Gbogbo ọmọ Ilé-Ìwé Girama, ní ilẹ̀ Yorùbá, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), ẹ kúkú ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé kò sí nkan tó kàn wá pẹ̀lú Nàìjíríà, àti pé a ti kúrò nìnú Nàìjíríà láti ogúnjọ́ oṣù bélú, ẹgbàá ọdún ó lé méjìlélógún, tí a dẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ ìjọba ti orílẹ̀-èdè wa láti ọjọ́ kéjìlá oṣù igbe, ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rin-lé-lógún tí a wà nínú rẹ̀ yí.

Bẹ́ẹ̀ náà ni olórí-ìjọba-adelé wa ti sọ pé, kí gbogbo ilé-ìwé kí ó ṣì wà ní títìpa báyi ní gbogbo ilẹ̀ Yorùbá.

Ṣùgbọ́n, Nàìjíríà ṣì njẹgàba lórí ilẹ̀ wa, a ò dẹ̀ gbọ́dọ̀ ṣe ohun tí Nìjíríà nṣe.

Nísíiyí, a gbọ́ pé wọ́n fẹ́ ṣe ìdíje ọ̀rọ̀ sísọ ọlọ́dọọdún ní ìlú Nàìjíríà, àti pé àkorí ọ̀rọ̀-ìdíje náà, tí ó wà fún àwọn ọmọ ilé-ìwé girama, ni “Ó yẹ kí òfin Nàìjíríà fi àyè gba Ìbálòpọ̀ Ọkùnrin-s’ọkùnrin àti Obìnrin-s’obìnrin.”

Ẹ jọ̀wọ́, gbogbo àwọn ọmọ wa tí wọ́n jẹ́ ọmọ-ilé-ìwé, ẹ MÁṢE BÁ WỌN KÓPA nínú ìdíje-ọ̀rọ̀ yí. Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y) kò sí lára Nàìjíríà mọ́! Bẹ́ẹ̀ náà ni a lòdì sí ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ ọkùnrin-sọ́kùnrin àti obìnrin-sóbìnrin. Ẹ máṣe bá wọn súnmọ́ ibi tí wọ́n ti nsọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. Aà kì nṣe ara Nàìjíríà.

Àwa òbí, ẹ jẹ́ kí á bá àwọn ọmọ wa sọ̀rọ̀ kí wọ́n máṣe súnmọ́ ohunkóhun tí ó jẹ́ ti ìjọba Nàìjíríà, kí wọ́n má dẹ̀ kópa tàbí lọ́wọ́ sí ìbálòpọ̀ ọkùnrin-sọ́kùnrin tàbí obìnri-sóbìnrin. 

Democratic republic of the Yoruba ominira new update | Yoruba Nation | Newest Nation in Africa, Youngest country in the World 2024
Ìròyìn Òmìnira Olojoojumọ – Bèrè fún ẹ̀da títí rẹ!