Ìròyìn tí ó tẹ̀ wá l’ọwọ́ ní àìpẹ́ yi sọ wípé ní’bi Odò Ẹran kan ní ìlú Èkó ni o ti nṣẹ’lẹ̀ wípé àwọn ọmọ Íbò ni wọ́n ngba owó ibodè Odò Ẹran náà, ní orí ilẹ̀ Yorùbá! HÁBÀ!

À b’ẹ́ ò rí ìwọ̀sí nlá nlà tí ó nṣẹ’lẹ̀ sí ọmọ Yorùbá, l’orí ilẹ̀ Baba wọn!

Kìí tún wá nṣe èyí nìkan; ṣùgbọ́n, ní’gbà tí wọ́n bá tún kọjá ibòdè wọ’lé lọ sí’nú odò ẹran lọ, nṣe ni àwọn Fúlàní náà á tún bẹ̀rẹ̀ tiwọn, nítorí wípé, àwọn ni ó máa gba owó ìjá’kùn ẹran!

Yoruba nation map

Bẹ́ẹ̀ ni a sì gbọ́ wípé, pẹ̀lú ọ̀rọ̀ rírùn yi, nṣe ni ó jẹ́ wípé, ọmọ Yorùbá wà l’ẹnu ibodè tí ó sì ntọrọ jẹ ní’bẹ̀!

Gbogbo ohun ìríra wọ̀nyí nṣẹ’lẹ̀ tìtórí wípé agésùnmọ̀mí Nigeria ṣì wà l’orí ilẹ̀ Yorùbá; ìbá má ṣe bẹ́ẹ̀ ni, tani baba t’ó bí Íbò papọ̀ mọ́ Fúlàní tí ó fi di wípé àwọn ni wọ́n á wá máa f’ọwọ́ la’lẹ̀ fún ọmọ Yorùbá l’orí ilẹ̀ Yorùbá?!

Èyí ni àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá fi sọ wípé, nígbàtí a bá lé agbésùnmọ̀mí Nigeria kúrò l’orí ilẹ̀ wa tán, ojú wa máa le o!

Ka Ìròyìn: Ọmọ Yorùbá, Ẹ Ṣọ́’ra! àwọn ọmọ Igbo ti ntú ní ọ̀pọ̀ yanturu wọ ìlú Èkó

Kí ẹnik’ẹni ó má ṣe dá wa l’ẹbi nígbàtí ọmọ Yorùbá bá bẹ̀rẹ̀ sí gbé ẹrù tí àwọn ọ̀tá  Yorùbá ndì yí, tí a bẹ̀rẹ̀ sí gbé ẹrù wọn lé wọn l’orí!

Ojú á le o! Ilẹ̀ Yorùbá kìí ṣe ilẹ̀ Íbò o! bẹ́ẹ̀ ni kìí ṣe ilẹ̀ Fúlàní.