ÀKÍYÈSÍ PÀTÀKÌ LÓRÍ AWUYEWUYE ÀTI ÌṢẸ̀LẸ̀ TÓ NṢẸLẸ̀ KÁÀKIRI LÓRÍLẸ̀-ÈDÈ YORÙBÁ, LÁTI ORÍ NKAN Ọ̀GBÌN OLÓRÓ, ÀTI ÌGBÀLÁÀYÈ ÌBÁLÒPỌ̀ ỌKÙNRIN-SỌ́KÙNRIN, TÀBÍ OBÌNRIN-SÓBÌNRIN, TÍ ÌJỌBA ORÍLẸ̀-ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ ṢAGBÁTẸRÙ RẸ̀, TÍ Ó SÌ NJẸGÀBA… Share on X
ÀKÍYÈSÍ PÀTÀKÌ LÓRÍ AWUYEWUYE ÀTI ÌṢẸ̀LẸ̀ TÓ NṢẸLẸ̀ KÁÀKIRI LÓRÍLẸ̀-ÈDÈ YORÙBÁ, LÁTI ORÍ NKAN Ọ̀GBÌN OLÓRÓ, ÀTI ÌGBÀLÁÀYÈ ÌBÁLÒPỌ̀ ỌKÙNRIN-SỌ́KÙNRIN, TÀBÍ OBÌNRIN-SÓBÌNRIN, TÍ ÌJỌBA ORÍLẸ̀-ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ ṢAGBÁTẸRÙ RẸ̀, TÍ Ó SÌ NJẸGÀBA LÓRÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ DEMOCRATIC REPUBLIC OF THE YORUBA, LÁTI MÁA PÀṢẸ, ÀTI LÁTI MÁA PE ORÍLẸ̀-ÈDÈ YORÙBÁ MỌ́ ORÍLẸ̀-ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ. Gbogbo àwọn ẹ̀rí yí, la fi nṣọwọ́ sí Àjọ Ìgbìmọ̀ Àgbáyé.Orílẹ̀-Èdè Yorùbá àti Orílẹ̀-Èdè Nàìjíríà máa pàdé nílé Ẹjọ́ Àjọ Ìgbìmọ̀ Àgbáyé.

 

Ìwé ìròhìn orí ayélujára kàn sọ wipe Ibrahim Salihu, tí wọ́n tún ń pè ní Giwa, tí o jẹ́ olórí àwọn agbésùnmọ̀mì kan nilu Naijiria tí jẹwọ́ pé òun tí pá tó ogún ẹlẹ́ṣọ̀ọ́ ààbò ni ipinlẹ Zamfara ni Naijiria.

Gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nígbàtí àwọn agbófinró mú tí wọ́n ńfi ọ̀rọ̀ wáa lênu wò, ó ní òun tí pá tó èṣọ́ aláàbò bíi ogún tí ọ̀lọ̀pàá àti ọmọ ológun Naijiria meta wà nínú wọn tí àwọn yòókù sí jẹ́ ọlọ̀dẹ ní ìpínlẹ̀ náà.

Salihu ni àwọn aṣiwaju tó ńṣiṣẹ́ pẹ̀lú afẹ̀misòfò kàn tó ńjẹ́ Alhaji Shingi ni wọ́n kọ̀ òun bí wọ́n ti ńyin ìbọn, àti bí òun tí ńfi ìbọn Ak47 ṣiṣẹ ibi.

ÈMỌ̀ RÉ Ó: Olórí Àwọn Agbesunmọmi, Ajínigbe Afẹ̀míṣòfò Ńbẹ̀bẹ̀ Pé Ki Ìjọba Naijiria ṣe Àtúnṣe Ayé Òun Lẹ́hìn To Ti Jẹ́wọ̀ Pipa Ogun Ẹlẹ́ṣọ Ààbò Tí Ọlọ́pàá Àtí Jagunjagun Wa Nínú Wọn

Ó’ wipe ní ìjọba ìbílẹ̀ Birnin Magaji tó wà ní ìpínlẹ̀ Zamfara ni ibùba fún iṣẹ́ ibi òun.

Salisi sọ wípé àwọn obí òun ṣe aláìní gégébí ohun tó ti òun sínú irú iṣẹ́ búburú yìí. Ó tẹ̀síwájú pé àwọn tí ó lè sanwó níkan ni àwọn máa ńjí gbé.

Salisu wá ńbẹ ìjọba Naijiria fún ìrànlọ́wọ́ láti lè ṣe ẹ̀sìn òún Islam àti fún ìràpadà pẹ̀lú àtúnṣe ayé oun.

O wa sọ pé tí ọlọ̀pàá fi òun ọwọ́ ẹbi àwọn tí òun tí pá, wọn kò ní d’áríjì òun, ṣugbọn ìrònúpìwàdà ni òun fẹ́, kí iṣẹ ikú.

Ọmọ Aládé se a ri báyìí pé ààbò kò sí ní Naijiria nibiti àwọn àgbébọn ti ńpa èèyàn ṣeré, titi kan ọmọ ológun àti àwọn agbófinró, ìtìjú ńlá ní fún wọn. Ẹ̀mí aráàlú kò jọjú lọ́dọ àwọn ìkà ìjọba Naijiria àfi ìwà ìmọtaraẹni nìkan ti ba ayé wọn jẹ́,

Ọmọ Yorùbá àkókò tí tó láti gba ilẹ̀ ìní wa kúrò lówó àwọn Naijiria tí o jẹ́ arúfin, agbésùnmọ̀mí, apànìyàn.

Ààbò tí o dara wà fún wa ní Democratic Republic of the Yorùbá, ẹ jẹ́ ká dìde láti parapọ̀ gba ògo wa padà.