L’atàrí ìròhìn tí ó já’de l’aná òde yí, wípé kò sí ọba ní ilẹ̀ Yorùbá, ẹni kan tí ó ṣì rò wípé ọba ni òun, ti kàn sí ojúlówó ọmọ Yorùbá, BLACK LION, o! Ẹni náà wá nsọ wipé ọmọ Yorùbá sọ wípé àwọn ò fẹ́ ọba ní ilẹ̀ Yorùbá.

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

BLACK LION wá da l’ohùn o! Ìròyìn tí ó tẹ̀ wá l’ọwọ́ sọ wípé BLACK LION ṣe àlaàyé fún ará’kùnrin náà wípé: Ẹ́ẹ̀ kìín ṣe obaà, ọmọ Yorùbá, tẹ́’lẹ̀ntẹ́lẹ́rí ti’lẹ̀ kọ́ l’ó yọ yín l’ọba! Nàìjíríà ti yọ ‘yín l’ọba tipẹ́ típẹ́! l’at’ayé gbọ́han!

BLACK LION wá fi ye wípé, ó ti lé l’ọgọ́ta ọdún nísiìyí, tí kò ti sí nkan t’ó njẹ́ ọba, kankan, ní ibi tí wọ́n npè ní Nàìjíríà! Kí Yorùbá ó tó já’de kúrò ní ìlú Nàìjíríà ni kò ti sí ọba mọ́!

Nàìjíríà ti yọ gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ́ ọba ní’gbà náà, l’ọhún, Nàìjíríà ti yọ wọ́n, Nàìjíríà ti yọ yín kúrò, kò sì sí nkan t’ó njẹ́ ọba mọ́, l’ati ọdún 1963! Ọdún 1963, tí Nàìjíríà sọ wípé àwọn ò ṣe Nàìjíríà mọ́, ‘pé ‘Republic of Nigeria’ l’àwọn; l’ati ijọ́ náà l’ọhún ni kò ti sí ọba mọ́ọ! BLACK LION wá sọ fun wípé, ṣé wọn ò mọ ìtúmọ̀ republic ni?

Ibik’ibi tí wọ́n bá ti pè ní ‘Republic,’ kò tún lè si nkan tí wọ́n npè ní ọba ní’bẹ̀! BLACK LION wá sọ fun wípé, Naìjíríà kàn nlò wọ́n l’ati fi orí àwọn ènìyàn s’abẹ́ niì; kò sí ọba mọ́ l’ati 1963!

Gbogbo àgbáyé l’ó gbọ́, ní’gbà náà l’ọhún, ní 1963, ọdún mẹ́ta l’ẹhìn tí Nàìjíríà ti gba òmìnira, kúrò l’ọwọ́ Britain (bí ó ti’lẹ̀ jẹ́ wípé, òmìnira irọ́ náà ni); gbogbo àgbáyé l’o gbọ́ ní’gbànáà l’ọhún wípé Nàìjíríà kò sí l’abẹ́ ọba kankan mọ́ (wọn o ti’lẹ̀ sí l’abẹ́ ọba gẹ̀ẹ́sì pàápàá mọ́), ṣùgbọ́n wípé wọ́n ti di ‘Republic;’ ìtú’mọ̀ republic ni “Ìlú Tí Kò S’ọba” tí ó jẹ́ wípé àwọn ará ìlú fún’ra wọn ni wọ́n nṣe àkóso ara wọn, tì wọn ò sí l’abẹ́ ọba kankan!

BLACK LION F'ÈSÌ FÚN ẸNI T'Ó PE'RA RẸ̀ L'ỌBA O!

Ṣebi àìmọ̀’kan’mọ̀kàn l’ó nṣe àwọn tí wọ́n rò wípé àwọn jẹ́ ọba wọ̀nyí – wọn ò mọ ìtàn! Ní’gbàtí àwọn Britain (Gẹ̀ẹ́sì) sọ wípé àwọn fún Nàìjíríà ní òmìnira ní’gbà yẹn, ọba ìlú òyìnbó (Queen Elizabeth) tí ó kú ní ìgbà díẹ̀ s’ẹhìn yí, ṣì ni Ọba l’orí gbogbo Nàìjíríà, ní’gbà náà, bí ó ti’lẹ̀ jẹ́ wípé, wọ́n sọ wípé àwọn ti fún Nàìjíríà ní òmìnira!

Ìdí n’yẹ̀n tí ó fi jẹ́ wípé, l’ẹyìn òmìnira yẹn, ní ọjọ́ kíní oṣù kẹwá ọdún 1960 (October 1st, 1960); l’ẹhìn ijọ́ yẹn, àworán Ọba’bìnrin Elizabeth yí l’ó ṣì pàpà wà l’orí owó bébà (currency note) Nàìjíríà, àwòrán rẹ̀ náà l’ó ṣì pàpà wà l’ara àwọn owó idẹ (coins) tí Nàìjíríà nná (àwọn bíi kọ́bọ̀ [1 penny], sísì [six pence], ṣílè kan [one shilling], àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ) ní’gbà yẹn; nít’orí wípé òun náà ṣì ni ọba l’orí gbogbo Nàìjíríà ní’gbà náà, bí ó ti’lẹ̀ jẹ́ wípé Nàìjíríà ti gba òmìnira! Ìdí n’ìyẹn tí ó fi jẹ́ wípé “Governor-General” ni wọ́n npe Azikiwe ní’gbà náà, tí Tafawa Balewa sì jẹ́ olórí ìjọba (Prime Minister). Gbogbo wọn wà l’abẹ́ Elizabeth tí ó jẹ́ Ọba l’orí gbogbo Nàìjíríà.

Ìdí n’ìyẹn tí wọ́n fi npe England àti gbogbo Britain ní ÌLÚ ỌBA ní’gbà náà (tí àwọn kan ṣì npèé títí di òní yí, tí wọn kò mọ̀); nít’orí wípé ẹnik’ẹni tí ó bá jẹ́ ọba ìlú England ní’gbà yẹn náà ni ọba l’orí gbogbo Nàìjíríà àtí l’orí àwọn ọba tí ó wà nínú Nàìjíríà bákannáà.

Bí ó ṣe wà n’ìyẹn l’ati October 1, 1960, tí Nàìjíríà ti gba òmìnira, títí di October 1, 1963! (ọdún mẹ́ta gbáko!) Ní’gbà yẹn, ọba ṣì wà, bí ó ti’lẹ̀ jẹ́ wípé, abẹ́ ọba Gẹ̀ẹ́sì, Queen Elizabeth náà ni gbogbo àwọn ọba Yorùbá àti irufẹ́ wọn káàkiri Nàìjíríà, abẹ́ ọba Gẹ̀ẹ́sì yí ni wọ́n wà.

Ṣùgbọ́n ní October 1, 1963, ni Nàìjíríà yí ètò ìṣè’jọba wọn padà, tí wọ́n sọ wípé Nàìjíríà kò sí l’abẹ́ ọba kankan mọ́ – àti ọba Gẹ̀ẹ́sì ni o, àti ọbak’ọba tí ó wù k’ó jẹ́; wọ́n wa sọ wípé “Republic” ni àwọn l’ati October 1, 1963 yẹn! Ijọ́ yẹn ni wọ́n lé ọba ìlú Gẹ̀ẹ́sì (nít’orí, lí lé l’ó já sí), tí kò jẹ́ Ọba l’orí Nàìjíríà mọ́; tí àwọn ọba tí ó wà ní ilẹ̀ Yorùbá, náà, kò ní agbára kankan mọ́, tí kò sì sí nkan t’ó njẹ́ ọba mọ́! nít’orí Nàìjíríà sọ wípé àwọn ò fẹ́ Monarchy mọ́ (èyíinì, wọn ò fẹ́ ọba mọ́), wípé Republic ni wọ́n yàn l’ati jẹ́ nísíìyí (eyíinì, Ìlú tí kò s’ọba). Ìtú’mọ̀ Republic, nìyẹn. Wọ́n sì polongo eléyi fún gbogbo àgbáyé ní’gbà náà! L’ati ìgbà yẹn ni gbogbo ayé ti mọ Nàìjíríà gẹ́gẹ́bí Republic – Ìlú tí kò l’ọba.

Ìgbà náà ni wọn ò pe Azikiwe ní “Governor-General” mọ́, tí wọ́n wá npèé ní President, tí Tafawa Balewa sì nṣe Prime Minister lọ (olórí-ìjọba). Nít’orí wípé “president” ni Republic máa nní, kìí ṣe ọba. Ibi tí ó bá dẹ̀ ti jẹ́ Republic, kìí sí ọba ní’bẹ̀.

Bí Nàìjíríà ṣe yọ ‘yín kúrò l’ọba n’ìyẹn, tí wọ́n dẹ̀ fa’gi lé ipò ọba pátápátá ní Nàìjíríà. L’orí òfin ni wọ́n dẹ̀ ti ṣé (èyíinì, Constitutionally), ní’torí, àwọn ìgbìmọ̀ ìṣe’jọba (Parliament) l’ó ṣeé, tí ó wá di òfin l’ati ijọ́ náà l’ọhún. Bí ọba Gẹ̀ẹ́sì, ṣe di ohun àti’jọ́ nìyẹn, ní Nàìjíríà, tí kò sí tún sí ọba kankan mọ́, ní ilẹ̀ Yorùbá, nítorí wípé, nínú Republic, kò sí àyè fún ọba! – àgàgà jùlọ, Federal Republic.

Ọdún 1979 ni Nàìjíríà wá kúkú fi èdìdí sí gbogbo rẹ̀, tí wọn ò ti’lẹ̀ wá lo ipò “Prime Minister,” mọ́; tí ó jẹ́ wípé “President” nìkan ni wọ́n wá ní, tí ó sì jẹ́ “Executive President” (ẹni tí kò gba àṣẹ l’ọwọ́ ọba, kò sí ọba kankan ní’bẹ̀).

Wọ́n tún wá ṣeé wipé “Federal Republic” tún wá ni! Kò sí nkan t’ó njẹ́ ọba mọ́! Nàìjíríà l’ó yọ yín, kìí ti’lẹ̀ ṣe ọmọ Yorùbá! Ṣùgbọ́n ẹ ò mọ̀ọ! Kíl’ẹ mọ̀! BLACK LION ṣe àlàyé wọ̀nyí fún ọkùnrin náà!

Nàìjíríà ti fa’gi lé ọba l’ati 1963! Àìmọ̀’kanmọ̀’kàn yín ṣì njẹ́ kí ẹ máa rò wípé ọba ni ‘yín! Ẹ̀rín pa wá gidi gan-an o, l’orí ọ̀rọ̀ yín! Wọn kòì tíì bí ẹlòmíràn pàápàá nínú yín, ní 1963 tí wọ́n ti fa’gi lé ọba! Ẹ dẹ̀ npe’ra yín l’ọba! Káì! Ẹ̀rín yín pa wá gan o!

Ṣé ọba máa ndọ̀bálẹ̀ fún ẹnik’ẹni ni! Ìránṣẹ́ olóṣèlú ni yín! Wọn ò sọ fún yín wípé kò sí nkan t’ó njẹ́ ọba nínú Republic!

Wọ́n gbé yín gun ẹṣin ẹlẹ́dẹ̀, wọ́n nf’ẹnu pè yín l’ọba, wọ́n dẹ̀ mọ̀ wípé kò sí ọba nínú republic! Ṣé ẹ rí “ọba” nínú Constitution Nàìjíríà ni? ẹ̀yin òpo’nú! Wọ́n nlò yín l’ati fi kó wa l’ẹrú! àmọ́ ṣá, ojú wa ti là! Nàìjíríà l’ó yọ yín, tí ò sí nkan t’ó njẹ́ ọba mọ́! Àwa náà ò dẹ̀ fẹ́’yín!

O pe’ra ẹ l’ọba, o ndọ̀bálẹ̀ f’olóṣè’lú! Kò yẹ k’ó ti mọ̀ ‘pé wọ́n ntàn ẹ́ ni, wípé oò kìn ṣe ọba! Ol’oṣe’lú l’ó fi ẹ́ sí’bẹ̀, k’o le rò wípé o já mọ́ nkan! Àwọn t’ó já mọ́ nkan wà nínú Constitution wọn, ìwọ ò sí n’bẹ̀!

Ol’oṣe’lú l’ó nsan’wó oṣù fún yín! Ṣé ọba n’ìyẹn? Ẹ nkúnlẹ̀ f’olóse’lú, ṣé ọba nìyẹn tàbí ìrán’ṣẹ́ ol’oṣe’lú? Ol’oṣe’lú l’ó nfi yín sí’pò, t’ó ngbé ọ̀pá àṣẹ irọ́ lé ‘yín l’ọwọ́! Ṣé ọba n’ìyẹn tàbí ìránṣẹ́ ol’oṣe’lú!? Ẹ yá’a wá nkan míì pe’ra yín! Kò ti’ẹ̀ wá sí nkan t’ó njẹ́ ọba ní Democratic Republic of the Yorùbá (D.R.Y), l’ó bá tán!

Ẹ npe’ra yín l’ọba, ẹni kan nṣe “Stand up, sit down” fún yín, ẹ̀yin náà ndìde, ẹ njóko! Ojú ò tì yín!? Ṣé ẹnik’ẹni máa np’àṣẹ f’ọba ni? Eèé! ẹ mà npa’yàn l’ẹrín gan o! 

Tí ó bá jẹ́ wípé ọba ni yín, l’oótọ́ – BLACK LION tún sọ fún ará’kùnrin náà, wípé, l’ayé àtijọ́, nígbàtí ọba wà, tí ó bá jẹ́ ‘pé ọba ni ‘yín, l’oótọ́, ṣé ìlú á ti burú tó bái, kí ọba ó tó ṣ’ọkùnrin, t’á ti pa’ra ẹ̀? Ẹ jọ̀ọ́, l’ayé, ẹ má jẹ́ á tún gbọ l’ẹnu yín, ‘pé, ẹ npe’ra yín l’ọba! Ṣé ẹ ò tiẹ̀ l’ojútì ni!