Nínú èdè Yorùbá, àwọn ọ̀rọ̀ kan wà tí ó jẹ́ wípé bákan náà ni kíkọsílẹ̀ wọn ṣùgbọ́n ìtumọ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ní, fífi àmì sí orí àwọn ọ̀rọ̀ bí eléyìí yóò mú kí a leè pe àwọn ọ̀rọ̀ náà bí ó ti yẹ.

A sọ eléyìí fún wa láti leè jẹ́ kí àwa ọmọ Yorùbá leè mọ pàtàkì fífi àmì sí orí ọ̀rọ̀ Yorùbá, nítorí wípé láì fi àmì sí orí ọ̀rọ̀ Yorùbá a kò ní leè pe ọ̀rọ̀ náà bí ó ti yẹ, èyí sì leè mú àbùdá bá ọ̀rọ̀ náà tàbí sọ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ nù nígbà tí òǹkàwé kò bá pèé bí ó ti yẹ.

Newest and the youngest flag in Africa is the Democratic Republic of the Yoruba Flag or Yoruba Nation flag

Tí a bá sì ṣe àkíyèsí àwa ọmọ Yorùbá lónìí, ń ṣe ni a kàn máa ń kọ àwọn ọ̀rọ̀ sílẹ̀ láì fi àmì síi, tí a kò sì ní bìkítà rárá.

Ṣùgbọ́n a dúpẹ́ lọ́wọ́ màmá wa, Modupẹọla Onitiri-Abiọla, ìyá ìran Yorùbá tí Olódùmarè rán sí wa ní àkókò yí láti ṣàwárí gbogbo ògo ìran Yorùbá tí ó ti sọnù, nítorí pé màmá ti sọ fún wa wípé, àlàkalẹ̀ ètò tí Olódùmarè gbé lé wọn lọ́wọ́ máa dá wa padà sí orísun wa. Ọmọ Yorùbá, a kú oríire!