Fọ́nrọ́n kan tí a rí ṣe àfihàn ọkọ̀-àjàgbé kan tí wọ́n kọ “Dangote” sí lára, tó ṣubú forí-dólẹ̀ ní ìlú Ìwòròkó-ÈkìtiOrílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, níbi tí aṣiwèrè Oyèbánjí, gómìnà Nàìjíríà ti njẹgàba sórí ilẹ̀ ọmọ Yorùbá, tí ó sì jẹ́ pé a ò sí lára Nàìjíríà mọ́ láti ogúnjọ́ oṣù bélú, ẹgbàá ọdún ó lé méjìlélógún, tí a sì ti bẹ̀rẹ̀ ìṣèjọba-ara-ẹni tiwa láti ọjọ́ kéjìlá oṣù igbe ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rinlélógún.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò mọ ohun tí ó fa ìjàmbá ọkọ̀ yí, gbogbo wa la mọ oríṣiríṣi nkan tó ṣeéṣe kó fàá, látàrí ìjọba àìbìkítà, ìjọba amúnisìn Nàìjíríà, tí wọ́n jẹ gàba lórí ilẹ̀ wa, ṣùgbọ́n, lágbára Èdùmarè, Ẹlẹ́da ọmọ Yorùbá, nínú gbogbo àánú rẹ̀, á bá wa ṣí’wọn nídi kúrò lórí ilẹ̀ wa láìpẹ́.

Ká Ìròyìn Síwájú sí:

Tó bá jẹ́ pé ìjọba wa ti wọlé sí gbogbo oríkò-ilé-iṣẹ́ ìjọba wa ni, tí kò sí ìwà agbésùnmọ̀mí ti Nàìjíríà, ó níbi tí iṣẹ́ á ti dé ní àkókò yí lórí ọ̀nà pópó wa gbogbo, fún ààbò, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ni ààbò wa, bẹ́ẹ̀ ni, ṣùgbọ́n èyí tí ó gbé lé wa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ náà, kí Nàìjíríà ó kúrò lórí ilẹ̀ wa kí á lè ṣeé.

Wọ́n ṣì ngbìyànjú láti fa ẹni kan yọ nínú ọkọ̀ náà nígbàtí wọ́n ṣe fídíò ọ̀ún.