Gbogbo ijọ́ kọ̀ọ̀kan tí ìjọba Agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà bá ṣì jẹgàba sí orí-ilẹ̀ Democratic Republic of the Yoruba, ni wọ́n máa jẹ́jọ́ ẹ̀sùn ẹ̀jẹ̀ ọmọ Yorùbá tí ó nti ọwọ́ wọn ta sílẹ̀.

Kò sí Bojú-bojú kankan mọ́; a mọ̀ pé àwọn òyìnbó amúnisìn ni ó nṣe ìdarí nàìjíríà, láti ìta; a dẹ̀ mọ̀ pé àwọn ọ̀gá, emir àti olóṣèlú Fulani ni wọ́n nlò nínú Nàìjíríà fúnra rẹ̀; tí àwọn Fúlàní ọ̀ún tún wá ní olùsọ̀gbè ọmọ-àlè, alábọ̀dè Yorùbá – àwọn ọba, bọ̀rọ̀kìní, ọ̀mọ̀wé, àti olóṣèlú Nàìjíríà tí wọ́n pera wọn ní Yorùbá.

Àwọn ọmọ-àlè Yorùbá yí ni wọ́n nfi àyè gba apànìyàn Fulani, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n mọ̀ pé kò sí ilẹ̀ Democratic Republic of the Yoruba lára Nàìjíríà mọ́, láti ogúnjọ́ oṣù bélú, ẹgbàá ọdún ó lé méjìlélógún; pàtàkì, bẹ́ẹ̀, láti ọjọ́ kéjìlá oṣù igbe ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rinlélógun tí a ti gbé ìjọba D.R.Y wọlé; àwọn ọmọ-àlè Yorùbá yí ni wọ́n nfi àyè gba àwọn apànìyàn Fulaní wọ̀nyí láti máa ṣe ọṣẹ́  ní orí-ilẹ̀ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá.

Ọmọ-Àlè Yorùbá nṣiṣẹ́ fún Fulani; Fulani nṣiṣẹ̀ fún òyìnbó amúnisìn, àti fún ara wọn náà; bẹ́ẹ̀ ni Òyìnbó Amúnisìn nṣiṣẹ́ fún ara wọn, láti lè máa kó ọrọ̀-ajé Yorùbá.

❗PÀJÁWÌRÌ FÚN ÀÀBÒ❗KÁÀKIRI GBOGBO ÌPÍNLẸ̀ YORÙBÁ TÍTÍ DÉ OLD Ọ̀YỌ́ EMPIRE, Ẹ MÁA YA FỌ́TÒ FÚLÀNÍ, OLỌ́PA, OLÓṢÈLÚ, SÓJÀ, TÍ Ẹ BÁ FURA SÍ ÌRÌN ÀTI ÌṢESÍ WỌN NÍ AGBÈGBÈ YÍN. KÍ Ẹ FI ṢỌWỌ́ SÍ BÀBÁ ÌJÌNLẸ̀ +905367341665 (WHATSAPP).… Pín Sórí Àgbàgbé X (Twitter)

A mọ̀ pe ohun tí ó nṣẹlẹ̀ nìyí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé oríṣiríṣi ọ̀nà ni wọ́n ngbe gbà: bí wọ́n ti ngbe gba ọ̀nà NGO, ni wọ́n ngbe gba ọ̀nà GMO; bí wọ́n ti ngbe gba ọ̀nà IMF, ni wọ́n ngbe gba ọ̀nà Bánkì Àgbáyé; bí wọ́n ti ngbe gba ọ̀nà àjàkálẹ̀ àrun, ni wọ́n ngbe gba ọ̀nà ayédèrú abẹ́rẹ́ àjẹsára; gbogbo rẹ̀, ọ̀nà àti dín iye ọmọ ènìyàn kù ní àgbáyé; pàtàkì jùlọ, àwa aláwọ̀dúdú, kí wọ́n lè gba ilẹ̀ wa – ní pàtàkì, pàápàá, ilẹ̀ ọmọ Yorùbá.

Bí àwọn òyìnbó ṣe nfẹ́ ilẹ̀ wa, kí wọ́n lè máa ṣàkósò àlùmọ́nì wa, bẹ́ẹ̀ni Fúlàní nfẹ́ ilẹ̀ wa fún àwọn Fulani alárìnkiri káàkiri Áfríkà – èyí tí ó sì jẹ́ pé kí àwọn daran-daran máa pa àwọn àgbẹ̀ wa, nínú oko wọn, jẹ́ ọkan tààrà tí wọ́n fi nṣe ikú pa ọmọ Yorùbá látàrí kí wọ́n le kó wa kúrò nlẹ̀, ṣùgbọ́n tí Olódùmarè, Ẹlẹ́da Yorùbá kò gbà fún wọn.

Ìgbà tí a bá ti lé agbésùnmọ̀mí nàìjíríà kúrò lórí ilẹ̀ wa, ni a ó lè ṣe àkóso gbogbo ilẹ̀ Democratic Republic of the Yoruba, tí gbogbo àrífín Fulàní yí máa kúrò nílẹ̀. Nítorí náà, ijọ́ kọ̀ọ̀kan tí Nàìjíríà bá ṣì dúró lórí ilẹ̀ wa, ní ẹ̀ṣẹ̀ àti ọ̀ràn dídá gbogbo ẹ̀jẹ̀ Yorùbá tí ó nta sílẹ̀ wà lọ́rùn wọn o! Kí wọ́n gbọ́, kí wọ́n yáa kúrò lórí ilẹ̀ wa.

Ìròhìn tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́ sọ pé, ní Ọjọ́ Ìṣẹ́gun tí ó kọjá yí, ní ìlú Ìfira-Àkókó, Orílẹ̀-Èdè wa, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá yí, ni ọmọ ọdún mẹ́ẹdógún kan, Joshua Gbàdàmọ́sí, tí ṣalábapàdé ikú òjijì, nígbàtí àwọn tí wọ́n kà sí daran-daran Fúlàní gún-un lọ́bẹ, tí ó sì kú; nínú oko rẹ̀ ní Ogudu. Ọmọ adúgbò Odoro ní Ìfira ni a gbọ́ pé ọmọdékùnrin náà jẹ́.

Ká Ìròyìn Síwájú sí: FULANI TI TÚ ÀṢÍRÍ ÀWỌN TÓ NPE ARA WỌN NI ỌBA NÍLẸ̀ YORÙBÁ

Gbogbo kátikàti tí àwọn kan tí wọ́n pè ní ọba ní agbègbè náà sọ, kò kàn wá – bí wọ́n ṣe máa nwí nígbàtí Fúlàní bá ti pa ọmọ Yorùbá nìyẹn! Àwa ti di Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá; kí Nàìjíríà ó kó ìwà agbésùnmọ̀mí àti ajẹgàba wọn kúrò lórí ilẹ̀ wa, ìyẹn ni a dúró lé lórí; Èdùmàrè, rànwá lọ́wọ́, ran ìránṣẹ́ rẹ, Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá lọ́wọ́; ran ìjọba-Adelé wa lọ́wọ́, kí ojú kí ó ti agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà; a dúpẹ́ pé O kò fi wá lé wọn lọ́wọ́, ṣùgbọ́n O bá wa lé wọn jáde; láìpẹ́ yí, Olódùmarè, jẹ́ kí gbogbo àgbáyé gbọ́ bí a ṣe nyọ̀ ayọ̀ yí, tí O sì mú àwọn Ìjọba-Adelé wa wọlé sí gbogbo oríkò Ilé-Iṣẹ́ Ìjọba Wa káàkiri Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá.

Democratic republic of the Yoruba ominira new update | Yoruba Nation | Newest Nation in Africa, Youngest country in the World 2024
Ìròyìn Òmìnira Olojoojumọ – Bèrè fún ẹ̀da títí rẹ!