Láti ìbẹ̀rẹ́ ayé ọmọ Yorùbá ni a ti mọ̀ wípé iṣẹ́ àgbẹ̀ ni iṣẹ́ àwon baba nlá wa, ẹni tí kò ṣe iṣẹ́ yíò jalè.  Ṣùgbọ́n ó jẹ́ oun tí ó b’anìyàn ní inú jẹ́, kí àjòjì máa wá sí orílẹ̀ èdè Yorùbá láti wá fi ọwọ́ lalẹ̀ fún àwa ọmọ aládé.

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

Àwon ajíríyà, aláyé bààjẹ́, agbésùnmọ̀mì, aríremáṣe, tí wọ́n jẹ́ amúlégbè wa ni wọ́n ti gbé agbára fún Fúlàní lọ́wọ́, nítorí wípé wọ́n fẹ́ máa dá ẹ̀mí ọmọ I.Y.P. ní ègbodò.

Eléyi Ṣẹlẹ̀ Ní Yàjóyàjó Ní Orílẹ̀ Èdè Yorùbá D.R.Y. Ní Old Ọyọ Empire Tí Wọ́n Pè Ní (Kwara).  Fúlàní Da Màlu Wọ Inú Okoo'lóko, Fúlàní Náà Sì Fi Ara Síìko

Àwa ọmọ I.Y.P. tí a jẹ́ àgbẹ̀ gbọ́dọ̀ dìde fún  ètọ́ wa àti láti gba ara wa kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n pe ara wọn ní Ọba, nítorí wípé kò sí Ọba ní ilẹ̀ D.R.Y., Àwon jàndùkú wọ̀nyí ni wọ́n kó màlu fún àwọn Fúlàní yí wípé, kí wọn máa fi jẹ oko, ẹni kẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀ kí Fúlàní paá, láti lè má jẹ́ kí àwọn àgbẹ̀ lọ máa dá oko, kí ebi máa pa ọmọ Yorùbá I.Y.P. ní orílẹ̀ èdè baba wọn.

Nígbàtí gbogbo  àwon aláyé  bàjẹ́ sì mọ̀ wípé orílẹ̀ èdè Yorùbá ti yọ kúrò ní ìlú Nigeria, láti 20th November, 2022. llẹ̀ Yorùbá  sì ti dúró gẹ́gẹ́bí orílẹ̀ èdè, láti 12th April 2024, ilẹ̀ Yorùbá sì ti ní ìjọba tiwa, Olórí Adelé wa ni, Ọ̀gbẹ́ni Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́. Tí wọ́n sì ti  nṣẹ iṣẹ́ takun takun pẹ̀lú àwọn adelé yíó kù.

Ká Ìròyìn Síwájú sí:

Àwa ọmọ Yorùbá, I.Y.P, ti D.R.Y. ní láti dìde kí a gba ara wa silẹ̀ lọ́wọ́ àwọn agbésùnmọ̀mí, aláyé bàjẹ́, aríremáṣe, ti amúlégbè, ti ilẹ̀ Nigeria tí wọ́n njẹ gàba ní ilẹ̀ Olómìnira tiwan’tiwa. Àgbàrá ò ní òun ò ní ilé wó sùgbọ́n onílé ni ò ní gbà fun.

Eléyi Ṣẹlẹ̀ Ní Yàjóyàjó Ní Orílẹ̀ Èdè Yorùbá D.R.Y. Ní Old Ọyọ Empire Tí Wọ́n Pè Ní (Kwara).  Fúlàní Da Màlu Wọ Inú Okoo'lóko, Fúlàní Náà Sì Fi Ara Síìko