Ìròhìn tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́ lórí ẹ̀rọ Ayélujára, ni oníròhìn, Tucker Carlson, ti Ilé-Isẹ́-Ìròhìn FOX NEWS ti sọ pé, Ìrànṣẹ́-Àṣìtáánì, Bill Gates, kò ka ara rẹ̀ sí ènìyàn o! Nṣe ló ka ara rẹ̀ sí Ẹlẹ́da, àti pé àkóso àgbáyé yí wà lọ́wọ́ òun.
Ṣé ìdí tí a fi nsọ eléyi fún wa ni, kí a lè mọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe lágbára tó, pé àwọn tó rán Bill Gates ní’ṣẹ́ ibi tó njẹ́ kiri wọ̀nyí, àwọn gan-an ni wọ́n rò pé kò sí báwọn ò ṣe jẹ́, tí eléyi kò sì rí bẹ́ẹ̀ rárá, àti kí á le mọ̀ pé àwọn ẹni ibi wọ̀nyí kò bá t’eré wá; wọ́n fẹ́ ṣe ayé yí yàtọ̀ sí bí Olódùmarè ti fẹ́ ni.
Àṣìtáánì ni wọ́n nṣiṣẹ́ fún, ṣùgbọ́n pẹ̀lú dídìde tí Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.RY) dìde ní àkókò yí, àti títí láí, kò sí ète ibi wọn tí ó máa ṣẹlẹ̀ lórí Ìran Yorùbá.
Ìwà asínwín tí a tún gbọ́ pé ó bà lé Bill Gates ọ̀ún nísiìyí, ni pé, ó fẹ́ wá bí wọ́n ṣe máa darí ìmọ́lẹ̀ oòrùn sí ibòmíràn, kí ayé yí lè tutù síi.
Àlùwàlá ológbò rẹ̀, ọgbọ́n àti kúkú kẹ́ran jẹ ni. Ó pẹ́ tí wọ́n ti nwá bí wọ́n ṣe máa gba ilẹ̀ aláwọ̀dúdú, ṣùgbọ́n tí Olódùmarè kò ní fún wọn ṣe láíláí (pẹ̀lú ṣíṣiṣẹ́ tọ̀ọ́ láti ọ̀dọ̀ wa ni o, kìí ṣe ká káwọ́ gbera, kí á sọ pé Ọlọ́run ò ní fún wọn ṣe).
Ká Ìròyìn Síwájú sí: ÀWỌN “ALÁGBAYÉ” FẸ́ GBA AYÉ !
Bóyá torí kí ilẹ̀ Áfríkà ó máṣe móoru jù fún àwọn wèrè amúnisìn òyìnbó ọ̀ún ni ọlọ́pọlọ-dídàrú Bill Gates ọ̀ún ṣe ndába àti darí agbára óòrùn síbi míì, ṣùgbọ́n a fi tó’wa létí ni, kí á le mọ bí ọ̀rọ̀ ṣe nlọ ní àgbáyé yí.
Jíjáde tí Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá ti jáde kúrò nínú ìlú-ibi, Nàìjíríà, láti ogúnjọ́ oṣù bélú, ẹgbàá ọdún ó lé méjìlélógún, tí a dẹ̀ ti gbé Ìjọba wa wọlé láti ọjọ́ kéjìlá, oṣù igbe, ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rin-lé-lógún, jẹ́ ìgbésẹ̀ pàtàkì tí Olódùmarè nlò láti ri pé Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) àti orílẹ̀-èdè wa, D.R.Y, kò sí fún àwọn wèrè aláwọ̀-funfun-amúnisìn kankan láti da ìpín Elédùmarè fún wa, rú! Rárá!
Àṣeyè ni Ìran Yorùbá máa ṣe iṣẹ́ tí Ẹlẹ́da wa fi wá sórí ilẹ̀ Ayé Yí láti ṣe. Ìrànlọ́wọ́ Olódùmarè fún Ìyá wa, Màmá, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, yíò sì wà ní ìgbà gbogbo láti ṣe atọ́nà wa.
- S