Àwọn Àjọ tó ńrísí ìmọ́tótó Àyíká lábẹ́ ìjọba Naijiria tó fi agídí je gàba lórí ilẹ̀ àwa IYP ní ìpínlẹ̀ Èkó tí wọ́n ńpè ní KAI, lè àwọn olùtajà òpópónonà ni ara odi ọgbà Tafawa Balewa l’Eko, tí wọ́n ńdá sunkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀ ní òpópó-ònà tí wọn sì ńfa ewu àyíká sí agbègbè náà.

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

 A fẹ kí ó yé wa pé ìjọba ajẹgàba ti Èkó tí ó rán wọn níṣẹ́ àti àwọn àjọ tí ńṣisẹ́ yìí jẹ́ arúfin lábẹ́ òfin àgbáyé nítorípé láti ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbẹ̀wáọdúnólémẹ́rìnlélógún ní ìjọba Democratic Republic of the Yorùbá tí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ kò sì yẹ kí Naijiria ṣì má ṣe ìjọba lórí orílẹ-èdè wa mọ́.

 

Democratic republic of the Yoruba ominira new update | Yoruba Nation | Newest Nation in Africa, World

 

Tí wọ́n bá fẹ́ ṣe imototo àyíká wọn ó yẹ kí wọn lọ sí ìlú Naijiria tí o yàn wọ́n ní gómìnà àti àjọ amúṣẹse, ìwà ìgbé sùmòmí ni won ńhù lórí ilẹ wa yìí.

Ìròhìn fi yé wa pé Tòkunbọ̀ Wahab tí o jẹ́ kọmiṣọ́ná wọn fún àyíká àti ohun ìmúṣọrọ̀ omi ló fi ìròhìn náà lède lórí X tàbí twítà rẹ̀, ó ní iṣẹ́ yi wa ní ìbámu pẹlú akitiyan ìjọba wọn l’Eko làti ṣètò àyíká tí ó mọ́ tí o sì wá létòlétò, gégébí ètò ìmúlò àinifarada tí àwọn gùn lé.

Wahab sọ pé “L’owurọ kùtù òní àwọn àjọ ìmọ́tóto àyíká KAI lè àwọn tí ń taja l’ópòópónà lára odi ti ó yí ọgbà Tafawa Balewa ka, tí wọn ńdá súnkẹ́rẹ fàkẹrẹ ọkọ̀ sílẹ̀, tí wọn sì ńfa ewu àyíká.”

Ká Ìròyìn Síwájú sí:

Ohun tó dájú ni pé nínú orílẹ̀-èdè D.R.Y kò ní sí ìdí fún ẹnikẹ́ni láti tajà òpópónà rárá nítorí ile ìtàjà olówó pọ́ọ́kú yóò wá fún ènìyàn gbogbo láti gbà láìsí ìnira tàbí ojúsàájú kankan. 

Ní kété ti àwọn ìjọba wa bá ti wọ ilé iṣẹ ìjọba wa, ayé tí dáa dé fún gbogbo wa nìyẹn.