Ó ṣeni láanú pé ọmọ Yorùbá ti wá di ẹni tí a nkà mọ́ olè àti ajínigbé, látarí ìlú burúkú, Nàìjíríà, tí wọ́n ba ilẹ̀ wa jẹ́ láti ìgbà tí òyínbó amúnisìn ti so wá papọ̀ mọ́ oríṣiriṣi ìran míràn, ṣùgbọ́n tí a ti wá jáde láti ogúnjọ́ oṣù bélú, ẹgbàá ọdún ó lé méjìlélógún, tí a dẹ̀ ti wá bẹ̀rẹ̀ ìjọba tiwa báyi, ìjọba Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y), láti ọjọ́ kéjìlá, oṣù igbe, ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rinlélógún, ṣùgbọ́n tí agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà yí ṣì pàpà njẹgàba sorí ilẹ̀ wa!
Lágbára Èdùmàrè, a máa rẹ́yìn wọn láìpẹ́ yí; àmọ́ jíjẹgàba tí wọ́n ti nṣe lórí ilẹ̀ D.R.Y títí di àsìkò tí a nsọ̀rọ̀ yí, ló fa kí àwọn nkan aburú ṣì máa ṣẹlẹ̀ sí ọmọ Yorùbá, lórí Ilẹ̀ Yorùbá. Eléyi panilẹ́kún.
❗PÀJÁWÌRÌ FÚN ÀÀBÒ❗KÁÀKIRI GBOGBO ÌPÍNLẸ̀ YORÙBÁ TÍTÍ DÉ OLD Ọ̀YỌ́ EMPIRE, Ẹ MÁA YA FỌ́TÒ FÚLÀNÍ, OLỌ́PA, OLÓṢÈLÚ, SÓJÀ, TÍ Ẹ BÁ FURA SÍ ÌRÌN ÀTI ÌṢESÍ WỌN NÍ AGBÈGBÈ YÍN. KÍ Ẹ FI ṢỌWỌ́ SÍ BÀBÁ ÌJÌNLẸ̀ +905367341665 (WHATSAPP).… Pín Sórí Àgbàgbé X (Twitter)Ìròhìn tí ó tẹ̀wá lọ́wọ́ fi hàn pé àwọn ọ̀dọ́ mẹ́ta kan ni wọ́n mú ní agbègbè Èbúté Igbogbo ní Ikòròdú, láìpẹ́ yí, tí wọ́n sì fìyà jẹ wọ́n, tí wọ́n bọ́ṣọ lọ́rùn wọn, nígbàtí wọ́n gbìyànjú láti jí ọkùnrin kan gbé, ẹni tí ó máa nta ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́.
Báwo ni ọmọ Yorùbá ṣe di ẹni ẹ̀sín báyi-ì? Ó mà ṣe o; ṣùgbọ́n ìwọ Sanwó-Olú tí o ṣì nfagídí dúró sórí ilẹ̀ D.R.Y, ní Ìpínlẹ̀ Èkó àti àwọn yókù rẹ káàkiri orílẹ̀-èdè D.R.Y, ṣé ẹ mọ̀ pé ọ̀ràn nlá ni ẹ ndá, pàápàá pẹ̀lú irú ìwà pálapàla tí àwọn ènìyàn ṣì nhù ní orí-ilẹ̀ Yorùbá, tí ó sì jẹ́ pé tìtórí oríbúrúkú ẹ̀yin gómìnà nàìjíríà wọ̀nyí sì ni, tí ẹ dúró láìní ẹ̀tọ́ sí ilé-iṣẹ́ Ìjọba D.R.Y
Láìpẹ́, láìjìnà, ẹ̀sín yín máa bọ́ sí àgbáyé.