Bí àwọn òpònú olóṣèlú ní ilẹ̀ adúláwọ̀, pàápàá ní ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà, ṣe ń ronú oríṣiríṣi ọ̀nà láti jí owó kó sí àpò ara wọn, bẹ́ẹ̀ náà ní àwọn òyìnbó aláwọ̀ funfun ń ronú nígbà gbogbo oríṣiríṣi ọ̀nà tí àwọn ó tún gbà láti leè túbọ̀ máa kó àwọn ohun àlùmọ́ọ́nì wa, síwájú àti síwájú síi.
❗PÀJÁWÌRÌ FÚN ÀÀBÒ❗KÁÀKIRI GBOGBO ÌPÍNLẸ̀ YORÙBÁ TÍTÍ DÉ OLD Ọ̀YỌ́ EMPIRE, Ẹ MÁA YA FỌ́TÒ FÚLÀNÍ, OLỌ́PA, OLÓṢÈLÚ, SÓJÀ, TÍ Ẹ BÁ FURA SÍ ÌRÌN ÀTI ÌṢESÍ WỌN NÍ AGBÈGBÈ YÍN. KÍ Ẹ FI ṢỌWỌ́ SÍ BÀBÁ ÌJÌNLẸ̀ +905367341665 (WHATSAPP).… Pín Sórí Àgbàgbé X (Twitter)Nínú fọ́nrán kan tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni a ti rí arákùnrin òyìnbó kan, níbi tí ó ti ń sọ̀rọ̀ báyìí pé, àwọn yóò ríi dájú pé, àwọn túbọ̀ ńlo àwọn aláwọ̀ dúdú ní ìlòkulò, láti leè ṣàwárí ibi tí wọ́n yóò ti rí àwọn ohun àlùmọ́ọ́nì síi láti kó.
Ìdí nìyí tí wọ́n fi sọ pé, àwọn fẹ́ pa àwọn ènìyàn tí ó tó bílíọ̀nù mẹ́ta níye.
Tí kìí bá ṣe ọpẹ́lọpẹ́ màmá wa, Ìyá ìran Yorùbá tí Olódùmarè rán sí wa ní àkókò yí, Ìyá Ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla, kí ni àwa ọmọ Yorùbá ìbá máa wí nísinsìnyí.
Bí Olódùmarè ṣe kẹ́ àwa ìran Yorùbá tó pẹ̀lú oríṣiríṣi ohun àlùmọ́ọ́nì, tí inú ilẹ̀, ti inú omi, àwa ènìyàn pàápàá tí a wà lórí ilẹ̀ Yorùbá, ènìyàn ọ̀tọ̀ ni a jẹ́, síbẹ̀, àwa náà ni a tún lọ ń ṣe ẹrú fún àwọn òyìnbó tí kò ní ohun àlùmọ́ọ́nì kankan látàrí bí àwọn tí wọ́n pe ara wọn ní ọba àti àwọn olóṣèlú ti ṣe ta ìran wọn nítorí owó àti ipò tí wọn kò sì ro ọjọ́ ọ̀la rárá.
Ṣùgbọ́n Olódùmarè ti gba àwa ìran Yorùbá lọ́wọ́ àwọn apànìyàn yìí, nítorí pé àwa kò sí lára ìlú Nàìjíríà mọ́ láti ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbẹ̀wáọdúnóléméjìlélógún, tí a sì ti ṣe ìbúra wọlé fún olórí adelé wá, Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ, ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbẹ̀wáọdúnólémẹ́rìnlélógún.
Gbogbo àwọn tí wọ́n ń fipá jẹ gàba lórí ilẹ̀ wa, láìpẹ́ láìjìnnà wọ́n máa bẹ̀rẹ̀ sí ní palẹ̀ ẹrù wọn mọ́ nítorí pé Olódùmarè ti bá wa sí wọn nídìí.
Nítorí náà, àwa ọmọ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira tiwantiwa ti Yorùbá, ẹ jẹ́ kí a ṣe arawa lọ́kan, kí a má ṣe rí ẹnikẹ́ni tí yóò gba àbọ̀dè fún ìran Yorùbá, kí a má se fi àwọn ohun tí ó yẹ kí ó jẹ́ àṣírí láàárín àwa ọmọ Yorùbá nìkan han àjòjì bóyá nítorí pé, a ti fẹ́ wọn ní ọkọ tàbí aya. Kò sí ẹni tó kéré jù tàbí dàgbà jù lábẹ́ òfin.
Ìjìyà tí ó tọ́ tí ó sì yẹ ní yóò wà fún ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ pa idà òfin lójú ní ilẹ̀ Yorùbá, nítorí pé kò sí ojúsàájú rárá.
Ká Ìròyìn Síwájú sí:
- ỌMỌ YORÙBÁ ṢE Ọ̀PÁ-ÌRÌN FÚN ÀWỌN ONÍPÈNÍJÀ OJÚ
- ÀWỌN OÚNJẸ ILẸ̀ YORÙBÁ
- ÀWỌN ỌMỌ ÌBÍLẸ̀ ÈKÓ PE SANWÓ-OLÚ NÍ’JÀ, L’ORÍ ILẸ̀ TÍ DANGOTE NÍ ÒUN SAN ỌGỌ́RUN MÍLÍỌ̀NÙ DỌ́LÀ FÚN