Ṣé láìpẹ́ yí ni a mú ìròhìn tó wa létí, pé, ilé-iṣẹ́ China kan, Zhongshan, gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ọkọ̀ bàlúù tí Nàìjíríà nlò fún ààrẹ wọn, látàrí pé Ìjọba ìpínlẹ̀ Ògùn, nígbàtí a ṣì wà nínú Nàìjíríà, fagilé àdéhùn tí wọ́n jọ ní lórí pé kí Zhongshan ó ṣe àkóso Gbàgede náà (Free Trade Zone).

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ògùn nígbà fífagilé Àdéhùn náà, Ìbíkúnlé Amósùn, sọ pé ẹ̀bi òun ni o, ó ní ṣe ni wọ́n tan òun jẹ, tí òun fi gbé iṣẹ́ náà fún Zhongshan lábẹ́ àkóso ìkan nínú àwọn ìlé-iṣẹ́ àbẹ́ rẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Zhongfu. Ọ̀tọ̀ ni ilé-iṣẹ́ China tí Gbenga Daniel gbé iṣẹ́ náà fún ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ní ẹgbàá ọdún ó lé méje, kí Amósùn ó tó wá gbe fún Zhongshan lábẹ́ òṣìṣẹ́ Zhongfu.

Ó ní ṣàdédé wá ni àwọn Zhongfu-Zhongshan yí wá bá òun, ní bí ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rin-dín-lógún, tí wọ́n sọ pé ilé-iṣẹ́ China ti Gbenga Daniel kọ́kọ́ gbé iṣẹ́ yẹn fún kò mà ṣeé dáadáa-à, ni òun bá sọ fún Zhongfu yí pé, ó dáa, ẹ̀yin ẹ máa bá wa ṣe, títí tí a máa fi ṣe ìwádi ẹ̀sùn tí ẹ mú wá yí!

Democratic republic of the Yoruba ominira new update | Yoruba Nation | Newest Nation in Africa, Youngest country in the World 2024
Ìròyìn Òmìnira Olojoojumọ – Bèrè fún ẹ̀da títí rẹ!

Hùn! Èèyàn wá bá ẹ, pé orogún òun kò màá ṣe, ó wá sọ pé ẹni tí ó wá fẹjọ́ sùn kí ó máa ṣé, títí tí wàá fi ṣe ìwádí bóyá irọ́ ló npa, tàbí kìí ṣe irọ́! To-ò, a ti gbọ́.

Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, Amosùn sọ pé òun wá ri pé irọ́ gbáà ni Zhongfu npa, ló bá fagilé àdéhùn tí ó ní pẹ̀lú Zhongfu, ni Zhongfu bá lọ fẹjọ́ sún àwọn kònkárí ilé-iṣẹ́ wọn, Zhongshan, ni Zhongshan bá gbọ̀nà ilé-ẹjọ́ káàkiri Àgbáyé; ìwọ̀nyí ló fa kí Zhongshan máa gbẹ́sẹ̀ lé ohun tí ó bá ti jẹ́ ti Nàìjíríà níbikíbi tí wọ́n bá ti lè ri, torí Nàìjíríà sháà ni àwọn le dì mú nígbà náà lọ́hún tí a ṣì wà lára wọn: ṣùgbọ́n, láti ogúnjọ́ oṣù bélú, ẹgbàá-ọdún ó lé méjìlélógún ni àwa ti wá jáde kúrò nínú Nàìjíríà, tí a dẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ ìṣèjọba-ara-ẹni tiwa láti ọjọ́ kéjìlá oṣù igbe, ọdún tí a wà nínú rẹ̀ yí – ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rinlélógún.

Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P), a mú èyí wá fún wa gẹ́gẹ́bí ìròhìn tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni o, kìí ṣe kí á wá máa ro kíleléyí? Ìjọba wa, Ìjọba Orílẹ̀-Èdè Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), gẹ́gẹ́bí ìjọba, mọ gbogbo ohun tí D.R.Y máa ṣe nígbàtí a bá ti wọlé sí oríkò-ilé-iṣẹ́ ìjọba wa gbogbo; Màmá wa, Òjíṣẹ́ Olódùmarè, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, dẹ̀ ti sọ fún wa, tẹ́lẹ̀ tẹ́lẹ̀, pé gbogbo ohun tí ó jẹ mọ́ orílẹ̀-èdè míràn káàkiri àgbáyé, ni D.R.Y máa wò fínní-fínní, láti mọ ohun tó ṣe kíni tí kíni fi ṣe kíni – ẹ̀ hẹn-ẹ̀n, ó ti yé wa!