Èèmọ̀! A rí fidíò kan l’orí ìkànnì @Nwaadaz ní orí X (èyí tí a mọ̀ tẹ́’lẹ̀ sí Twitter), ní’bi tí àwọn ọmọ wa, àwọn ọmọ ol’ogo, àwọn ọmọ al’adé, àwọn géndé ọ̀dọ́ Yorùbá ti mbẹ àwọn ènìyàn tí wọ́n nkọjá lọ nínú mọ́tò ti wọn, wípé kí àwọn tí ó nkọjá lọ wọ̀nyí, kí wọ́n jọ̀wọ́ dákùn fún wọn ní owó kí àwọn lè fi jẹun!

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X
Democratic republic of the Yoruba ominira new update | Yoruba Nation | Newest Nation in Africa, World

Nkan yí gba omijé l’ojú ọmọ èèyàn; ní pàtàkì, tí o bá jẹ́ ọmọ Yorùbá!

Ó ṣe’ni l’aánú wípé báyi l’ó ti wá dà, fún ìran ọmọ Al’adé! Yorùbá tí gbogbo àgbáyé nwò l’okèl’okè tẹ́’lẹ̀, ti wá di ẹni tí ó ntọrọ jẹ l’orí ilẹ̀ baba rẹ̀!

Ká Ìròyìn: Ìkà Á Pa Oní’kà

Ẹ̀bi wọn kọ́, ẹ̀bi àwọn wèrè tí ó pe’ra wọn ní ọba àti olórí ní ilẹ̀ Yorùbá ni! Tí wọ́n la ojú la imú wọn sí’lẹ̀ tí ìran Yorùbá wá di o ní báárà!

L’aìpẹ́, l’aìjìnà, báyi, l’agbára Olódùmarè, gbogbo ìwọ̀nyí á di òpìn, ní’gbàtí ìjọba wa bá ti wọ’nú ilé-iṣẹ́ ìjọba (Secretariat) wa, káàkiri gbogbo ilẹ̀ Yorùbá!

Àwọn òpònú tí wọ́n pe’ra wọn ní gómìna, èyíinì, gómìnà nàìjíríyà, máa tó fi ìtìjú kúrò ní’bẹ̀, l’aìpẹ́, l’aìjìnnà; ní’gbà náà ni gbogbo ayé máa tó rí ògo ọmọ Yorùbá!

Ká Ìròyìn: Àwọn Ìkà Èèyàn Fẹ́ Pààrọ̀ Ẹran Dáradára Pẹ̀lú Ẹran Ayédèrú

Fún àwọn tí ó ṣe eléyi fún ìran Yorùbá, ẹ ò ní mu’jẹ o! Ẹ ti ṣẹ̀ sí’bi tí ènìyàn kò gbọdọ̀ ṣẹ̀ sí!

Democratic republic of the Yoruba ominira new update | Yoruba Nation | Newest Nation in Africa, World