The democratic republic of the Yoruba daily news

 

Gẹ́gẹ́bí ohun tí arákùnrin náà sọ, ó ní òun gbọ́ wípé ọ̀pọ̀ nínú àwọn ẹrù ìjọ̀gbọ̀n yí wá l’ati àwọn ìlú Mali, Niger àti Chad; ṣùgbọ́n arákùnrin náà wá sọ wípé, ní t’òun o, òun wò’ye wípé kìí ṣe l’ati àwọn ìlú wọ̀nyí nìkan, ṣùgbọ́n wípé, ọ̀pọ̀l’ọpọ̀ àwon ìránṣẹ́ sọ’gboro-d’ogun yí, wípé l’ati Nigeria ni o!

Ó sọ wípé apá òkè ní ìlú tí ó f’ẹ̀gbẹ́ tì wá, èyíinì, ìlú Nigeria, ni ó jẹ́ wípé iṣẹ́ wọn ni l’ati máa da ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn aláìní-nkan-ṣe sí’nú ayé, èyíinì, àwọn àlmájìrí, àti wípé kìí ṣe ìṣòro kékeré l’ó máa dá sí’lẹ̀ ní’jọ́ iwájú o, tí ó dẹ̀ ti ndá sí’lẹ̀ kí ó tó di àkókò yí.

Ka Ìròyìn: Tí o bá fẹ́ sọ ẹ̀yàk’ẹyà di ẹrú, gba èdè àti ìtàn wọn – Wendall Donelson

Tani à bá rí bá wí, fún eléyi o? Gbogbo wa ni a mọ̀ wípé orílẹ̀-èdè Yorùbá ti bẹ̀rẹ̀ ìjọba rẹ̀ l’ati  ọjọ́ kéjìlá oṣù kẹ́rin ọdún yi, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ wípé ìjọba Nigeria ni ó fi ipá dúró l’orí ilẹ̀ wa, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ wípé iṣẹ́ ti nlọ ní gidi l’ati gbá Nigeria kúrò ní ilẹ̀ Yorùbá, tí ó jẹ́ wípé ẹ̀tẹ́ gbáà ni wọ́n máa gbé kúrò l’orí ilẹ̀ wa.

Nítorí náà, ọmọ Yorùbá ẹ má mi’kàn, ṣùgbọ́n ṣá oo, kí ẹ fi ojú tó gbogbo agbègbè yín o!

Ojú l’alákàn fi nṣọ́’rí; kí a sì ríi dá’jú dá’jú wípé a kò fi àyè gba ẹnikẹ́ni l’ati ṣe iṣẹ́ ibi kankan ní agbègbè wa, tàbí l’ati da ilú rú fún àwọn ìjọba Adelé wa.

Ìgbà díẹ̀ l’ókù o! ayọ̀ wa kò ní di ìbànújẹ́ láíláí