Àṣé ikú ún bọ́mọ rìn ọmọ ò funra ni ọ̀rọ̀ àwa pẹ̀lú àwọn òyìnbó amúnisìn yí jẹ́ tí akò mọ̀.

Àwọn amúnisìn wọ̀nyí fẹ́rẹ̀ dàbí ẹnipé kòsí ẹ̀mí Ọlọ́run nínú wọn rara, tí o fi jẹ́ pé ọ̀nà àti pa aláwọ̀dúdú run ni èròngbà wọn láti ọjọ́ pípẹ́ tí a ò sì mọ̀.

Ìdí atótónu yí ni bí ọ̀kan lára àwon óyìnbó aláwọ̀ funfun tí orúkọ rẹ́ njẹ́ Robert F. Kennedy ṣe tú àṣírí ọ̀rọ̀ kan. Ó jẹ́wọ́ wípé ìwádi fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó lé ní ẹgbẹ̀rún igba àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ aláwọ̀dúdú tí wón ti kàgbákò ikú àìtọ́jọ́ láti ara abẹ́rẹ́ TTP yí, ó bani lọ́kàn jẹ́ gidigidi.

Bẹ́ẹ̀ sì ni, ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà tí a ti kúrò, ngbé abẹ́rẹ́ yí lárúgẹ fún àwọn ọmọ ìlú wọ́n láti gbà.

Títí di òní ilé iṣẹ́ kankan kò tí yẹ wò bóyá ó dára tàbí kò dára, kí wọ́n ṣáà tí gba owó ni tiwọn, wọn ìbáà fi májèlé pa gbogbo ọmọ ìlú wọn kò kàn wọ́n, owó ṣáá ni ìṣòro ayé wón.

Democratic Republic of the Yorùbá latest news updates 04/09/2024

Ìdí nìyí tí àwa ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, I.Y.P se ún dúpẹ́ lọ́wọ́ Ìyá wa, ẹni orí ṣàdaá Olóyè ìyáàfin Modúpẹ́ọlá Onítirí-Abíọ́lá tí wọ́n dìde lákokò yí láti gbà àwa ọmọ aládé kúrò lọ́wọ́ ìparun ayérayé.

A dúpé lọ́wọ́ Olódùmarè tí o ti ọ̀rọ̀ yí jáde lẹ́nu ọ̀kan lára àwọn òyìnbó amúnisìn wọ̀nyí, gbogbo ìran adúláwọ̀ ni ìbá tẹ̀síwájú láti máa gba abẹ́rẹ́ aṣekúpani ọ̀hún. Ní tí àwa ọmọ aládé, a ti bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́.

Gbogbo ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá, ẹ jẹ́ kí á kíyèsára gigigidi. Ọ̀gbẹ́ni Robert F. Kennedy tún dárúkọ Bill Gates nínú fọ́nrán náà! Ẹni tí kò bá yàgò fún Bill Gates, ẹ jẹ́ kí àwa ó yàgò fún ẹni yẹn o!

Gbogbo ibi tí wọ́n bá ti nsọ̀rọ̀ ìṣekúpani nípa abẹ́rẹ́-àjẹsára, àbí dídín iye ènìyàn tí ó wà ní àgbáyé kù, pàápàá ní ilẹ̀ Áfríkà, orúkọ Bill Gates kan yíì náà ni wọ́n máa ndá níbẹ̀! Ẹni tí ó bá sọ pé ọ̀rọ̀ yí kò tíì yé òun, ní’jọ́ wo ló fẹ́ ye o?

Bill Gates ni Ìránṣẹ́-Ikú tí àwọn amúnisìn aláwọ̀funfun rán láti fi abẹ́rẹ́-àjẹsára pa aláwọ̀dúdú run.