À fi kí Olódùmarè kí ó gbà wá o, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe ri nínú ìròyìn kan wípé, pásítọ̀ kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Matthew Ashimọlowo ni ó wípé, ẹnití kò bá fi owó rẹ̀ d’ókòwò ta’lẹ̀ t’alé sí ìlú Èkó ní ìsinsìnyí, irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóò kábàámọ̀ rẹ̀ ní ọdún bíi mẹ́wàá síbi tí a wà yí. 

Ìdí ni wípé òun kò faramọ́ ìdókòwò pẹ̀lú ilé ìfowópamọ́ látàrí bí òun ti ṣe pàdánù owó tí ó tó igba mílíọ̀nù owó Nàìjíríà nígbà tí òun d’ókòwò pẹ̀lú àwọn ilé ìfowópamọ́.

Pásítọ̀ náà ni ó wá ń gba àwọn ènìyàn níyànjú láti lọ máa d’ókòwò ta’lẹ̀-t’alé sí ìlú Èkó nítorí pé lẹ́yìn ọdún díẹ̀ wọn yóò ti rí èrè gọbọi.

Ọ̀rọ̀ yí jẹ́ èyí tí ó dun’ni, ní àsìkò tí a wà yí. Ẹni tí ó bá nífẹ Ashimọlówó kí ó sọ fun pé Ìlú Èkó tó mọ̀ tẹ́lẹ̀ ti yàtọ̀ o! Kí ó dẹ̀ rọra sọ̀rọ̀ ilẹ̀ títà ní Èkó lọ́wọ́ tí a wà yí, kí ó máṣe di ọ̀ràn dídá.

Ìdí tí a ní láti ṣe àlàyé fún ọkùnrin ọ̀ún ni pé, tí kò báì tíì mọ̀, kí ó mọ̀, báyi, pé, Èkó kò sí nínú Nàìjíríà mọ́, láti ogúnjọ́ oṣù bélú, ẹgbàá ọdún ó lé méjìlélógún, bẹ́ẹ̀ ni a ti ní ìjọba tiwa láti ọjọ́ kéjìlá, oṣù igbe, ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rinlélógún.

Democratic republic of the Yoruba ominira new update | Yoruba Nation | Newest Nation in Africa, Youngest country in the World 2024
Ìròyìn Òmìnira Olojoojumọ – Bèrè fún ẹ̀da títí rẹ!

Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ẹni tí ó bá ń ta’lé-ta’lẹ̀, tàbí tí ó ń ràá níbikíbi ní orílẹ̀-èdè D.R.Y, ńtàpá sí òfin wa ni ò! Nítorí èyí, kí pásítọ̀ Ashimọlówó ó ṣì dákẹ́ ná.

Ẹni tó bá nra ilẹ̀, tàbí ta ilẹ̀, nísiìyí tí agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà fi agídí dúró sórí ilẹ̀ Yorùbá, lábẹ́ ìjọba wo ló ti fẹ́ ṣe àdéhùn ìwé ilẹ̀ náà? Ìjọba D.R.Y ti fi yé wa pé ọ̀ràn-dídá ni báyi fún ẹnikẹ́ni láti ní àdéhùn pẹ̀lú Nàìjíríà lórí ilẹ̀ D.R.Y.

Kí oníkálùkù ó mú sùúrù kí á rẹ́hìn àwọn agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà, kí ìjọba wa, ìjọba D.R.Y, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nínú àwọn oríkò-ilé-iṣẹ́-ìjọba wa gbogbo ní Orílẹ̀-Èdè wa, D.R.Y, kí a wá gbọ́ òfin tí ó wà ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y) nípa ọ̀rọ̀ Ilẹ̀. Nítorí èyí, pásítọ̀ Ashimọlówó, ẹ ṣì fara balẹ̀ ná.

Ṣùgbọ́n ṣá, kí á ṣì sọ fún wa ná, pé, Ilẹ̀-Yorùbá, ti Ọmọ Yorùbá ni!

Ẹ jẹ́ kí á tún rán ara wa léti pé láti ọmọ-ọdún mọ́kanlélógún, àwa ọmọ-ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ní ẹ̀tọ́ sí Ilẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ìjọba Orílẹ̀-Èdè wa, D.R.Y, ọ̀fẹ́ sì ni, ṣùgbọ́n a ò lè ta ilẹ̀ náà fún ẹnikẹ́ni o!