Ákí bísọ́bù sọ wípé kí ìjọba àpapọ̀ ìlú Ajíríyà máa yọ ìdáméwàá kúrò nínú owó osù àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba kí wọn tó san ọwó oṣù.

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

Hmmmm. Orísìíríṣìí, ìyàwó elégún; bí a ṣe ń rí gígùn là ń rí kúkúrú; bí a ṣe ń rí tínrín là ń rí ọ̀rọ̀bọ̀; bí a ṣe ń rí gíga ni à ń rí kúkúrú, nítorípé ijó ni egún fi fẹ́  wọ́n.

Bẹ́ẹ̀ni ìjọba Ajíríyà ṣe ra ọ̀pọ̀lọ́pọ̀  ìránṣẹ́ ọlọ́run tí wọ́n wá di ìránsé àwọn ọ̀jẹ̀lú lokaṣan 419.

Ẹ jẹ́ kín rán yín létí ní ìgbà ìdìbò ọdún 2023 tí ó kọjá.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni bàbá abirùn, àrẹ lokaṣion 419 rán aṣọ bíṣọ́bù sí lọ́rùn tí wọ́n sì wọ̀ọ́ wá sí ibití wọ́n ti di ìbò.

Ṣé a rántí pé wọ́n rán aṣọ bíṣọ́bù sí ofarétẹ́dì lọ́rùn ní kotonú.

Àwọn tí wón fi owó rán ńkọ́? tí wọ́n ń bá àwọn ọ̀jẹ̀lú Ajíríyà kó owó lọ sí òkè òkun gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ́ láti inú ẹ̀rọ ayélujára.

Ṣe bí tí a bá ń pe ènìyàn ní abìfun raìraì, ṣé kò yẹ kíó pa ìfun rẹ̀ mọ́?

Ṣùgbọ́n bí ti àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ìlú Ajíríyà kọ́. ǹjẹ́ Ákí bísọ́bù kò ha ti fihàn wípé òtítọ́ ni  ọ̀rọ̀ náà, haaa, kí ló kan ìjọba Ajíríyà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìdámẹ́wàá? 

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí wọ́n pe ara wọn ní ìránṣé ọlọ́run ni ebíléndé, aláìríṣẹ́ṣe, a fi ọ̀rọ̀  ẹ̀taǹ gba owó lọ́wọ́ ènìyàn nípa ìríran tó ba ni lẹ́rù, àsọtẹ́lẹ̀ èké tó sọ ẹnití gbọ́ọ di aláìní ìfọ̀kànbalẹ̀, tí ó sì sá kíjokíjo lọ sí ọ̀dọ̀ wọn fún àbò níbi tí kòti sí àbò.

Òmìnira Yorùbá daily news democratic republic of the Yorùbá

Bísọ́bù kò lè ṣe aláìsọ bẹ́ẹ̀, owó ti gbẹ ní àpò àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀, lóṣe rárí wọ inú agbo àwọn ọ̀jẹ̀lú ìjọba lokasan 419 lọ. ǹ jẹ́ èyí kò wá jẹ́ ìtìjú fún Ákí Bísọ́bù, odidi Ákí Bísọ́bù, ló sọ èyí jáde sí ìgboro ayé. Òùn nìkan kọ́ o, wọ́n pọ̀ jáǹtìrẹrẹ ní ìlú Ajíríyà.

Nítorí ìdí èyí, ẹ jẹ́ kí àwa ọmọ IYP orílẹ̀ èdè olómìnira máa kíyèsára nítorí àwọn ẹlẹ́tàn bí èyí, níwọ̀n ba ọjọ́ péréte tí ó kù kí ìjọba Yorùbá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àkóso ní pẹrẹwu lórí ilẹ̀ olómìnira DRY.

Àwọn kẹ̀, níbo? Kò sáyè fún wọn ní ilẹ̀ abínibí Yorùbá IYP fún irú àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run ọ̀jẹ̀lú ìlú Ajíríyà, àwọn wọ̀bià, ọ̀dájú Ákí Bísọ́bù, àwọn ìran wòlíì Bálámù nínú Bíbélì. Ìṣiwèrè wọn ìlú ajíríyà náà ló máa mọ.