọ̀hún, ẹni tibí gbe ní àárín, ẹni tọ̀hún yẹn fàá ní igun kejì, ìkan tún fàá nísàlẹ̀, ìkan gbe lókè, ìkan gbe ní àárín, kò dí ẹnikankan lọ́wọ́.

Ohun tí Ọlọ́run bá ti fi sí ọkàn oníkálùkù, ni kó ṣe nínú ìrìn àjò yí, tí ó jẹ́ ohun rere, tí ó máa ran ìrìn àjò yí lọ́wọ́, kì nṣe eléyi tó máa dàárú. Ẹni tí ó ngbe ní apá gúùsù l’ọhún l’ọhún, ìwọ tí o wà ní àríwá, o bẹ̀rẹ̀ sí yọjú sí ẹni tí ó nṣiṣẹ́ ní gúùsù, tí kì dẹ̀ nṣe wípé ẹni yẹn tako ìrìn àjo, tí kò ṣe màdàrú kankan, tí ẹ dẹ̀ nba tiẹ̀ jẹ́, tí ẹ ṣáà fẹ́ gbe wálẹ̀. Torí kíni? Ṣé, àwáìlọ ni ilé ayé ni?

“Ìdí nìyẹn tí wọ́n ṣe máa nsọ nígbà míì, wípé, tí ẹrú bá di ọba, ó máa tẹ’lẹ̀ bàṣù bàṣù ni. Ẹlòmíràn, nínú ìrìn àjò yí, ó dà bí idán (magic) ni lójú ẹ̀. Ìṣe wípé èmi náà fẹ́ jẹ́ nkan báyi-báyi, mo fẹ́ jẹ́ nkan t’ọ̀hún, òun ni wọ́n nṣe, kí wọ́n le mọ̀ wọ́n. Òkìkí tí gbogbo wọn nwá. Òun ni wọ́n ṣe máa nsọ wípé èmi máa nkó gbogbo ẹ̀ mọ́’yà. Wọ́n ní mo nfa gbogbo ẹ̀ s’orí. Ṣùgbọ́n, kò lè yé ‘yín. Bí Ọlọ́run ṣe rán oníkálukú, ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni. Ọlọ́run ló nṣeé, kì nṣèèyàn. Ọlọ́run tó gbe sí mi láyà, tó gbe sí mi lórí, òun náà ló nbá mi gbe.

“Nítorí náà, mo fẹ́ ṣe eléyí ní ÌKÌLỌ̀. Ẹ ṣọ́ra. Ẹ̀yin ọmọ Yorùbá, ẹ jẹ́ kí a jí; kí a má sùn. Ẹ jẹ́ kí á ṣọ́ra. Aà gbọ́dọ̀ gba ohunkohun láyè, níbi tí a ba dé yí, tí ó máa gbé ojú wa kúrò ní ibi tí a nlọ. Aà nílò kí á máa fa àwọn tó nṣiṣẹ́, kí á máa fa ẹlòmíì wálẹ̀, lórí nkan tí kò tó nkankan. Mi ò fẹ́ irúfẹ́ ìwà bẹ́ẹ̀.

“Lọ́dọ̀ tèmi, bí Ọlọ́run tèmi ṣe sọ, ni mo sọ fún yín yẹn o. Èmi ò fẹ́ irú ìwà wọ̀nyẹn. Mi ò ní rí ẹnikeyì tó ngùnkè, tàbí ó mọ nkan íṣe, kí nwá ní mo fẹ́ gbe wálẹ̀; mi ò níí báwọn lọ́wọ́ nínú irúfẹ́ ìwà bẹ́ẹ̀, láyé! Mi ò ní bá wọn ṣe’rú ẹ̀. Mi ò kì nsí níbi ìbàjẹ́. Ṣùgbọ́n tí ó bá jẹ́ wípé, wọ́n fún mi ní iṣẹ́, tí mo dẹ̀ sọ wípé, BÁYI ni wọ́n ṣe ní kí a ṣé; ìwọ ṣe báyi, ìwọ ṣe báyi, tí mo wá ri wípé o fẹ́ gbàbọ̀dè, màá yọ ẹ́! 

“Tí mo bá ri wípé, iṣẹ́ tí wọ́n dẹ̀ gbé fún ẹ, oò lè ri ṣe, màá yọ ẹ́! màá gbé ẹlòmíràn tí ó le ṣe iṣẹ́ náà síbẹ̀! Tìtorí, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù ni àwọn ọmọ Yorùbá. A pọ̀. 

“Bí mo ṣe máa nṣiṣẹ́ nìyẹn. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin á kan máa máa parọ́, àtamọ́, àtamọ̀, ohun tí kò ṣẹlẹ̀. Ẹlòmíì gan-gan tí èèyàn ò bá sọ̀rọ̀ rí gan-an, á ní òun bá Black Lion sọ̀rọ̀ – gbogbo rádaràda wọ̀nyẹn, ẹnikan sọ báyi, ẹnikan sọ báyi. Hmm. Ẹ jẹ́ ká má tíì débẹ̀ yẹn – ẹ ngbé ojú wa kúrò ní ibi tí a nlọ ni.

Ìkìlọ̀ Ré O! L'ati Ọwọ́ Black Lion

“Mo wá fún oníkálùkù ní ìkìlọ̀ ni. Ẹ jọ̀ọ́, nítorí Ọlọ́run.

“Ẹ má ṣe dá ọ̀tá sílẹ̀, láarín àwọn ọmọ Yorùbá.”

Lákotán, BLACK LION wá kí gbogbo ọmọ Yorùbá – àwọn tí wọ́n nṣ’iṣẹ́ takuntakun, àti àwọn tí wọ́n ndá’wó sí’nú  òmìnira Account. A dúpẹ́ l’ọwọ gbogbo yín o! Kí ẹ dẹ̀ jọ̀wọ́, ọmọ Yorùbá, kí ẹ túbọ̀ máa bá wa f’owó sí’nú ÒMÌNIRA ACCOUNT. Ilé yín, ọ̀nà yín á dára; gbogbo ẹni tí ó nṣiṣẹ́ takuntakun, tí wọn nṣiṣẹ́ tọkàntọkan, tí ẹ ò kì nṣe àlábòsi. Gbogbo nkan tí ẹ bá dá’wọ́lé, ní dáradára, l’ó máa bọ́ sí rere; bẹ́ẹ̀ ni, ní’lẹ̀ Yorùbá, ẹ máa j’èrè.

BLACK LION wá sọ wípé kí ẹnikẹ́ni má ṣe fi owó sínú ti naíra account o! Ẹ má sì jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ó fún yín ní naira account kankan. Wọ́n ti dẹ́kun fífi owó sí naira account omìnira o! Ṣùgbọn òmìnira account ti ÒKÈ ÒKÚN, ẹ jọ̀wọ́, Black Lion rọ gbogbo àwọn èèyàn wa tí wọ́n wà lókè òkun, kí wọ́n jọ̀wọ́, kí wọ́n túbọ̀ máa fi owó si.