Ó mà ṣe o! Ìjọba agbésùnmọ̀mí ilẹ̀ Naijiria tó ń fipá jẹ gàba lórí ilẹ̀ wa ló fún Fúlàní ní ìgboyà láti máa kó àwọn màálù wọn wọ’nú oko – olókó tí àwọn ẹran náà sì jẹ oko éékà márùn-ún tí ó jẹ́ ti ilé-iṣẹ́ kan ní Ìpínlẹ̀ Ìbàdàn, ní Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y).

Ilé-iṣẹ́ nàá béèrè fún owó-ìtanràn bí mílíọ̀nù mẹ́fà naira lọ́wọ́ Fulani yìí, gẹ́gẹ́ bíi owó gbà má bínú, ṣùgbọ́n wọ́n kọ̀ jálẹ̀, wípé ogójì ẹgbẹ̀rún péré ní àwọn yóò san. Irú owó kí leléyìí?

Ìjẹgàba yi burú tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ará ìlú ń bẹ àwọn tó ni oko láti gbàgbé owó ọ̀hún nítorí ìbẹ̀ru kí Fúlàní má kó ogun wá bá wọ́n! Ẹ̀gbin o ní yọ̀rọ̀.

Láìpẹ́ yìí náà ni a rí fọ́nrán ọmọ fúlàní kan tó ń wípé, àwọn alátẹnujẹ tí wọ́n pe ara wọn lọ́ba ní ilẹ́ Yorùbá ló máa ń fún àwọn láṣẹ láti da ẹran wọ inú igbó, àti pé, àwọn kò leè wọ inú igbó kankan ni ilẹ̀ Yorùbá làìjẹ́ pé ọba ìlú náà ti gba owó lọ́wọ́ wọn.

Ṣebí ìnira tí a ń rí lọ́wọ́ àwọn alágbára mám’èro baba ọ̀le Naijiria tó ńjẹgàba lórí ilẹ̀ wa náà lo ń fà oríṣiríṣi yí, Fúlàní daran – daran kò lé jẹgàba l’órí ohun ìní wa.

Nítorí ìjẹ gàba àwọn agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà yìí náà ni àwọn Íbò ṣe ń sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ sí àwa ọmọ aládé.

Òjò ẹ̀sín gbogbo wọn pátá ti ṣú, kò ní pẹ́ rọ̀, ọjọ́ ń bọ̀ ni Olúwa wí! Bíkò bá ṣe ọpẹ́lọpẹ́ Elédùmarè tó rán Ìyá wa Olóyè Ìyá Ààfin Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá ní iṣẹ́ òmìnira ìran Yorùbá, ṣe ipò àìnírèti yí náà ni àwa ọmọ Yorùbá ìbá wà?

Democratic Republic of the Yorùbá latest news updates 02/09/2024

A dúpẹ́ fún òmìnira wa kúrò nínú ìlú agbèsùnmọ̀mí Naijiria ní ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbẹ̀wá-ọdún-ó-lé-méjìlélógún, tí a sì ti gba agbára ìṣèjobà ara ẹni tí Olódùmarè lo ìyá wa ìrọ̀rùn ló bá dé, láti gbà padà fún wa ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbẹ̀wá-ọdún-ó-lé-mẹ́rìnlélógún, a tí ní àṣẹ láti ṣe àkóso àwọn ibodè wa pátápátá, èyí ni a ó sì ṣe lẹ́yìn tí a bá ti lé àwọn agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà tó fi agídí ń jẹgàba lé wa lórí, olórí ìjọba Adelé wa, bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ pẹ̀lú àwọn adelé wa tó kù yóò wọlé sí ilè iṣẹ́ ìjọba láti lo òfin Orilẹ̀ èdè D.R.Y fún ìṣàkóso àwọn ibodè wa.

Gbogbo àlejò tó bá fẹ́ wọlé sí Orílẹ̀-Èdè wa níláti bọ̀wọ̀ fún òfin , tabi kí wọ́n fi orílẹ̀-èdè wa sílẹ̀.