Ẹni tí ó bá rò wípé ọkọ̀ wíwọ̀ nìkan ni ó tí gbówó lérí, nílẹ̀ Yorùbá, l’oní, irọ́ ni o! Tàbí kí o rò wípé, owó epo petiróòlù nìkan ni ó gbówó lérí! Rárá o! Ní ìpínlẹ̀ Èkó wa, ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, ẹni tí ó nfi ẹsẹ̀ rìn, pàápàá, níláti SAN OWÓ kí ó tó lè fi ẹsẹ̀ méjèèjì tí Olódùmarè fún-un, láti rìn! Èèmọ̀! ní’lẹ̀ Yorùbá!! Háàà!

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

Tinubú ààrẹ agbésùnmọ̀mí ìlú agbésùnmmí, Nigeria, ibi tí ayé rẹ bàjẹ́ po, dé, ni eléyí?! Wèrè tó nsínwín lọ́wọ́, ni’lú Èkó, Jídé Sanwó-Olú, múra si o! Máṣe tètè sá kúrò lórí àlééfà ọmọ Yorùbá ní ìpínlẹ̀ Èkó; ṣùgbọ́n, kí ìyà rẹ kí ó le túbọ̀ pọ̀ jọjọ náà ni; àmọ́ ṣá, a fi npòwe fún ẹ ni o!

say no to gmo foods, seed, crop. yoruba warns africans

Fa etí ẹ, báyi, kó aṣọ wèrè ẹ, k’o sáré jáde, ní kíakía, kúrò lórí àlééfà ọmọ Yorùbá, ní Ìkẹjà, àti ní gbogbo ìpínlẹ̀ Ekó! Máṣe mú àwọn ogún àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá lọ o! Má jalè wa o! Àkísà ẹ nìkan ni k’o o kó jáde o!

A wí táì wí, o ò kúrò l’orí àlééfà ọmọ Yorùbá, fún ìjọba adelé ìpínlẹ̀ Èkó, ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá kí ó wọ’lé; o tún jóko síbẹ̀, ìwọ aláìnírònú, lábẹ́ igi imú ẹ ni ọmọ Yorùbá, lórí ilẹ̀ Yorùbá, tún ti wá nsan owó báyi, hàà, láti f’ẹsẹ̀ wọn rìn lójú ọ̀nà.

Fifi Ẹsẹ̀ Rìn Ti Di Ọ̀wọ́n Gógó Ní Ilẹ̀ Yorùbá!

Bẹ́ẹ̀ ni o, ẹ̀yin ọmọ Yorùbá, ìròhìn tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́ sọ wípé, ní agbègbè Trade Fair, Under-Bridge, ní ìpínlẹ̀ wa, ìpínlẹ̀ Èkó, ni àwọn ọmọ kọ̀lọ̀rọ̀sí kan o, tí wọ́n ti kó’ra jọ, tí wọ́n sì sọ wípé, ẹnik’ẹni kò le RÌN kọjá lórí ẹsẹ̀ wọn níbẹ̀, láti gba ibikan níbẹ̀ kọjá, àfi kí ẹnikọ̀ọ̀kan tí ó bá fẹ́ gba ibẹ̀ kọjá kí ó kọ́kọ́ san ọgọ́run owó náírà, kí ó tó lè fi ẹsẹ̀ rẹ̀ rìn kọjá sí ibi tí ó bá nlọ!

Ẹ dúró náa, kíni gbogbo rádaràda wọ̀nyíi? Irúfẹ́ ìwà agbésùnmọ̀mí wo ni eléyi?

Láìpẹ́, láì jìnnà, Jídé Sanwó-Olú máa sá kàbàkàbà kúrò ní àlééfà ọmọ Yorùbá ní Ìpínlẹ̀ Èkó. Ohun tí àwọn ọmọ ìgboro tí wọ́n nfi’pá gba owó ìrìnsẹ̀ l’ọwọ́ ará ilú wọ̀nyí, ohun tí wọ́n rí l’ọbẹ̀, tí wọ́n fi wa irú s’ọwọ́, wọ́n á wá ṣe àlàyé ara wọn níwájú ètò ìgbẹ́jọ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá.