Njẹ́ ẹ mọ̀ wípé Pútìn Olórí Ìjọba Rọ́ṣíà ti ṣe òfin pé ẹnikẹ́ni tí ó bá ta èso GMO tàbí tí ó gbin èso GMO ti rú òfin agbésùnmọ̀mí.

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

Say no to gmo foods and seed in Yorubaland, Africa

Tí a bá wo GMO lórí agbagbe a ó ri pé Pútìn sọ wípé àwọn nṣọ́ ìlú Amẹ́ríkà nítorí àwọn ónjẹ tí nwọ́n fi nránṣẹ́ tí kò ṣe ànfàní fún ẹnití ó njẹẹ́, síbẹ̀ ó sì tún npa wọ́n lára. 

Ṣùgbọ́n, ó ṣe’ni l’aánú wípé Monsanto, tí ó jẹ́ ilé-iṣẹ́ aburú GMO, ní owó àti agbára tó bẹ́ẹ̀ t’ó jẹ́ wípé wọ́n máa nborí ní ẹjọ́ tí ẹnik’ẹni bá pè, wípé kí wọ́n máa kọ GMO s’orí àwọn onjẹ burúkú wọ̀nyí – wọn ò ní kọọ́. 

Nwọ́n ṣe èso GMO nípa pípa oríṣiríṣi èso papọ̀ láti sọọ́ di ọ̀kan, bí ìrú èso tí ó nhù ní ilẹ̀ òtútù àti ilẹ̀ òmíràn papọ̀, nkàn DNA oríṣiríṣi ni ó ma wà nínú èso náà, tí a bá jẹ èso yí, ẹ̀yà ara wa kò ní dá èso yí mọ̀, nítorínà kò ní mọ ohun tí ó jẹ́, yíó sì tún fa ìjàmbá sínú àgọ́ ara wa.

say no to gmo foods, seed, crop. yoruba warns african

Tí o bá jẹ́ wípé àwọn Adelé wa ti wọ inú secretariat láti lè ma ṣe iṣẹ́ nwọn dáradàra ju bí nwọ́n ti ṣe nísìyí lọ, nwọn á ti mójútó kí èso búburú yìí kí ó mà wọ Orílẹ̀ Èdè wa. Tí àwọn agbésùnmọ̀mí bá ti kúrò lórí àga wa, ìdíwọ́ kò ní sí mọ́.