Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

Mo wá kí gbogbo àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, káàkiri gbogbo àgbáyé.

Mo kí gbogbo àwọn ọmọ ogun wa, tí wọ́n wà ní àhámọ́ abẹ́ àwọn agbésùnmọ̀mí Nigeria tí wọ́n wà ní orí ilẹ̀ wa. Mo kí àwọn ọmọ ogun wa wípé wọ́n kú akin íṣe; wọ́n sì kú ìfọkànsìn orílẹ̀-èdè baba wọn.

Mo kí ìyá-ààfin wa, Chief (Mrs) Modúpẹ́ Onítirí aya Abíọ́lá, tí Ọlọ́run lò fún gbogbo Ìran Yorùbá, l’ati kó wa kúrò nínú oko ẹrú, èyí tí wọ́n sì ti ṣe àṣeyọ’rí rẹ̀, tí iṣẹ́ sì nlọ l’ọwọ́.

Mo wá fẹ́ kí ẹ mọ̀ wípé àyájọ́ t’oní jẹ́ àyájọ́ June 12, ọjọ́ kéjìlá oṣù kẹ́fà, èyí tí àwọn orílẹ̀-èdè Nigeria nṣe ìránti rẹ̀; tí àwa orílẹ̀-èdè Yorùbá náà, tí a sì nṣe ìrántí rẹ̀.

Ka Ìròyìn: Ìfọ́’jú Tí Ó Wà Nínú “One Nigeria”

Ṣùgbọ́n, mo wá l’ati ṣe ìyànyànná l’aárin orílẹ̀-èdè méjèèjì, nítorí wípé kò jẹ́ ìkankan náà.

Àyájọ́ èní jẹ́ ọjọ́ tí a nṣe ìrántí Olóògbé Chief MKO Abíọ́lá, tí wọ́n já’de kúrò ní’lé àyé. Chief MKO Abíọ́lá jẹ́ ẹni t’ó ní ìfẹ́ ará ilú, tí ó sì jẹ́ ẹnití a di’bò yan, tí ó jẹ́ ol’orí, tí wọ́n sì di’bò yàn gẹ́gẹ́bí ààrẹ ní orìlẹ̀-èdè Nigeria, ṣùgbọ́n tí wọn kò jẹ́ kí wọ́n dé ipò ààrẹ náà títí wọ́n fi já’de kúrò l’ayé.

Olori Adele of the democratic republic of the Yoruba government address to indigenous yoruba people

Chief MKO jẹ́ ẹni tí ó ní’fẹ́ ará ìlú púpọ̀ jù, tí ó dẹ̀ jẹ́ ol’oṣè’lú t’òótọ́.

Nípasẹ̀ ìgbà ti Chief MKO já’de sí ìta l’ati ṣe olórí, ìgbà yẹn gan-an gan ni a tó ṣẹ̀ mọ ohun t’ó njẹ́ kí a máa ṣe ìjọba-tiwantiwa l’otítọ́; tí wọ́n sì jẹ́ ẹni t’ó já’wé olúborí, tí wọn kò jẹ́ kí wọ́n dé ipò ààrẹ.

Ikú Chief MKO Abíọ́lá yi, òun l’ó bí ìjọba olómìnira tiwantiwa t’òótọ́, èyí tí gbogbo wa njẹ ìgbádùn rẹ̀ l’oní.

Chief MKO jẹ́ ẹni t’ó ní ìfẹ́ ará ìlú, tí àwọn ènìyàn sì ní’fẹ́ wọn. L’orí òótọ́ yi ní wọ́n kú lé l’orí, tí a lè fi rí ààyè l’ati ṣe òmìnira ti tiwa, èyí tí a fi jẹ́ orílẹ̀-èdè olómìnira tiwantiwa ti ilẹ̀ Yorùbá ní ọjọ́ ti t’òní.

Ka Ìròyìn: Ọmọ-Alade Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá Ṣe Àlàyé Nípa Ìbò Dídì Ní D.R.Y

Àyájọ́ t’òní jẹ́ ọjọ́ tí a nṣe ìrántí ìkẹ́dùn olóògbé tí wọ́n pa ní ilẹ̀ Nigeria.

Gbogbo àwọn tí wọ́n nṣe ìwọ́de káàkiri ní orílẹ̀-èdè Yorùbá, wọ́n nrú òfin ni; a sì fẹ́ kí gbogbo wọ́n mọ̀ wípé gbogbo ìrú’fin wọ̀nyí l’a nkójọ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí.

A ti fi òpin sí gbogbo ẹgbẹ́ ní Orílẹ̀-Èdè Yorùbá. Nítorí náà, ẹgbẹ́k’ẹgbẹ́ kankan tàbí ẹnik’ẹni kankan t’ó bá nṣe ìwọ́de l’orí ilẹ̀ wa, ó ti rú òfin Orílẹ̀-Èdè Yorùbá.

Ìjọba Nigeria nrú òfin ní orílẹ̀-èdè Yorùbá.

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí.

Mo wá fẹ́ k’ẹ mọ̀ wípé gbogbo ìgbé’sẹ̀ kí’gbésẹ̀ tí gbogbo àwọn ìgbìmọ̀ kí’gbìmọ̀, l’ati ara àwọn agbésùnmọ̀mí Nigeria, tí wọ́n nṣe l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá òun ni ó máa f’ojú jó’fin ní abẹ́ òfin gbogbo ìgbìmọ̀ gbogbo àgbáyé.

Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ wípé a nkó àwọn ẹ̀rí jọ l’orí gbogbo àwọn gómìnà tí ó yẹ kí ó ti fi orí àléfà sí’lẹ̀ l’ati ìgbà tí Orílẹ̀-Èdè Yorùbá ti dúró, ṣùgbọ́n tí wọ́n nṣe àbòsí, wọ́n sì nṣ’ète, wọ́n sì pe’ra wọ́n ní ọmọ Yorùbá, tí wọ́n pa ìdí àpò pọ̀ pẹ̀lú ìjọba Nigeria l’ori ilẹ̀ Yorùbá.

Wo eto ti o da’lori June 12 nipa baba wa MKO Abiola

 

Ní báyi, mo fẹ́ kí gbogbo àwa ọmọ Yorùbá, kí a fi ọkàn ara wa ba’lẹ̀, kí a sì ní ìrètí tó pọ̀; t’orí pé a mbá iṣẹ́ lọ, a kò sì dúró rárá. Gbogbo nkan nlọ l’etò l’etò, ní mẹ̀lọ mẹ̀lọ.

Nít’òótọ́, àwọn agbésùnmọ̀mí Nigeria, wọ́n nṣe ìdíwọ́, ṣùgbọ́n èyí tí kò dí wa l’ọwọ́ rárárárá. A mbá iṣẹ́ wa lọ. Mo wá fẹ́ kí ẹ ní ìrètí t’ó pọ̀, tìtorí wípé ìgbà kékeré báyi l’ó kù kí ohun gbogbo ó fi di òun.

Ka Ìròyìn: Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá (MOA) S’ọ̀rọ̀ Ní Àyájọ́ June 12

Ilẹ̀ Yorùbá ti dúró, a sì ti fẹ́ parí iṣẹ́ tí a mbá lọ.

Mo wá fẹ́ kí ẹ máa ṣe ìmúra sí’lẹ̀ fún ìgbáradì tí a fẹ́ ṣe ìwọ́de rẹ̀, tí a máa jó, tí a sì máa yọ̀; tí a máa fi ìdùnnú àti ayọ̀ ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn adelé, àti ìjá’de káàkiri gbogbo ìpínlẹ̀ méjèèje orìlẹ̀-èdè Yorùbá, ní pápá ìṣeré tí ó tó’bi jùlọ ní orílẹ̀-èdè Yorúbá.

Toò, mo tún wá kí wa wípé a kú àf’ojús’ọnà ọjọ́ yi, ọjọ́ nlá yi, tí a máa jó, tí a sì máa yọ̀, níwájú Olódùmarè tí ó dá wa sí àyè wa gẹ́gẹ́bí ìran ọmọ Yorùbá.

Mo wá dá’nu dúró ná.

Kí Ọlọ́run Ọba Olódùmarè kí ó bùkún gbogbo àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá ti Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (I.Y.P, D.R.Y).