Ṣé ní, ọ̀pọ̀ ọdún s’ẹhìn báyi, ni àwọn òyìnbó, pẹ̀lú agbátẹrù ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà, nínú èyí tí a ti wá jáde báyi, bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìpolongo ìfètò-sọ́mọ-bíbí, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ni wọn ò fura nígbà náà, l’ọhún, pé ó ní iṣẹ́ ibi kan tí wọ́n fẹ́ ṣe.
Ẹ jẹ́ kí á rántí, pé, ní àìpẹ́ púpọ̀ s’ẹhìn, ni Màmá wa, Olùgbàlà tí Olódùmarè rán sí ìran Yorùbá, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, sọ fún wa pé, a ṣì máa bí’mọ si o! Ó ní ìdí tí Màmá fi sọ bẹ́ẹ̀.
Ṣùgbọ́n ohun tí àwa lè sọ gẹ́gẹ́bí ìròhìn tí a gbọ́, àti àwọn ìrírí nínú ìrìn-àjò sí Òmìnira Yorùbá, ni pé, tẹ́lẹ̀ntẹ́lẹ́rí, àwa aláwọ̀dúdú, pàápàá àwa Yorùbá, máa mbí’mọ pọ̀ ju àwọn òyìnbó lọ. Pẹ̀lú ohun tí a ti wá mọ̀, báyi, nípa bí àwọn òyìnbó amúnisìn ṣe fẹ́ dín aláwọ̀dúdú kù ní àgbáyé, ó ti wá nyé wa báyi ìdí tí wọ́n fi npolongo ìfètò sọ́mọ-bíbí!
Ṣebí kí a tó bẹ̀rẹ̀ sí nkan tí wọ́n npè ní ìfètò-sọ́mọ-bíbí yí, ebi ò pa wá; ẹ̀yìn ìgbà tí a wá sọ pé a nfi ètò sọ́mọ-bíbí gan-an ni ebi ṣìṣẹ̀ wá nṣe wá lọ́ṣẹ́! Bẹ́ẹ̀ ohun tí wọ́n dẹ̀ sọ fún’wa nígbà yẹn ni pé fífi “ètò” sí ọmọ bíbí ni yíò jẹ́ kí á le tọ́jú àwọn ọmọ wa dáadáa.
❗PÀJÁWÌRÌ FÚN ÀÀBÒ❗KÁÀKIRI GBOGBO ÌPÍNLẸ̀ YORÙBÁ TÍTÍ DÉ OLD Ọ̀YỌ́ EMPIRE, Ẹ MÁA YA FỌ́TÒ FÚLÀNÍ, OLỌ́PA, OLÓṢÈLÚ, SÓJÀ, TÍ Ẹ BÁ FURA SÍ ÌRÌN ÀTI ÌṢESÍ WỌN NÍ AGBÈGBÈ YÍN. KÍ Ẹ FI ṢỌWỌ́ SÍ BÀBÁ ÌJÌNLẸ̀ +905367341665 (WHATSAPP).… Pín Sórí Àgbàgbé X (Twitter)Ọmọ mélo ni a le tọ́jú wọn dáadáa nísiìyí tí a ti sọ pé a nfi “ètò” sí ọmọ-bíbí?
Tí a ò bá ní tan ara wa jẹ, ó hàn gbangba báyi, pé, ìpolongo “ìfètò-sọ́mọ-bíbí” tí àwọn òyìnbó ṣe agbátẹrù rẹ̀, nígbà náà, kìí ṣe ìfẹ́ kankan tí wọ́n ní sí kí a le tọ́jú àwọn ọmọ wa: kàkà bẹ́ẹ̀, ara kí wọ́n máa dín iye aláwọ̀dúdú kù ni.
Bẹ́ẹ̀ kẹ̀ dẹ̀ ré, kìí ṣe pé àwọn babanlá-baba wa kò fi ètò sí ọmọ bíbí nígbà ayé wọn; rárá o, wọ́n tilẹ̀ nfi ètò sí ọmọ bíbí gidi ni! Àwọn babanlá wa ní ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ti Yorùbá, tí Olódùmarè fún wọn, tí ó jẹ́ pé nígbà-kúùgbà tí wọn kò báì tíì fẹ́ kí ìyàwó kan ó lóyún, ó ní bí wọ́n ti máa nṣeé, gẹ́gẹ́bí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ti Yorùbá. Nítorí èyí, irọ́ gbàà ló wà ní’di pé aláwọ̀dúdú tàbí Yorùbá kìí fi ètò sí ọmọ bíbí!
Wàhálà tí a ní, gẹ́gẹ́bí Màmá ti fi yé wa, ni pé, kí a máa rò pé ohun tiwa kò dára – inkan tí àwọn òyìnbó dẹ̀ nfẹ́ nìyẹn! – kí ó jẹ́ pé ohun tí àwọn bá ti sọ ni aláwọ̀dúdú gbọ́dọ̀ máa ṣe!
Àwọn ni ó gbé ìpolongo ọ̀rọ̀ “ìfètò-sọ́mọ-bíbí” yí jáde nígbà náà, tí àgbáyé sì gbàá bí ọtí! Ṣùgbọ́n, nísiìyí, ojú wa ti là sí òtítọ́!
Nígbà náà l’ọhún ni a bẹ̀rẹ̀ sí gbọ́ nípa àjọ kan tí àwọn òyìnbó pè ní “Planned Parenthood;” tí a ò sì mọ̀ pé àjọ ṣẹ́’yún-ṣẹ́’yun ni wọ́n, ṣùgbọ́n tí a rò pé nṣe ni wọ́n ní ìfẹ́ aráyé, tí wọ́n sì fẹ́ kí á bí iye ọmọ tí a bá le tọ́jú rẹ̀.
Ìròhìn tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ní àìpẹ́ yí, pẹ̀lú fídíò, fi hàn wá pé àwọn àjọ ìfètò-sọ́mọ-bíbí yí ní ilé-iṣẹ́ kan ní Houston, Texas, tí ó jẹ́ pé wọ́n máa nṣẹ́ oyún tí ó tó oṣù mẹ́fà pàápàá, tí ó sì jẹ́ pé wọ́n máa ntà wọ́n ni!
Èyí tún wá fi hàn wá pé, kìí ṣe kí wọ́n dín iye ènìyàn tí ó wà ní agbáyé kù, nìkan, ni iṣẹ́ ibi tí àwọn òyìnbó wọ̀nyí nṣe, ṣùgbọ́n wọ́n tún nta àwọn ọmọ oyún-inú tí wọ́n bá ṣẹ́ fún àwọn tí wọ́n nfi wọ́n ṣe ìwádi!
Ohun abẹ́lẹ̀ ni ọ̀rọ̀ yí jẹ́, ṣùgbọ́n tí àṣírí ti wá tú báyi!
Ohun tí ó ṣe pàtàkì fún àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, ni pé, oko ẹrú tí a ti bọ́ nínú rẹ̀ yí, ẹ má ṣe jẹ́ kí á padà sínú rẹ̀ mọ́! Wípé òyìnbó sọ nkankan kò túmọ̀ sí pé ohun tí Olódùmarè fẹ́ kí á ṣe níyẹn!
Ká Ìròyìn Síwájú sí:
- ÒYÌNBÓ AMÚNISÌN NI Ó BẸ̀RẸ̀ YÍYAN YORÙBÁ JẸ !
- Ẹ̀KỌ́ PÀTÀKÌ LÓRÍ Ọ̀RỌ̀ ÌLÚ GẸ̀Ẹ́SÌ: ỌMỌ YORÙBÁ, Ẹ MÁA BỌ̀ N’LÉ
- ÀJÀKÁLẸ̀ ÀRÙN MPOX: OLÓRÍ ÀJỌ ÌWÒSÀN ÀGBÁYÉ SỌ̀RỌ̀ SÍTA
- KÍ NÀÌJÍRÍÀ Ó KÚRÒ LÓRÍ ILẸ̀ YORÙBÁ NI KÓKÓ
- ÈÈMỌ̀ WỌ̀LÚ NÀÌJÍRÍÀ! ÀWỌN Ọ̀DỌ́MỌBÌNRIN ŃTA ẸYIN INÚ WỌN LÁTI RA IRUN ÒYÌNBÓ NÍTORÍ OGE.