Ọ̀rọ̀ ètò ààbò jẹ́ ohun pàtàkì tí a kò sì gbúdọ̀ fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú, nítorí wípé, kò sì ohunkóhun tí ènìyàn leè ṣe nínú ìbẹ̀rù àti àìbalẹ̀ ọkàn. Ìjọba tó bá fẹ́ ìdàgbàsókè fún orílẹ̀ èdè rẹ̀, yóò rí ọ̀rọ̀ ààbò gẹ́gẹ́ bíi ohun àkọ́kọ́ nínú ètò ìsèjọba rẹ̀ tí ó sì gba àbójútó gidigidi.
Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe mọ̀ wípé orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá kò sí lára Nàìjíríà mọ́ láti ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbàáọdúnóléméjìlélógún tí a sì ti ṣe ìbúra wọlé fún olórí adelé wá bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ láti ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbàáọdúnólémẹ́rìnlélógún, tí wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tí Olódùmarè pè wọ́n sí èyí tí ètò ààbò tó dájú sì jẹ́ ọ̀kan gbòógì lára àwọn àlàkalẹ̀ ètò tí Olódùmarè gbé lé màmá wá lọ́wọ́, ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla, èyí tí yóò mú ọkàn gbogbo wa bálẹ̀ lórí ilẹ̀ babańlá wa.
Àwọn àgbẹ̀ wa yóò leè máa lọ sí oko wọ́n pẹ̀lú ìfọ̀kànbalẹ̀, tí kò ní sí ìbẹ̀rù àwọn ajínigbé, àwọn arìnrìn-àjò yóò leè lọ síbi tó bá wù wọ́n ní àkókò tí wọ́n fẹ́,láìsí ìfòyà àwọn alọnilọ́wọ́gbà, bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí ìbẹ̀rù lórí àwọn dúkìá wa gbogbo.
Bákan náà, àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò tí yóò máa wo ìgbòkègbodò àwọn ènìyàn yóò wà tọ̀sán-tòru, àti wípé, káàkiri orilẹ́ èdè wa ni yóò ní ohun èlò ìyàwòrán, dé bi pé, abẹ́rẹ́ tó kéré jù kò leè jábọ́ tí àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò kò ní mọ̀ ní orí ilẹ̀ wa.
Iṣẹ́ ọwọ́ Olódùmarè ni eléyìí jẹ́, nítorí náà àwa ìran Yorùbá yóò máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run wa títí láé.
Ká Ìròyìn Síwájú sí:
- ABALA ‘KEJÌ ÈRÒǸGBÀ ÀWỌN ALÁWỌ̀ FUNFUN LÓRÍ ADÚLÁWỌ̀
- Ètò Ààbò Tó Péye Ni Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá
- ÀṢÍRÍ BÍ ÀWỌN ALÁWỌ̀ FUNFUN ṢE Ń JÍ ỌRỌ̀ ÀWA ADÚLÁWỌ̀ KÓ
- ÀWỌN ARÁ ÌLÚ KỌMINÚ SÍ BÀÀLÚÙ TUNTUN TÍ ÀÀRẸ WỌN RÀ
- ÌYÀN NÍ ORÍLẸ̀ ÈDÈ ZIMBABWE