A le pe ìran ni ẹbí, nítorí náà, ẹ jẹ kí á pe ìran Yorùbá tuntun yìí ní ẹbí, ẹ jẹ́ kí a kíyèsí ẹbí, tí ó jẹ́ baba, iya àti àwọn ọmọ wọn tí ẹbí wọn bá ní ìpìlẹ̀ rere, tí gbogbo wọ́n ba sì ni ìfẹ́ ìjìnlẹ̀, a ó ri wípé tí ìfẹ́ àìs’ẹ̀tàn bá ti wà nínú ẹnìkọ̀ọ̀kan won sí ara wọn, ó máa jẹ́ ìnira fún ẹnikẹ́ni láti ìta kí ó tó lè rí àyè láti wọ àárín wọn, nítorí wípé, wọn dúró bíi òṣùṣù ọwọ̀ tí a fi okùn dì, tí ó sì le daindain, tí ó sì máa ṣòro fún ẹnikẹ́ni láti ṣẹ́ẹ sí méjì.
Bákan náà ní ìran ṣe jẹ́, tí a bá le gbàgbé pe, èmi ni ti Júù tàbí ti Elénì, tí a bá gbé ìpìlẹ̀ ọ̀tun, èyí tí màmá írọ̀rùn, MOA, gbé kalẹ̀ fún wa ní Democratic Republic of the Yorùbá, pẹ̀lú ìfẹ́ àìlàbààwọ́n yii, kí a kúrò nípò gaga ọwọ̀ tí a ti wà láti àìmọ’ye ọdún yìí wá, tí kò mú èso kankan wá fún ìran Yorùbá, tí ó sì rọrùn láti ṣẹ́ sí wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́, pàápàá, tí ó tún ju méjì lọ, tí a bá dúró bii òṣùṣù ọwọ̀ tí a fi okùn dì daindain, tí kò ṣeé ṣẹ́ sí méjì, henhen!, ìyẹn ni ó máa fún wa ní agbára tí a lè fi fi ọwọ́so’wọ́pọ̀ tí ó máa ràn wá lọ́wọ́ láti le tètè dé ibi ìlépa wa tí a ti ń pòngbẹ rẹ̀, tí kò sì ní sí àyè fún àtakò láti ìta, tí a ó sì lè tètè lé àwọn orílè-èdè tí wọn ti wà lókè bá.
Èrèdí atótónu tòní ni wípé, ìfẹ́ ni ìpìlẹ̀ ohun rere gbogbo, lẹ́yìn ìfẹ́ ni ìf’ọwọ́so’wọ́pọ̀ bíi ti òṣùṣù ọwọ̀ ti a de ni okun daindain, nítorí pé, àgbájọ ọwọ́ ni a fi ń sọ’yà, èyí ni ó sì máa fún wa ní agbára láti ṣe àṣeyọrí.
Àwa Indigineous Yorùbá People, ẹ jẹ́ kí á ṣe ara wa ní òṣùṣù ọwọ̀ kí á baà le jèrè Democratic Republic of the Yorùbá.
Ká Ìròyìn Síwájú sí:
- ÈÈMỌ̀! WỌ́N PÈÉ NÍ ÌFÈTÒ-SỌ́MỌ́-BÍBÍ, ṣùgbọ́n ètò ìpànìyàn ni
- ÒYÌNBÓ AMÚNISÌN NI Ó BẸ̀RẸ̀ YÍYAN YORÙBÁ JẸ !