Ìpínlẹ̀ Èkìtì jẹ́ ìkan nínú àwọn ìpínlẹ̀ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, l’abẹ́ ìṣ’àkóso Ìjọba Adelé Orílẹ̀-Èdè Yorùbá, pẹ̀lú Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́ tí ó jẹ́ olórí ìjọba adelé orílẹ̀-èdè Yorùbá.

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

Ṣùgbọ́n àwọn ìjọba agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà (ìjọba tẹ́rọ́síìs) tí wọ́n fi ipá dúró l’orí ilẹ̀ wa, ilẹ̀ Yorùbá, tí agbésùnmọ̀mí apàà’yàn Oyèbánjí tí nàìjíríà npè ní gómìnà wọn ní Èkìtì náà npe ara rẹ̀ ní gómìnà ní’bẹ̀; tí ó nbá wọn ṣe iṣẹ́ ìkà àti ìjẹgàba wọn ní’bẹ̀, ni a gbọ́ wípé ó ti ṣe òfin oní’lé-gbé’lé l’ati aago méje alẹ́ di aago méje àárọ̀; ní ìpínlẹ̀ Èkìtì, l’atàrí wípé àwọn ìṣẹ̀’lẹ̀ ìpànìyàn tí ó ti nw’ayé ní Ekìtì ní ọjọ́ mélo kan báyi.

Ìjọba Agbésùnmọ̀mí Ṣe Òfin Oní'lé-Gbé'lé Ní Èkìti!

Ẹ jọ̀wọ́, ẹ bá wa béèrè l’ọwọ́ agbésùnmọ̀mí, apànìyàn Oyèbánjí, àti Tinubú ọ̀gá rẹ̀ t’ó nṣi’ṣẹ́ fún, wípé, ta ló bẹ̀ wọn ní’ṣẹ́ ṣíṣ’òfin oní’lé-gbé’lé ní ìpínlẹ̀ Èkìtì, ní orílẹ̀-èdè Yorùbá o!

Kí wọ́n kúrò l’orí ilẹ̀ wa, ilẹ̀ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, l’a sọ! Ìjọba Yorùbá ti bẹ̀rẹ̀; kí wọ́n yéé dókùkùlajà mọ́ wa l’orí ilẹ̀ wa! Olè, apànìyàn, ẹ kúrò l’orí ilẹ̀ Yorùbá!

Ẹ kúrò ní Èkìtì, kí ẹ sì kúrò l’ati jẹ gàba l’orí gbogbo ìpínlẹ̀ tí ó wà ní Orílẹ̀-Èdè Yorùbá! Ẹyin gan-an gan l’apànìyàn! Ìjọba nàìjíríà l’ó sún wa dé’bi t’a dé yí, tí ìwà ìpànìyàn ṣe nṣẹ’lẹ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá.

Tinubú, àti Oyèbánjí, Ẹ JÁ’DE KÚRÒ NÍ JÍJẸGÀBA L’ORÍ ILẸ̀ YORÙBÀ, Ẹ JÁ’DE KÚRÒ NÍ JÍJẸGÀBA L’ORÍ ÌPÍNLẸ̀ ÈKÌTÌ! Ẹ̀YIN GAN-AN NI APÀNÌYÀN TÍ Ó GBA APÀNÌYÀN L’AÀYÈ NÍ ÌPÍNLẸ̀ ÈKÌTÌ! Ẹ máa lọ!

Ìjọba Orílẹ̀-Èdè Yorùbá mọ bí ó ṣe máa d’ẹkun ìwà apànìyàn ní ilẹ̀ Yorùbá! Ṣe bí ẹ̀yin nàìjíríà ni apànìyàn tí ó kó ìwà agbésùnmọ̀mí, ìwà apànìyàn, àti ìwà olè, tí ó sọọ́ di kárí-ilé, tí Èkìtì àti gbogbo ilẹ̀ Yorùbá fi rí b’ó ṣe rí l’oní yí!?

A ò bẹ̀ yín ní’ṣẹ́ kí ẹ máa ṣe òfin fún ilẹ̀ Yorùbá o!

iroyin ominira ojoojumo - democratic republic of the yoruba