Arákùnrin Fulani darandaran kan tí sọ̀rọ̀ jáde láti tú àṣírí àwọn tí ó npe ara wọn lọ́ba ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, bíótilẹ̀jẹ́pé kò sí ọba kankan ní orílẹ̀-èdè ti wa.
Ọmọ Fulani náà sọ pé àwọn ọba yìí máa ńgba owó lọ́wọ́ àwọn Fulani darandaran kí àwọn tó da màlúù wọ inú ìlú kankan láti fi ẹran jẹ òko ní ìlú náà, ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń tọ́ka síi pé, pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ati ìgbaniláàyè àwọn ọba òfò àti àdánù yìí ni àwon apanijayé Fulani náà fi ńṣiṣẹ́ ọ̀daràn, bíí ìjínigbé, ìpànìyàn, olè jíjà, kíkó màlúù wọ’nú oko láti jẹ oko run, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ, ní Orílẹ̀-Èdè D.R.Y. Ẹ̀yin tí ẹ pe ara yí ní ọba yìí ti wọ wàhálà.
❗PÀJÁWÌRÌ FÚN ÀÀBÒ❗KÁÀKIRI GBOGBO ÌPÍNLẸ̀ YORÙBÁ TÍTÍ DÉ OLD Ọ̀YỌ́ EMPIRE, Ẹ MÁA YA FỌ́TÒ FÚLÀNÍ, OLỌ́PA, OLÓṢÈLÚ, SÓJÀ, TÍ Ẹ BÁ FURA SÍ ÌRÌN ÀTI ÌṢESÍ WỌN NÍ AGBÈGBÈ YÍN. KÍ Ẹ FI ṢỌWỌ́ SÍ BÀBÁ ÌJÌNLẸ̀ +905367341665 (WHATSAPP).… Pín Sórí Àgbàgbé X (Twitter)Àṣẹ̀ àwọn wèrè ọba yìí ni ìkà! Ọmọ Fulani yìí búra gidi pé kí Fulani tó wọ inú igbó ìlú kan láti lo oṣù kan sí mẹ́ta tàbí jù bẹ́ẹ̀, àwọn máa níláti lọ san owó fún àwọn ọba ìlú náà, ṣùgbọ́n èyin ará ìlú kò mọ̀ rárá, ó wá wípé, “ẹ béèrè lọ́wọ́ àwọn ọba yin, kí ẹ má ṣe sọ pé à ńwọ igbó yin lọ́fẹ̀ẹ́ rárá mọ́.”
Kí wá ni ànfàní igi tó yẹ kó ṣíji bo ni, ṣùgbọ́n tó ńpe òjò àti òòrùn lé ni lórí? Àwa ọmọ Yorùbá dẹ̀ ti ríi bayìí pé alábọ̀dé ni àwọn ọba rádaràda wọ̀nyí, wọ̀n ò sì wúlò rara ní orílè-èdè wa, bíkòṣepé agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà tó ṣì ń jẹgàba lóri ilẹ̀ Yorùbá, à bá ti kó gbogbo wọn kúrò nilẹ̀, ṣùgbọ́n àkókò díẹ̀ ló kù fún wọn. Ṣèbí àwọn baba ńlá wọn ló tá àwọn baba ńlá wa l’ẹ́rú fún àwọn aláwọ̀ funfun, àwọn ọmọ wọn náà tún ńtà àwa náà fún ẹ̀yà ìgbò àti Fulani, tí àjèjì Yorúbá, àwa I.Y.P. wá di ayálégbé lórí ilẹ̀ baba ńla wa. Ìwọ̀sí Ẹlẹ́gbin!! Ṣe ayé àwọn ọba wèrè yìí ni a wá ni? Ara àwọn ìdí nìyí tí
màmá wa Modúpẹ́ọlá Onitiri-Abiola fí sọ pé ó tó gẹ́ẹ́ fún àwọn ọba wèrè àgbà ìyà yìí, Olódùmarè tí lo ìyá wa dáradára yìí láti yọ wá nínú ìgbèkùn oko ẹrú.
Àwa Orílẹ̀-Èdè Democratic Republic of the Yorùbá kìí ṣe ará Nàìjíríà mọ́, a ti di òmìnira láti ogúnjọ́ oṣù Bélú, ẹgbẹ̀wá-ọdún-ó-lé-méjìlelogun, ìjọba Adelé wa sì ti bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbẹ̀wá-ọdún-ó-lé-mẹ́rìnlélógún, orílẹ̀-èdè wá kò sí fi àyè gba ọba rara, àti pé ọmọ Aládé ṣáà ni gbogbo I.Y.P.
Ofin wá ní yíò sọ bí àjèjì ṣe máa bá wa gbé nílùú wa, àlejò tí kò bá ti lè bọ̀wọ̀ fún òfin D.R.Y yíò fi ìlú wá sílẹ fún wa ni.