Ìjọba Nàìjíríà, tí ó jẹ́ ìjọba agbésùnmọ̀mí tí wọ́n ndúkòkòlajà mọ́ ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, lórí ilẹ̀ Babanlá wa, kòì tíì kúrò l’orí kí wọn máa purọ́ wípé Yorùbá ṣì wà l’ara Nàìjíríà.

Èyí tí wọ́n tún gbé dé ní àìpẹ́ yí ni wípé, wọ́n nka Èkó mọ́ àwọn ibi tí irin-iṣẹ́ tí ó nṣàkóso ètò ìrìnnà ọkọ̀ òfúrufú ní Nàìjíríà wà.

Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá

 

Ní ọjọ́ àbámẹ́ta, èyíinì, ọjọ́ Sátidé, ọjọ́ kárun-dín-l’ogún, oṣù òkúdù, ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rin-lé-l’ogún (èyíinì, oṣù kẹ́fà ọdún 2024), tí ó ti lé ní oṣù méjì tí a ti ṣe Ìpolongo Ìṣè’jọba-ara-Ẹni ti Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, tí a sì ti ṣe Ìbúra-Wọ’lé fún Olórí Ìjọba Adelé wa, ni ìròhìn náà já’de l’orí ẹ̀rọ ayélujára wípé, Ahmed Umar Farouk, tí ó jẹ́ Olùdarí ilé-iṣẹ́ tí ó mbojútó ètò ìrìnnà ọkọ̀ òfúrufú (èyíinì, NAMA) ní ìlú Nàìjíríà, sọ nípa àwọn irin-iṣẹ́ ìbojútó ètò ìrìnnà ọkọ̀ òfúrufú ní Nàìjíríà, ó sì dá’rúkọ ibi mẹ́rin tí ó sọ wípé àwọn irin-iṣẹ́ yí wà – ó dá’rúkọ Kano, Èkó, Abuja àti Port Harcourt!

Ka Ìròyìn: Orúkọ Nílẹ̀ Yorùbá

Èyí tú’mọ̀ sí wípé, l’ẹhìn ìgbà tí Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá ti di orílẹ̀-èdè aṣè’jọba-ara-ẹni, Nàìjíríà ṣì pàpà nka ilẹ̀ Yorùbá mọ́ ara Nàìjíríà!

Eléyi jẹ́ ọ̀ràn-dídá tí ó l’agbára púpọ̀, àti ẹ̀sùn sí ọrùn Nàìjíría.

Ìjọba Agbésùnmọ̀mí Nka Yorùbá Mọ́ Naìjíría! Hábà!

Ṣé a ti mọ̀ wípé oríṣiríṣi ọ̀nà ni agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà ti nṣẹ̀ sí òfin àgbáyé, nípa fí fi ipá àti ìwà ìpánle jóko sí orí ilẹ̀ Yorùbá. Èyí tí Farouk tún wá sọ yí fi hàn gbangba wípé Nàìjíríà nfi ojoojúmọ́ kó pánpẹ́ sí’ra wọn l’ọwọ́. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́bí Olórí Ìjọba Adelé ti sọ ní ọjọ́ àíkú t’ó kọjá yí, ìgbà díẹ̀ báyi l’ó kù tí a kò ní fi rí Nàìjíríà mọ́ l’orí ilẹ̀ Yorùbá.

Ká Ìròyìn: Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P), Ẹ̀ Jẹ́ Kí á Bá’ra Wa Sọrọ