Ọmọ Yorùbá!!! Èèmọ̀ wọ’lú o! Àwọn ọ̀tẹ’lẹ̀múyẹ́ ìlẹ̀ Yorùbá tí gbé èsì ìwádi kan tí wọ́n ṣe ní ilẹ̀ Yorùbá já’de o! Ọ̀rọ̀ ti bàjẹ́ pátápátá o! àfi kí Ọlọ́run tìkárarẹ̀ ó gbà wá o!

L’ọnà kíní, ó ṣ’oro báyi o! l’ati mọ ẹni tí ó jẹ́ ọmọ Yorùbá o! Ọ̀pọ̀l’ọpọ̀ àdàmọ̀dì ènìyàn l’ó wà ní ilẹ̀ Yorùbá, báyi o! tí ó jẹ́ wípé wọn kìí ṣe ọmọ Yorùbá, rárárárá, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ wípé ẹ ò le mọ̀, L’AYÉ, wípé wọn ò kìí ṣe ọmọ Yorùbá!

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

Báwo ni a ṣe fẹ́ ṣe eléyi sí o! L’ọnà kíní ná, àwọn náà á gbé ara wọn sí’ta ní’gbatí àwọn ìjọba wa bá ti wọ’nú Secretariat tan, wọ́n á sọ wípé àwọn fẹ́ jẹ ànfààní gẹ́gẹ́bí ọmọ Yorùbá, bẹ́ẹ̀ wọn kìí ṣe Yorùbá rárárárá!

Àìfura l’ó ṣe wá o! l’ati ilẹ̀ pẹ̀pẹ̀ wá! Wọ́n ti wọ̀ wá l’ara tipẹ́tipẹ́! Wọ́n bá àwọn ọmọ wa d’àgbà papọ̀, ní àdúgbò, wọ́n bá wọn lọ sí ilé-ìwé papọ̀! wọ́n dà wọ́n mọ́’ra papọ̀! A ti fi gbogbo ilé àti ọ̀nà wa hàn wọ́n!

A ti’lẹ̀ máa ndun’nú wípé wọ́n ti gbọ́ èdè wa! L’aìmọ̀ wípé bí wọ́n ṣe sún típẹ́típẹ́ mọ́ wa yẹn, ìpal’ara gbáà ni ó jẹ́ fún wa! A ti wá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìṣe’jọba orílẹ̀-èdè Yorùbá, báyi, fún ọmọ Yorùbá òtítọ́, báwo ni a ṣe fẹ́ mọ ẹni tí ó jẹ́ ọmọ Yorùbá nít’òótọ́?

ÈÈMỌ̀ NÍ'LẸ̀ YORÙBÁ!!! Ọ̀TẸ'LẸ̀MÚYẸ́ ILẸ̀ YORÙBÁ TI GBÉ ÈSÌ ÌWÁDI KAN JÁ'DE O!

 

L’oótọ́, ìjọba wa máà ní àgbéka’lẹ̀ òfin fún tani ó jẹ́ ọmọ Yorùbá gidi. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn tí àwọn ọ̀tẹ’lẹ̀múyẹ́ ṣe alábapàdé rẹ̀ nínú ìwádi abẹ́lẹ̀ wọn yí, wọn kìí ṣe ọmọlúàbí tí ó máa nsọ òótọ́ o!

Wọ́n ti rẹkẹ sí’lẹ̀ dè wá wípé àwọn máa pe ara wọn ní Yorùbá, kété tí ìjọba Yorùbá  bá ti wọ’lé sí’nú Secretariat l’ati bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ l’ojú páálí gan-gan-gan.

Ní òtítọ́ àti ní òdodo, tí a bá ti f’ara ba’lẹ̀, dáradára, a mọ́ ọ mọ ọmọ Yorùbá, yàtọ̀ sí ẹni tí kìí ṣe ọmọ Yorùbá, b’ó pẹ́, b’ó jin’nà, tí a bá ti ṣe ìwádi wa dáradára, láì fi igbá kan bọ̀ ‘kan nínú! Ṣùgbọ́n wàhálà tí ó wà ní’bẹ̀ ni wípé, àwa’ra’wa, Yorùbá, ní ọ̀pọ̀l’ọpọ̀ ìgbà, ni ó jẹ́ wípé, àwa náà ni a máa máa ṣe aláàbò fún irọ́ pípa irúfẹ́ àwọn bẹ́ẹ̀!

Àwa náà ni “ojú-àánú” wa kò ní gbà wípé k’á ṣe òótọ́ sí ìran Yorùbá, nínú ọ̀rọ̀ yí! Àwa náa ni a máa ran Chinedu l’ọwọ́, tí a máa ran Chukwuemeka l’ọwọ́, l’ati bá wọn purọ́ wípé ọmọ Yorùbá ni wọ́n, tí a sì mọ̀ wípé wọn kìí ṣe ọmọ Yorùbá! L’oótọ́, bàbá Chinedu, ó ti wà ní ọmọ ọdún méjìlá ní’gbà tí òun fún’ra rẹ̀ ti dé ilẹ̀ Yorùbá; òun pàápàá ni ó tún máa nkọ́ àwọn ọmọ ti’wa tí wọ́n jẹ́ ojú’gbà rẹ̀, ní àwọn ÒWE àti àṣà ilẹ̀ Yorùbá, nít’orí tí ó ti f’ara ba’lẹ̀, tí ó sì ti mọ èdè wa àti àṣà wa ju àwa elédè àti àwa aláṣà fún’ra wa lọ!

Ṣùgbọn, èyí kò sọ Chinedú tàbí bàbá rẹ̀ di ọmọ Yorùbá o! Ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, ẹ jọ̀wọ́, ẹ jẹ́ kí eléyi kí ó yé wa dáradára o! L’oótọ́, èdè ìran ni a fi ndá orílẹ̀-èdè ìran náà mọ̀, ṣùgbọ́n èyí kò wá tú’mọ̀ sí wípé ẹni tí ó bá ti wá gbọ́ èdè wa, tí ó si f’ara mọ́ àṣa àti ìṣe wa, típẹ́típẹ́, wípé ẹni náà ti wá jẹ́ ìkan náà pẹ̀lú wa, Rárá o!

Democratic republic of the Yorùbá

Àwa Yorùbá máa ndá àṣàk’aṣà kan, wípé, tí a bá ti rí àjèjì tí ó ti pẹ́pẹ́pẹ́ l’aárin wa, tí a sì tún wá ní ìfẹ́ rẹ̀, kí á máa sọ wípé, a ti di ara kan náà! Ìwà òmùgọ̀ pátápátá gbáà ni eléyi o!

Ẹ jẹ́ kí ojú wa kí ó le, ní àkókò yí, kí òfin wa sì mú’lẹ̀ dúró, dáradára, tí kìí bá íṣe Yorùbá, ìbáà máa jẹ́ orúkọ Yorùbá, ìyá rẹ̀ pàápàá ìbáà jẹ́ Yorùbá, kìí ṣe Yorùbá o!

Gbogbo ọmọ gidi, l’oótọ́, ọmọ Yorùbá, tí ó bá tí pa’rọ́, tàbí tí ó ṣe ẹlẹ́ri irọ́ wípé ẹni tí kìí ṣe Yorùbá, nít’òótọ́, tí wọ́n nj’ẹrí irọ́ pé Yorùbá ni ẹni náà, tàbí tí wọ́n DÁKẸ́ ní’gbàtí ẹni náà pe’ra rẹ̀ ní Yorùbá, tí ọmọ Yorùbá tí ó mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yí mọ̀ wípé ẹni yẹn, tàbí àwọn yẹn kìí ṣe ọmọ Yorùbá nínú ẹ̀jẹ̀ abínibí wọn, irúfẹ́ ọmọ Yorùbá tí ó DÁKẸ́ bẹ́ẹ̀, ti ṣẹ̀ sí ìran Yorùbá o!

Gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀tẹ’lẹ̀múyẹ́ wa tí ó lọ ṣe ìwádi fínnífínní ní abẹ́’lẹ̀ ní’lú Èkó ṣe sọ, wọ́n ti’lẹ̀ tùn sọ wípé ìlú Èkó ti bàjẹ́ gidi gan! Wọ́n fún wa ní àbọ̀ wípé bíbàjẹ́ tí Èkó ti bàjẹ́, nísiìyí, ó ti wá kọjá ohun tí ènìyàn lè fi ẹnu sọ rárárárà!

Ní ibi kan tí a mọ̀ sí “Kọ́lá” ní Àgbàdo-Ìjàyè, wọ́n fi tó wa l’etí wípé, àwọn ọmọ Yorùbá tí ó wà ní’bẹ̀ kò ní ojúlówó iṣẹ kan, gidi, tí wọ́n nṣe!

ÈÈMỌ̀ NÍ'LẸ̀ YORÙBÁ!!! Ọ̀TẸ'LẸ̀MÚYẸ́ ILẸ̀ YORÙBÁ TI GBÉ ÈSÌ ÌWÁDI KAN JÁ'DE O!

Ní kí wọ́n máa tọrọ bárà, tàbí kí ó ti’lẹ̀ jẹ́ wípé, l’aàrín ṣọ́ọ̀bù ìta’jà bíi méje, kí mẹ́fà ṣe àwọn ọmọ Íbò; kí Yorùbá kan ṣoṣo t’ó wà l’aárín wọn má ti’lẹ̀ rí iṣẹ́ t’ó tó’ṣẹ́ gidi kan ṣe ní ṣọ́ọ̀bù tirẹ̀!

Èyí tí ó tún dùn’ni, ni wípé, kí ọmọ Yorùbá máa gbé ilé yíyálò fún ọmọ Íbò, bí ó ti’lẹ̀  jẹ́ wípé ó ti ní àdéhùn tẹ́’lẹ̀ pẹ̀lú ọmọ Yorùbá, tít’orí wípé ọmọ Íbò gbé owó t’ó pọ̀ wá!

Ọmọ Yorùbá kò mọ pàtàkì ilé àti ILẸ̀ fún Ìran oní’lẹ̀! Wọn ò mọ̀ wípé ilẹ̀ tí Olódùmarè bá ti dá mọ́ ìran kan, àwọn Ìran yẹn kò gbọ́dọ̀ gbée fún àjèjì, ní’wọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ wípé ọmọ ìbílẹ̀ ìran náà ní’lò irúfẹ́ ilẹ̀ tàbí ilé bẹ́ẹ̀!

A níl’ati bẹ̀rẹ̀ ìdánil’ẹkọ́, kíakía fún àwọn ènìyàn wa, wípé, láíláí, èèwọ̀ ni l’ati gbé ohun ilé fún ará ìta, bíó ti wù kí ó pẹ́ to, tí ará ìta náà ti wà l’aárín wa!

A ti gbé ìran wa lé àwọn ọmọ Íbò l’ọwọ́ – gẹ́gẹ́bí àbájá’de ìwádi tí àwọn ọ̀tẹ’lẹ̀múyẹ́ ilẹ̀ Yoùbá yí lọ ṣe! A ti gbé àwọn ohun ìṣẹ̀mbá’yé àwọn baba wá lé àwọn àjèjì l’ọwọ́!

Àwọn ọ̀tẹ’lẹ̀múyẹ́ ilẹ̀ Yorùbá, wọ́n ti j’abọ̀ padà, wípé, àwọn ohun ìbílẹ̀ wa, àti àwọn ohun ìṣẹ̀mbá’yé wa, tí a ti jẹ́ kí ìyàwó tàbí ọkọ wa, kí ó mọ̀, fínnífínní, tí ó sì jẹ́ wípé ìyàwó tàbí ọkọ yí kìí ṣe Yorùbá, ti já sí ọ̀pọ̀l’ọpọ̀ wàhálà fún wa o! A ti fi àṣírí ìran wa han àwọn àjèjì o! Háà! ọmọ Yorùbá! kí l’ó ṣe wá gan-an!

Tí ó sì jẹ́ wípé ohun tí Olódùmarè ti sọ fún àwọn babanlá wa ni’yí, wípé ká ṣọ́’ra fún ìsúnmọ́ àjèjì, dé’bi tí wọn ó ti mọ̀ wá dé’nú dé’ta! Háà! Yorùbá ti di kòròfooo! OLÓDÙMARÈ, gbà wá! Ẹ̀yin ọmọ Yorùbá, ẹ jẹ́ kí a mọ̀ wípé akókò náà nì’yí, l’ati ro’nú p’ìwàdà àwọn àìṣedéédé wa wọ̀nyí!

A ti’lẹ̀ rí ẹni tí ó sọ wípé òun kìí tún fi gbogbo ara ṣe ọmọ Íbò má, tìt’orí wípé, Yorùbá ní ọkọ òun, àti wípé gbogbo ohun agbára àti ohun àṣírí ìṣẹ̀mbá’yé ìdílé ọkọ òun jẹ́ ohun tí ẹnik’ẹni nínú ìdílé ọkọ náà kò léè fi rú òun l’ojú ráràrárá! L’ó báá tán o! Yorùbá ti rin’hòòhò fún àjèjì! A ti fi ohun inú ilé wa, gẹ́gẹ́bí Yorùbá, han Àjèjì!

Àwọn ọ̀tẹ’lẹ̀múyẹ́ wa ti’lẹ̀ sọ wípé àwọn rí ohun ìṣẹ̀mbá’yé tí ó jin’lẹ̀, tí ó jẹ́ ti Yorùbá, l’ọwọ́ ọmọ Íbò!

Ìbòsí ò! Ìlẹ̀kẹ̀ àwọn Ìyá Ọ̀ṣun, inkan ìjìn’lẹ̀ ìṣẹmbá’yé Yorùbá, a ri l’ọwọ́ ọmọ Íbò! Ẹ jọ̀wọ́, ìgbà wo ni wọn ò ní rí’wa fín? Ìgbà wo ni wọn ò ní sọ wípé àwọn ni ọ̀gá wa, l’orí ilẹ̀ wa?

A wá gbọ́ l’ati ẹnu àwọn ọ̀tẹ’lẹ̀múyẹ́ wa, wípé, kìkìdá ọmọ àti Ìran Íbò ni wọ́n njẹgàga lé orí ibi tí wọn ti lọ ṣe ìwádi abẹ́’lẹ̀ yí, ní ìlú Èkó!

Bẹ́ẹ̀ náà ní àbọ̀ tí àwọn ọ̀tẹ’lẹ̀múyẹ́ ilẹ̀ Yorùbá yí, wá fún àwọn olùda’rí ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, fi hàn wípé àwọn ọmọge Yorùbá tí ó wà ní ibi tí wọ́n ti ṣe ìwádi yí, kìkìdá kí wọ́n ṣ’iṣẹ́ aṣẹ́wó ni wọ́n kàn nṣe!

Ìwádi àwọn ọ̀tẹ’lẹ̀múyẹ́ ilẹ̀ Yorùbá fi hàn, gbangba wípé, kí á la ojú wa dáradára o! nít’orí wípé àwọn tí wọn ò kì nṣe ọmọ Yorùbá ti  npe ara wọn ní Yorùbá o! Wọ́n rò wípé, ní’gbàtí àwọn ti ní ọkọ Yorùbá, tí àwọn ti bí ọmọ fún Yorùbá, ìyẹn ti wá jẹ́ kí àwọn náà ó ní ẹ̀tọ́ sí ohunk’ohun tí ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá bá ní ẹ̀tọ́ sí!

Ọmọ Yorùbá, àwa ni kiní yí kòì tíì yé o! ó ti yé àwọn àt’ọ̀húnrèwá tí wọ́n wà l’aárín wa, tipẹ́tipẹ́, wọ́n sì ti ní ìṣ’èto, l’ọwọ́l’ọwọ́, wípé, ohun tí ó bá máa gbà ni àwọn máa fun o! – wípé, kò sí ẹni tí ó lè bá àwọn sọ́ o, wípé àwọn kìí ṣe Yorùbá!

Bẹ́ẹ̀ ni ìwádi tí àwọn ọ̀tẹ’lẹ̀múyẹ́ wa ṣe, fi hàn gbangba wípé àwọn Íbò, àwọn àjèjì, pọ̀ rẹpẹtẹ nínú àwọn tí ó ngb’owó ìta ní ilẹ̀ wa!

A gbọ́ wípé, ní Terminal ní Oṣòdì, l’orí ilẹ̀ Babanlá wa, wọ́n á tún gba àyè kúrò l’ọwọ́ ọmọ Yorùbá, wọ́n á gbé àyè náà fún àjèjì, ọmọ Íbò!

Yorùbá, ẹ jẹ́ kí á fu’ra, kí á dẹ̀ gbé ìgbésẹ̀! Ṣé síso’wápọ̀ tí wọ́n so wá pọ̀ ní ìlú amúnisìn, Nàìjíríà, ní’jọsí, kí a tó kúrò ní’bẹ̀, ni kò jẹ́ kí làákàyè wá sọ mọ́ ni?

Tàbí iṣẹ́ ìta’nis’ẹrú tí àwọn ọ̀jẹ̀’lú nàìjíríà ti tà wá fún ìjọba Fúlàní, tí wọ́n npè ní Nàìjíríà, ṣé ìyẹn l’ó ti dà wá l’orí rú dé’bi kí á má mọ ILẸ̀ YORÙBÁ ní ilẹ̀ Yorùbá, tàbí kí a má mọ ọmọ Yorùbá ní ọmọ Yorùbá, tàbí kí a má mọ àjèjì ní àjèjí? Gbogbo ẹni tí ẹ̀jẹ̀ wọ́n, láìl’abàwọ́n, kìí ṣe ẹ̀jẹ̀ ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, ní orí ilẹ̀ Yorùbá, ẹ jọ̀wọ́, wọn ò ní orúkọ méjì o! -ÀJÈJÌ ni wọ́n o! Eléyi kò ní àyípadà rárárárá, òfin ẹ̀mí ni. Tí kìí bá nṣe Yorùbá, kì nṣe Yorùbá.

Mo bí’mọ fún Yorùbá kọ́ l’ansọ yí o! Mo fẹ́ ọkọ Yorùbá kọ́ l’ansọ yí o! Yorùbá ni’yá mi kọ́ l’ansọ yí o! Ilẹ̀ Yorùbá ni wọ́n bí mi sí, kọ́ l’a nsọ yí o! Èdè kan ṣoṣo tí mo gbọ́ ní ayé mi, èdè Yorùbá ni; ìyẹn kọ́ l’ansọ o! Orúkọ gbogbo tí mo njẹ́, orúkọ Yorùbá ni – ìyẹn kọ́ l’ansọ o!

Àbọ̀ tí àwọn ọ̀tẹ’lẹ̀múyẹ́ ilẹ̀ Yorùbá, mú padà, tún fi hàn wípé ní agbègbè Ìyànà-Ìpájà, olè elétò (organized Crime) ni àwọn ọ̀dọ́ Yorùbá nhù ní’bẹ̀!

Ọmọ Yorùbá, ta l’ó sọ yín di eléyi? Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n nṣe ní Kọ́lá, bẹ́ẹ̀ náà ni ní Cásò; a sì gbọ́ wípé, tí ìjà bá ṣẹ’lẹ̀ l’aárin wọn, nṣe ni àwọn ọmọ Yorùbá yí máa npa ara wọn bí ẹni np’ẹran!

A gbọ́ wípé iṣẹ́ olóṣó ni ọ̀pọ̀ àwọn ọmọge Yorùbá fi njẹun, tí wọn ò rí’kan ṣe’kan l’orí ilẹ̀ Baba wọn!

O burú dé’bi wípé, àwọn ọ̀tẹ’lẹ̀múyẹ́ wa sọ wípé, àwọn ọmọge Yorùbá wọ̀nyí kò ti’lẹ̀ fi bò; wọ́n ti ní oríṣiríṣi gbólóhùn tí wọ́n fi nbéèrè l’ọwọ́ ọkùnrin irúfẹ́ nkan tí ó bá fẹ́ fi wọ́n ṣe: oríṣiríṣi ọ̀rọ̀ tí ó ba ‘ni l’ọkan jẹ́ ni wọ́n máa nlò l’ati béèrè l’ọwọ́ ọkùnrin bóyá “ọ̀rẹ́ t’ó l’arinrin” ni ó nfẹ́ àwọn fún, tàbí “sáréwá” (ohun tí òbí kò lè dun’nú wípé kí ó já’de l’ẹnu ọmọ òun, tí sísọ rẹ̀ l’orí ahọ́n pàápàá mú kí ọmọlúàbí ó sún’ra kì); ìwọ̀nyí tún yàtọ̀ sí wípé kí wọ́n máa béèrè bóyá o ti ní ìyàwó, tí o kò dẹ̀ fẹ́ fẹ́ àwọn náà sí’lé gẹ́gẹ́bí ìyáwó bákannáà, ṣùgbọ́n l’ẹyin odi!

Nígbà wo ni ọmọ aladé di ẹni tí kò ní’ṣẹ́ dání, bóyá ó dẹ̀ tún ti pàdánù àwọn òbí méjèèjì, tí ó fi wá di wípé kí ọmọ ìran Yorùbá máa fi ara rẹ̀ fún àrífín l’ọdọ̀ ọkùnrin kí ó tó lè rí ọwọ́ mú lọ sí ẹnu!

Dé’bi tí ó jẹ́ wípé ìtìjú kò ti’lẹ̀ wá sí ní’bẹ̀ má, bí ẹni t’ó ns’ọ̀rọ̀ iṣẹ́ gidi kan l’ẹnu ní’gbàtí wọ́n bá nròyìn ohun tí ọkùnrin alẹ́ àná fi àwọn ṣe!

Gbogbo ọmọ Yorùbá, pàápàá àwọn tí ó wà ní òkè okun; ẹ gbọ́ o! ilẹ̀ ti kún o! fún ìwà ibi, ìwà aláìní’rònú, ìwà ìkà, ní ilẹ̀ Yorùbá! Bẹ́ẹ̀ náà ni a jẹ́ ẹrú fún àwọn àjèjì l’orí ilẹ̀ wa; tí ó sì tún jẹ́ wípé ọmọ Yorùbá bíi ti’wa l’ó máa gba nkan l’ọwọ́ wa, t’á dẹ̀ mú ohun ọ̀ún fún àjèjì, l’orí ilẹ̀ Baba wa! HÁÀÀ!