Igbá-kejì ààrẹ wọn ní’lú agbésùnmọ̀mí nàìjíríà sọ pé ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ náírà tí tó láti tán ìṣòro ọ̀dọ́ tí ó bá mọ ohun tí ó nṣe!
Ẹ jọ̀ọ́, ẹ bá wa bérè lọ́wọ́ ẹ̀, tí ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ náírà bá ti lè tán ìṣòro ọmọ ti ẹ̀!
Aláwàdà, gbáà, ni àwọn ìlú òṣì, nàìjíríà, yí!
Àkọ́kọ́, ṣebí ìdílé kan ni wọ́n sọ pé àwọn fẹ́ fún ní ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ náírà ọ̀ún? Ó ti wá di ọ̀dọ́ kan báyi, àbí? Ó dáa, ó ti yé wa – ọ̀dọ́ kan, pẹ̀lú ìyàwó àti àwọn ọmọ ẹ̀, ìlú yín, nàìjíríà, fẹ́ máa fún yín ní ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ náírà ní oṣooṣù! Ẹ ẹ̀ ri pé ẹ ti ṣorí ire gan ni!
Ẹ kú ọ̀fọ̀ o, ẹ sì kú òfò, ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ owó náíra, fún gbogbo ìdílé kan, lóṣù kan, fún osù mẹ́fà, à bẹ́ẹ̀ ri, owó ti dé nìyẹn; àá wẹ̀ẹ́ o! Ẹ kú orí-ire o!
Ìlú àdánù, ìlú òfò, Káì! Àwọn ẹranko wọ̀nyí, wọ́n dájú!
Ọmọ Ibílẹ̀ Yorùbá, ẹ jọ̀wọ́, ibi tí a nlọ ni kí àwa ó dojú kọ ní tiwa o!
Kí Olódùmarè kí ó bukún Ìránṣẹ́ Rẹ̀, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, kí Ó dáàbò bò wọ́n, tọ̀sán tòru, kí Ó si mú gbogbo ìfẹ́ Rẹ̀ ṣẹ lórí Màmá wa, àti lórí gbogbo àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, lórí Democratic Republic of the Yoruba.
Ẹ jọ̀wọ́, gbogbo I.Y.P tí a nílò Ilẹ̀, tí a dẹ̀ tí pé ọmọ ọdún mọ́kànlélógún sókè, ṣé a ti nronú irúfẹ́ ilé tí a fẹ́ kọ́ o? torí ọ̀fẹ́ ni Ilẹ̀, aò nílò ìrònú lórí ti ilẹ̀; D.R.Y ti ṣètò ilẹ̀ fún wa, lọ́fẹ – ẹ̀tọ́ wa ni o, gẹ́gẹ́bí I.Y.P.
Ilé-iṣẹ́ ayélujára wa nkọ́? Ṣé a ti gbéra láti forúkọ̀ sílẹ̀: ìyẹn kìí ṣe fún ti ilẹ̀ o, fún ti gbogbogbò ìforúkọ sílẹ̀ ni o! – ó yá, ẹ jẹ́ ká lọ www.democraticrepublicoftheyoruba.com , àkókò ìforúkọ sílẹ̀ rèé.
Ká Ìròyìn Síwájú sí:
- ỌMỌ YORÙBÁ TÍ ÌYÀ NJẸ, FI LÀÁKÀYÈ HÀN NÍ BÍ ÒUN ṢE LÈ ṢE ÒWÒ, TÍ Ẹ̀YÁWÓ BÁ WÀ FÚN ÒUN
- Ọ̀NÀ MÍRÀN TÍ ÀWỌN ALÁWỌ̀ FUNFUN TÚN FẸ̀ GBÀ LÁTI PA ÀWA ÁFRÍKÀ RUN
- ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN NJẸ CHINA LÓWÓ, NI CHINA BÁ GBA ỌKỌ̀ BÀLÚÙ NÀÌJÍRÍÀ! Òótọ́ tàbí Eré?
- ÈTÒ AMÚLUDÙN, NÍ TI ORIN KÍKỌ