Ọ̀gbẹ́ni Klaus Schwab àti Bill Gates ní ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́jọ ló ń ṣe ìf’ọ̀rọ̀wérọ̀ lórí afẹ́fẹ́ amóhùn-máwòrán nípa àníyàn Bill Gates, ó ní òhún fẹ́ kí iye àwọn ènìyàn dínkù ní àgbáyé.

Fún ìdí èyí, ó ti ṣètò onírúurú ọ̀nà láti pa ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn.

Apànìyàn náà sọ lára ọ̀nà tó fẹ́ gbe gbà, nípasẹ̀ ilé-ìwòsàn, ilé-ẹ̀kọ́, oúnjẹ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.

Ṣùgbọ́n Olódùmarè ti kó àwa ọmọ aládé yọọ. Ẹ fura oo!Ṣebí ohun gbogbo tí ọ̀daràn yíi sọ náà ni ó ń ṣe pẹ̀lú àwọn agbésùnmọ̀mí ilẹ̀ Nàìjíríà tí wọ́n ń ṣe ọṣẹ́ nípasẹ̀ ìjẹgàba lórí ilẹ̀ àwa ọmọ aládé.

Òun ló gbé irúgbìn GMO wá fún àwọn ọ̀daràn ìjọba apanisayọ̀ Nàìjíríà tí wọ́n sì gbe fún àwọn àgbẹ̀ lórílẹ̀-èdè Olómìnira Tiwanwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) nípasẹ̀ ìdúkokò mọ́ ni. Bẹ́ẹ̀ naa ni apànìyàn yí ń lo Dangote nípasẹ̀ oúnjẹ láti ṣe ikú pa àwa ọmọ D.R.Y ṣùgbọ́n kòle ṣééṣe o.

Fọ́nrán yí fihàn gbangba bí Bill Gates se ń fi ìgboyà sọ pé ojúṣe òun ni láti dín iye ènìyàn tí ó wà láyé kù, kí oúnjẹ ó lè kárí, àti kí àwọn ènìyàn tó bá kù le ní ètò-ẹ̀kọ́ tó péye.

Ẹlòmíràn á sọ pé ṣé ó ṣeéṣe ní? Ó pẹ́ tí wọ́n ti nṣeé, ọ̀rọ̀ ṣé ó ṣeéṣe kọ́ Olódùmarè ló sọ pé ìran Yorùbá kò ní parun; ìdí nìyẹn tí ó fi gbé Ìyà wa dìde, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ọlá Onítirí-Abíọ́lá, pé kí Wọ́n jẹ́ Olùgbàlà fún Ọmọ Yorùbá ní àkókò yí àti títí ayé.

Ẹ jẹ́ kí á gbárùkù ti Ìjọba-Adelé wa, láti ri pé ohun gbogbo wá sí ìmúṣẹ gẹ́gẹ́bí àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè gbé lé Màmá wa lọ́wọ́ fún ìran Yorùbá.

BILL GATES, APANI MÁ YỌDÀ