Orílẹ̀-Èdè Burkíná Fasò ti pinu láti dá ilé-iṣẹ́ tí ó máa gbé agbára jáde láti inú hóró-àyíká, èyí tí wọ́n pè ní “àtomic energy,” látàrí kí wọ́n máṣe gbẹ́kẹ̀lé ará-ìta fún ohun àmúṣagbára, gẹ́gẹ́bí agbára iná mọ̀nọ̀mọ́nọ́, fún àpẹrẹ; àti fún ìdàgbàsókè ìlú wọn ní dídá ìlé-iṣẹ́ sílẹ̀, àtí kí gbogbo agbègbè ìlú wọn le ní iná mọ̀nọ̀mọ́nọ́ ní àrọ́wọ́tó.

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal

Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ti gbésẹ̀ kí ilé-iṣẹ́ ẹ̀kọ́ṣẹ́-ọwọ́ wọn ó le gbòòrò si, àti kí wọ́n le ní ọkọ̀ ojú-irin tí ó máa so gbogbo agbègbè ìlú wọn pọ̀.

Ní àfikún, wọ́n ti ṣètò ilé-ìwòsàn alárìn-kiri (mobile clinics) tí ó máa ṣe ètò ìwòsàn ọ̀fẹ́ fún àwọn èèyàn wọn. Wọ́n ṣe eléyi ní pàtàkì kí àwọn tí kò ní tó, ó màṣe jìyà àìní ìwòsàn tó péye látàrí àìní owó.

Àfi bí ẹni pé ẹni kan nfi apákan ojú nwo bí ó ṣe nlọ ní ìlú olórí-ire ni. Olórí-Ire ni Ilẹ̀ Yorùbá, a kí gbogbo ẹni tí ó bá ngbé ìgbésẹ̀ àti mú ayé dẹrùn fún ìlú tiwọn.

Ká Ìròyìn Síwájú sí: