Ìròyìn tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́ sọ o, bí àwọn Fúlàní kan ṣe gbé ọmọ Yorùbá, ní ilẹ̀ Yorùbá, tí wọ́n sì de ọmọ Yorùbá yí, tí wọ́n nfi ìyà jẹẹ́, wípé kí ó máa kú díẹ̀ díẹ̀, títí tí yíò fi kú pátápátá! Lórí ilẹ̀ Yorùbá o!

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

Fúlàní Fi Ìyà Jẹ Ọmọ Yorùbá Lórí Ilẹ̀ Yorùba!

Kíni ó fa eléyi? Ìròhìn náà sọ wípé, ọmọ Yorùbá yí sọ wípé, kí màlúù àwọn Fúlàní ọ̀ún má ṣe jẹ nkan inú oko òun mọ́ o! Ìyẹn ni “ẹ̀ṣẹ̀” tí ọmọ Yorùbá yí ṣẹ̀ o!

Agbésùnmọ̀mí ìlú, nàìjíríà, àti àwọn bàbá wọn, Fúlàní, ló nṣe  eléyi ní orí ilẹ̀ Baba wa! Ìbá ṣe wípé a ti gbé ìgbésẹ̀ ní àsìkò tí ó yẹ ni, láti ọjọ́ kẹ́tàlá oṣù kẹ́rin ọdún yí, l’ẹhìn ìgbàtí ìjọba adelé wa ti wọlé, kí a ti pọ̀, lọ́pọ̀ yanturu láti lọ kí wọn káàbọ̀ ní olú-ìlú wa, Ìbàdàn, ojú wa kì bá má ti rí irúfẹ́ ìwọ̀sí yi, ní ilẹ̀ Baba wa! Ṣùgbọ́n, ẹ má mikàn rárá, iṣẹ́ nlọ láti lé àwọn gómìnà nigeria kúrò lórí ilẹ̀ wa; láìpẹ́, láìjìnnà, a máa yọ̀.