Òṣèlú-ṣíṣe ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) jẹ́ èyí tí kò fi àyè gba fàmí-létè-ntutọ́, nítorí gẹ́gẹ́bí màmá wa, Ìyá-ààfin Modúpẹ́ọlá Onítirí-Abíọ́lá, ti ṣe àlàyé fún wa, òṣìṣẹ́-ìjọba náà ni àwọn tí a bá yàn sí ipò ní D.R.Y jẹ́, wọn kò sì ní àṣẹ láti ṣe ohun tí ó yàtọ̀ sí òfin Orílẹ̀-Èdè Yorùbá.

Gẹ́gẹ́bí àpẹẹrẹ, Olórí-Ìjọba Orílẹ̀-Ède Yorùbá kò lè lo ọkọ̀ ìjọba lẹ́yìn tí ó bá ti ṣíwọ́-iṣẹ́ ní ojoojúmọ́, àfi tí ó báá ní àfikún-iṣẹ́ ní ọjọ́ náà.

Bẹ́ẹ̀ náà ni kò sí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ọkọ̀ tí yóò máa tẹ̀le níbikíbi tí ó bá ń lọ. Kìkìdá ọkọ̀ tí òun wà nínú rẹ̀, ọkọ̀ ẹ̀ṣọ́ ààbo, gbogbo ọkọ̀ náà kò ju mẹ́ta lọ ní ìbẹ̀rẹ̀, lẹ́yìn àkókò díẹ̀, méjì péré ni yóò jẹ́.

Ọ̀sẹ̀ méjì-méjì ni àwọn olóṣèlú wa yóò máa gba owó ọ̀yà wọn gẹ́gẹ́ bí ó ti wà fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba tó kù,wọn kò sì ní àǹfààní láti wà ní ìdí gbígbé iṣẹ́ fún agbaṣẹ́ṣe.

Gbogbo ẹni tí a bá yàn sípò ni yóò bu ọ̀wọ́ lu ìwé-àdéhùn pẹ̀lú ọmọ-ìbílẹ̀ Yorùbá, wọn kò sì gbọ́dọ̀ yẹ àdéhùn náà.

Abundant of mineral resources in the democratic republic of the yoruba.
Ìròyìn Òmìnira Olojoojumọ – Bèrè fún ẹ̀da títí rẹ!