Àkọsílẹ̀ ọ̀rọ̀ bí ó ṣe ń lọ ti òní dá lé orí Babangida tí ó bá àwọn Fúlàní márun ṣe ìpàdé pọ̀, nínú wọn ni: Abdulsallam àti Emir tí Maiduguri.

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

Ó fún wọn ní àbọ̀ lórí ìwádìí tí ó ṣe ní ìta lórí ọ̀rọ̀ MOA àti Yorùbá tí ó ti di Olómìnira pé, wọ́n sọ fún òun pé Yorùbá ti lọ tí kò sì sí ohun tí ẹnikẹ́ni le se síi mọ́, wọ́n sọ fún òun pé àwọn Amerika ni ó wà lẹ́yìn MOA.

Ó sọ fún wọn pé wọn kò gba ìmọ̀ràn tí òun fún wọn nígbà tí wọ́n fẹ́ ṣe ètò ìdìbò tí ó kọjá lọ pé kí wọ́n mú Oṣibajo dí’pò Tinubu, ṣùgbọ́n tí wọn kò gbà sí òun lẹ́nu. Ó gbà wọn ní ìmọ̀ràn pé kí wọ́n lọ dá agbára padà fún àwọn alága ìjọba ìbí’lẹ̀.

Ijabo Re Ti Oní Ọjọ́ Kẹ́jọ Oṣù Kéje Ẹgbàá Ọdún Ó-Lé-Mẹ́rìn-Lé-Lógún.

Ó tún gbà wọ́n ní ìmọ̀ràn sí’wájú síi pé, kí wọ́n lọ wá ọmọ Èkó tí ó jẹ́ ológun, ṣùgbọ́n kò sọ ohun tí ó fẹ́ kí wọ́n fi ṣe.

Babangida tún sọ wípé, òun gba ìmọ̀ràn láti ìta pé kí wọ́n lọ gbé owó jáde púpọ̀, kí wọ́n fi ra àwọn adélé àti àwọn ará ìlú ní orílè-èdè Yorùbá, kí ọ̀tá MOA má baà ní èrò lẹ́yìn mọ́, kí ìjọba tiwọn (láì kì í ṣe ti ilẹ̀ Yorùbá ní agbára Ọlọ́run) má baà ṣe é se.

Ó tún fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé wọ́n sọ fún òun láti ìta pé, ó dájú pé ilẹ̀ Yorùbá ti lọ, ṣùgbọ́n kí wọn má jẹ́kí wọ́n fi ìrọ̀rùn ṣe ìjọba náà.

Democratic republic of the Yoruba ominira new update | Yoruba Nation | Newest Nation in Africa, World

Ó tún ṣe ìlérí pé ó tún ku ohun kan tí òun má tún ṣe ní ìta.

Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé Tinubu kò lè lọ fún ìṣe’jọba ẹ̀kejì, àwọn Fúlàní sì ti pinnu ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe fun tí ó bá parí ìjọba èyí tí ó ń ṣe lọ́wọ́ yìí. Ká Ìròyìn Síwájú sí: