Ìbá jẹ́ pé àwọn Adelé wa ti wọlé sí oríkò ilé iṣẹ́ ìjọba ìpínlẹ̀ wa k’ọ̀ọ̀kan jákèjádò Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá ni, àwa ọmọ Yorùbá ì bá má nípa nínú ewu tí ó wà nínú ìjàmbá àwọn oúnjẹ asekúpani tí Bill Gates àti àwọn ti wọ́n jọ ń ṣisẹ́ ibi ń pín kiri yìí, ṣùgbọ́n, àwọn agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà tó ń fipá jẹ gàba lórí ilẹ̀ wa tí gbàbọ̀dè oúnjẹ búburú yìí, nítorínáà àwa ọmọ Yorùbá níláti ṣọ́ra gidi.

Ní Orilẹ ède kan ni àgbáyé, ni ṣọ́ọ̀bù kan tó wà fún àwọn oúnjẹ irúgbìn àtọwọ́dá wọ̀nyí, olùtàjà náà ṣe àlàyé kíkún fún oníròyìn kan ti o béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ ewu wà nínú jíjẹ wọ́n?”

Say no to GMO foods in yoruba
IYP, say no to GMO seeds and foods

Obìnrin ná s’opé ewu wà níbẹ̀, ó ní àwọn oúnjẹ yìí kìí ṣe ara l’óore, nítorí kìí kúrò l’ára bọ̀rọ̀ tí à bá fi ṣe oúnjẹ, wọn sì lè dúró lára ènìyàn fún bíi odún márùn, méje tàbí mẹwa, tí o si lè fa àrùn ọlọjọ pípé sára. 

Oníròyìn náà tún tẹ̀síwájú nínú ìbéèrè rẹ̀ wípé, “Báwo l’ase lé dá oúnjẹ a ṣe’kúpani yìí mọ̀ lórí igbá tí a bá fẹ́ rà wọ́n?

Obìnrin oní sọ́ọ́bù náà fèsì pé ó nira, àti pàápàá jùlọ, ẹ̀ka tí ó wà fún ìdámọ̀ láàrín àwọn irúgbìn àtọwọ́dá yí àti ti àdáyébá kò kọbi ara síi mọ́, èyí wá mu kó rọrùn fún ilé iṣẹ́ tí ó ń pèsè àwọn oúnjẹ àtọwọ́dá wọ̀nyí láti má jẹ́ dandan fún wọn mọ́ láti fi àmì ìdánimò síi, èyí sì léwu púpọ̀.

Àìsàn kòní wọlé tọ̀ wá o, kì ojú má sì rí ibi gbogbo ara loògùn rẹ̀, gbàrà tí àwọn Adelè wá bá ti wọ̀lé sí oríkò ilé iṣẹ́ ìjọba Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá láì pẹ́ yìí, kò ní sí àyé fún ìwà aburú yìí mọ́, àwọn Adelè wa yíò bẹ́’gi dí ọ̀nà gbogo nkan rádaràda wọ̀nyí.