Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ojú àánú wo Nàìjíríà, nígbàtí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìyà wọn bá dé, irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ nílò àyẹ̀wo!

Bí a ti ngbọ́ kan, ni a tún ngbọ́ míì, ní oríṣiríṣi ìṣẹ̀lẹ̀ aburú tó nṣẹlẹ̀ ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, látàrí pé Nàìjíríà ṣáà fi ipá jẹgàba sí orí ilẹ̀ wa.

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal

Láìpẹ́ yí ni a tún rí ìròhìn, pẹ̀lú àwọn àwòrán tí ó ba ni nínú jẹ́, èyí tí ó sọ nípa bí ọkọ̀ àjàgbé kan tí ó kó páànù ìkọ́lé ṣe rọ́ lu ọkọ̀ mẹ́ta míran, ní pópó Ọ̀jọ́ọ̀-Ìwó, ní Olú-Ìlú Orílẹ̀-Èdè wa, ní Ìpínlẹ̀ Ìbàdan, agbègbè Agbowó-Ajao, ní ìlú Ìbàdan, èyí tí a gbọ́ pé ènìyàn bíi mẹ́ẹdọ́gbọ̀n ní wọ́n rò pé ó pàdánù ẹ̀mí nínú jàmbá yí, tí àwọn kan tí wọ́n fara pa sì ti wà ní ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú.

Ẹlẹ́da ọmọ Yorùbá kò lè dárí ji Nàìjíríà àti àwọn agbésùnmọ̀mí rẹ̀: báwo ni a ṣe fẹ́ ṣe eléyi sí báyi? Láarín ìgboro olú-ìlú wa!

Nàìjíríà, oò lè mú eléyi jẹ o! Ẹ̀mí àwọn tó kú sínú jàmbá ọkọ̀ yí máa béèrè, kíni Nàìjíríà ṣì nṣe, lọ́wọ́lọ́wọ́ báyi, ní orí ilẹ̀ D.R.Y, lẹ́hìn oṣù mẹ́rin, gbáko, tí a ti dá wà gẹ́gẹ́ bí orilẹ̀-èdè aṣèjọba-ara-ẹni, tí a sì ti ní ìjọba tiwa níkàlẹ̀, ṣùgbọ́n tí àwọn agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà nfi ipá dúró sórí ilẹ̀ wa, tí ẹ̀mí sì nṣòfò lójoojúmọ́!

Àsìkò yí jẹ́ èyí tí a ó máa ránti, títí láí, fún ìwà ìka, ọ̀dájú àti àìbìkítà nàìjíríà pẹ̀lú àwọn gómìnà agbésùnmọ̀mí rẹ̀, tí ó jẹ́ ọmọ àlè ni wọ́n jẹ́ ní ilẹ̀ Yorùbá.

Ṣùgbọ́n, ohun tí ó máa lé wọn ni ó máa lé wọn o, ní àìpẹ́ àti ní àìjìnà dẹ̀ ni.

Ní agbára Olódùmarè, ìjọba-Adelé Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá máa wọlé sínú gbogbo oríkò ilé-iṣẹ́ Ìjọba wa, káàkiri ìpínlẹ̀ méjèèje láìpẹ́ yí, ìrọ̀rùn á wá dé fún gbogbo ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, ní orí ilẹ̀ Baba wa!

Ẹ má ṣe jẹ́ kí á dàgunlá, ẹ jẹ́ kí a máa retí ìfarahàn àánú Olódùmare, ṣùgbọ́n, ìwọ Nàìjíríà, ìparun rẹ ti dé.

Democratic republic of the Yoruba ominira new update | Yoruba Nation | Newest Nation in Africa, Youngest country in the World 2024
Ìròyìn Òmìnira Olojoojumọ – Bèrè fún ẹ̀da títí rẹ!