Láìsí àní-àní, ètò ọ̀gbìn ní orílẹ̀ èdè aláwọ̀ dúdú wà ní abẹ́ ìkọlù àti ogun tó lágbára, pàápàá ní orílẹ̀ èdè Kenya. Àwọn  amúnisìn wọ̀nyí kò fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa pín irúgbìn ìbílẹ̀ wọn mọ́ nítorí pé, irúgbìn tiwọn ni wọ́n fẹ́ kí àwọn ènìyàn ó máa gbìn.

Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe gbọ́ọ nínú ìròyìn kan wípé, wọ́n ń gba irúgbìn àwa aláwọ̀ dúdú tí wọ́n sì ń kóo lọ sí orílẹ̀ èdè Norway èyí tí ó ní ilé ìf’irúgbìn pamọ́ tí ó tóbi jù lọ ní àgbáyé. Èròǹgbà wọn náà ni láti leè jẹ́ kí àwọn adúláwọ̀ leè máa ra irúgbìn GMO lọ́wọ́ wọn.

Ṣé a ò gbàgbé àwọn aláyé tí a ṣe fún wa nípa irúgbìn GMO yí wípé, oríṣiríṣi àìsàn ni yóò máa súyọ lára ẹni tí ó bá jẹẹ́, àti pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò ní leè bí ọmọ mọ́, èso rẹ̀ kò sì ṣeé tú gbìn lẹ́ẹ̀ kéjì, bẹ́ẹ̀ sì ni ilẹ̀ tí wọ́n bá gbìn-ín sí kò tún ní leè mú èso jáde mọ́ láí. Ọ̀rọ̀ GMO yí kò wá mọ ní irúgbìn nìkan ò, wọ́n tún ń ṣe GMO ẹranko pàápàá.

Bí a ṣe rí àwọn orílẹ̀ èdè kan tí wọ́n tako irúgbìn GMO yìí, tí wọ́n sì tún fi òfin lée wípé ẹnikẹ́ni tí ó bá gbìn- ín yóò fi ẹ̀wọ̀n jura èyítí orílẹ̀ èdè Russia sì jẹ́ àpẹẹrẹ, bẹ́ẹ̀ náà ni a rí àwọn orílẹ̀ èdè tí wọ́n gbàá tọwọ́-tọsẹ̀, èyí tí orílẹ̀ èdè Kenya jẹ́ ọ̀kan lára wọn.

A tilẹ̀ gbọ́ọ nínú ìròyìn náà wípé, ìjọba àná ní orílẹ̀ èdè Kenya tún fi òfin de àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè náà láti má gbìn èso ìbílẹ̀ wọn mọ́, àfi GMO nìkan, tí àwọn ọnímọ̀ Ìjìnlẹ̀ sáyẹ́ńsì náà tún báwọn parọ́ wípé ó dára fún jíjẹ, àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ nọ́mbà ìkẹrin ni orílẹ̀ èdè Kenya wà nínú orílẹ̀ èdè tí ó ní àìsàn jẹjẹrẹ jùlọ ní Afrika báyìí látàrí irúgbìn GMO tí wọ́n ń gbìn, tí wọ́n sì ń jẹ.

Gbogbo ọgbọ́n àwọn amúnisìn yí náà ni láti leè máa ṣe àkóso oúnjẹ ní ilẹ̀ adúláwọ̀, èyí tí yóò mú kí ó rọrùn fún wọn láti lè máa darí wa bó ṣe wù wọ́n, nítorí pé ẹni tí ó bá ń fún ni ní oúnjẹ òun ni alákòóso àti olùdarí ẹni.

Òmìnira Yorùbá News Update
Ìròyìn Òmìnira Olojoojumọ – Bèrè fún ẹ̀da títí rẹ!

Kí Ọlọ́run Olódùmarè kí ó dá màmá wa Modupẹọla Onitiri-Abiọla láre títí láé. Láti bíi ọdún méjì ni màmá ti máa ń sọ fún wa wípé, gbogbo ènìyàn ní ó ń fojúrénà ogun jíjà ti ọrọ̀ ájé, ogun jíjà ti ààbò, àti ogun jíjà ti orí ilẹ̀ tó ń lọ lọ́wọ́. Ṣé gbogbo wa ti wá rí àwọn ẹ̀rí náà níwájú wa báyìí?

Ọlọ́run Olódùmarè ti bùkún Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, (I.Y.P) pẹ̀lú Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y). Àwa ọmọ I.Y.P yóò máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run Olódùmarè ni títí láé fún oore rẹ̀ láyé wa.