Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn kan tí wọ́n pe’ra wọn ní ọmọ Yorùbá ṣùgbọ́n tí a w’òye wípé wọn ò kìí ṣe ọmọ Yorùbá, ni ó jẹ́ wípé ìfọ́jú nlánlà ni ó mbá wọn jà; ìdí ni èyí tí ó fi jẹ́ wípé ìrònú wọn, ìrònú “one Nigeria” ni.

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

Yoruba nation map

Irúfẹ́ wọn ni àwọn kan tí wọ́n pe’ra wọn ní “South West Caucus of the House of Reps” ní ìlú Nigeria.

Ṣé etí wọn di ni? Ṣé ọmọ Yorùbá tún ya Adití ni, àbí báwo l’ó tún ṣe jẹ́ tí àwọn kan tún ṣì npe ara wọn ní “South West” ní ìlú Nigeria, nígbàtí ó jẹ́ wípé orílẹ̀-èdè Yorùbá (tí wọ́n npè ní ‘South West’ nínú Nigeria tẹ́’lẹ̀) ti dádúró gẹ́gẹ́bí orílẹ̀-èdè.

Nkan tí àwọn wọ̀nyí kò mọ̀ ni wípé wọ́n ndá ọ̀ràn mọ́ ọ̀ràn ní ọjọ́ tí wọ́n máa f’ojú w’iná ọ̀ràn tí wọ́n ndá  yi.

Kí ọmọ Yorùbá kankan má ṣe  l”ọwọ́ pẹ̀lú wọn nínú irúfẹ́ ohun tí ó l’òdì sí  Ìjọba Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorúbá, èyí tí wọ́n nṣe wọ̀nyí.

Olori Adele of the democratic republic of the Yoruba government address to indigenous yoruba people

Ìgbéraga àti àìmọ̀kan l’ó fa kí ẹnik’ẹni, ní’kórita tí a dé yi, kí wọ́n ṣì máa s’ọ̀rọ̀ “South West” ní ìlú Nigeria, àfi tí ó bá jẹ́ wípé wọ́n ti wá mọ̀ dáadáa wípé Yorùbá kò sí nínú Nigeria mọ́, tí wọ́n ti wá ní ibòmíràn gẹ́gẹ́bí South West nísiìyí nínú Nigeria.

Ka Ìròyìn: Ẹ̀kún Rẹ́rẹ́ Ọ̀rọ̀ Olórí Adelé Ní Àyájọ́ June 12

Ṣùgbọ́n a ṣ’àkíyèsí wípé àwọn tí wọ́n pe’ra wọn ní “South West Caucus” yí, orúkọ Yorùbá ni a rí l’aárin wọn – àwọn bíi  Dr. James Abiodun Faleke, tí ó pe’ra rẹ̀ ní Alága Caucus yí; àti Taofeek Ajilesoro tí wọ́n pè ní Akọ̀wé wọn; bẹ́ẹ̀ náà ni Dr. Adewummi Oriyomi Onanuga.

Wo eto ti o da’lori June 12 nipa baba wa MKO Abiola

 

Ẹ jẹ́ kí gbogbo ayé kí ó gbọ́: YORÙBÁ TI KÚRÒ NÍNÚ NIGERIA. Kò tún sí wípé kí ẹnik’ẹni kí ó máa pe ilẹ̀ Yorùbá ní South West Nigeria. Èyí ti di Ọ̀ràn dídá ní Orílẹ̀-Èdè Yorùbá l’ati ọjọ́ kéjìlá oṣù  kẹ́rin ọdún tí a wà nínú rẹ̀ yí (2024).